June 12: Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ní Nàìjíríà sọ lórí ìfẹ̀hónúhàn táwọn èèyàn fẹ́ ṣe lásìkò àyájọ́ ìjọba awarawa

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu
Ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria, IGP Usman Alkali Baba ti sọrọ lori iwọde tawọn eeyan kan n gbero lati ṣe lọjọ ayajọ ijọba awarawa ni Naijiria lọjọ kejila oṣu kẹfa ọdun 2021 yii, June 12.
Ọga ọlọpaa ni Naijiria rọ awọn araalu lati ṣe ayajọ ijọba awarawa pẹlu alaafia lai da rogbodiyan kankan silẹ.
Ọga ọlọpaa Baba sọrọ yii lasiko abẹwo ọlọjọ mẹta to ṣe si ipinlẹ Eko.
- Mo kọ̀ láti sọ̀rọ̀ nípa fí f'òfin de 'Twitter' báyìí sùgbọ́n a ti sí isẹ́ àkànse Deep Blue ti NIMASA- Buhari
- Ìrora iṣẹ́ abẹ ìdí tí mo ṣe pọ̀jù, mò ń kú lọ, mo fẹ́ padà sí bí mo ṣe wà tẹ́lẹ̀ - Bobrisky
- Orílẹ̀-ède 174 káàkiri àgbáyé ní ìwọ́de Yoruba Nation yóò tí wáyé ní June 12- Ẹgbẹ́ Yoruba One Voice
- Wo ilúbìnrin tí wọn ti ń ní ìbálòpọ̀, bímọ̀ láì ní ọkọ
- Pańpẹ́ ọba mú pàsítọ̀, babaláwo àti àwọn mẹ́ta tí wọ́n ká ara ènìyàn mọ́ lọ́wọ́
- Orí mi wú pé àkòkò ìjọba mi ní àṣeyọrí reluwé ń wáyé - Buhari
- Ẹ̀yin òṣèré tíátà, kò sí iṣẹ́ ọ̀fẹ́ mọ́, ẹ sanwó iṣẹ́ tẹ bá gbé fún mi - Funmi Awelewa
Awọn eeyan kan papa julọ awọn ọdọ ti n gbero lati fi ẹhonu wọn han lori bi nkan ko ṣe fara rọ ni Naijiria.
Eleyii ti mu ki ibẹru bojo gbalẹ kaakiri orilẹede ṣaaju ọjọ iwọde yii.
Koda awọn kan tiẹ n sọ pe afaimọ ki iwọde ọhun maa da bi ti EndSARS to mi ilu titi loṣu kẹwaa ọdun 2020.
Ṣugbọn ọga ọlọpaa sọ pe ọjọ ayọ ati ọjọ idunnu ni June 12 tii ṣe ayajọ ijọba awarawa lorilẹede Naijiria.
O rọ awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn yọ ayọ mọ ni wọn ki onikaluku si maa ṣiṣẹ rẹ lai pa ẹlomiran rara.
''Ẹyin olugbe ipinlẹ Eko, ẹ lọ fọkan balẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ṣetan lati daabo bo yin bi ẹ ti n ṣe ajọyọ ayajọ ijọba awarawa,'' Baba lo sọ bẹẹ.
Ọga ọlọpaa ni Naijiria tun rọ awọn ọba alaye lati fọwọ sowọpọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa lori akitiyan ati wa ojutu si eto abo to mẹhẹ ni Naijiria.
Ọga ọlọpaa sọrọ yii nigba to ṣabẹwo si Eleko ti Eko, Oba Rilwan Akiolu niluu Eko.












