Iṣẹ́ abẹ láti ya ìbejì tó lẹ̀pọ̀ yọrí sí rere l'Abuja

Oríṣun àwòrán, Dogara media office
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Awọn dokita kan ṣe iṣẹ abẹ lati ya awọn ibeji ti wọn lẹpọ ni ile iwosan ikọni Fasiti Ilu Abuja to wa ni Gwagwalada lọjọ Iṣẹgun.
Olori awọn dokita ọun Nuhu Kwajafa lo kede aṣeyọri iṣẹ abẹ naa loju opo Instagram rẹ.
Dokita Kwajafa sọ pe isẹ awọn ni igbiyanju lati doola ẹmi gẹgẹ oniṣegun, ati wipe o ṣe pataki fun awọn lati fifẹ han si awọn eniyan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
O fi kun ọrọ rẹ pe aye yii yoo dara ju bayiii lọ ti onikaluku ba n fifẹ han si ọmọlakeju wọn.

Oríṣun àwòrán, Dogara media office
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe miliọnu naira ni owo ti wọn san fun iṣẹ abẹ lati ya awọn ọmọ naa.










