Ogbomoso Quintuplets: Ọ̀kan nínú àwọn ìbarùn-ún jáde láyé lọ́jọ́ karùn-ún
Isẹ Oluwa, awamaridi ni nitori ọna rẹ, ko si ẹni to ye tabi ẹni to mọ, bo si se wu Oluwa lo n se ọla.
Nibi ti awọn eeyan kan ti n fi ojoojumọ sunkun si Ọlọrun lọrun fun ẹbun ọmọ, ni Ọba Oke ti fi ibarun ta idile Idowu ati Funmilayo Oluwadara lọrẹ.
Awọn tọkọ-taya yii lo ti kọkọ bi ọmọ marun tẹlẹ, ki oore ibarun tun to wọle de, ti iya wọn si bi wọn wọọrọwọ lai se isẹ abẹ.
- Wo àwọn ìbejì tó mú ẹ̀dọ̀ àti egungun àyà kan ṣoṣo wá látọ̀run
- Ayẹyẹ ọdún ìbejì dùn, ó lárinrin nílùú Igbó-ọrà
- Ọdún ìbejì sọkutu-wọ̀wọ̀ ní Igboọrà, àṣírí bí wọn ṣe ń bí ìbejì tú
- Ìbejì Oníbẹ̀mbẹ́ Òru tí kò yara wọn lẹ́yìn ọgọ́ta ọdún
- Wọ́n gba ìyá mi nímọ̀ràn láti fi òògùn pa ìbejì mi tó lẹ̀pọ̀ torí abàmì ọmọ ni wọ́n - Tawakalitu Ahmed
- Oshisko twins, àwọn 'ìbejì' tó ń dẹ́rìn ín p'òṣónú
- Obìnrin kan bí ibejì lẹ́yìn ọjọ́ 26 tó bí ọmọkùnrin
- Wo àwọn òṣèré tíátà Yorùbá tó bí ìbejì
- A jọ ṣe ìyàwó pọ̀, a jọ bímọ ní ọjọ́ kan náà, a tún jọ máa ń ṣàìsàn pọ̀ ni
- "Ìbejì ní wá ṣùgbọ́n àyẹwò fí hàn pé baba ọtọ́ọ̀tọ̀ ló bí wà"
- Ilé ìwòsàn l'Àbuja ti ya àwọn ìbejì tí wọ́n sọpọ̀ láyà lọ́fẹ̀ẹ́
- Àwọn dókítà ya ìbejì tó lẹ̀pọ̀ l'Abuja
Nigba ti tọkọtaya Oluwadara n ba BBC Yoruba sọrọ nilu Ogbomoso, wọn ni ibẹta ni dokita kọkọ ni oun yoo bi, ki ibarun to wa, ọkunrin kan ati obinrin mẹrin.
Ni ọjọ karun tawọn ọms naa dele aye la gbọ pe ọkunrin kan soso laarin awọn ibarun naa jade laye.
Tọkọ-taya naa ti wọn jẹ alagbaro, ni ko ti wa ri owo ile iwosan san lati maa lọ sile, bi o tilk jẹ pe dokita ti yọnda wọn.
Wọn wa n bẹbẹ fun iranwọ owo lọdọ awọn ẹlẹyinju aanu, lati sanwo ile iwosan ati fun itọju awọn ọmọ mẹrin to ku pẹlu awọn ẹgbọn wọn nitori ọna abayọ.




