Funmi Awelewa - N kò ní gbà kẹ lò mí tán, kẹ wá já mi jù sílẹ̀ bíi náírà márùn-ún àlòkù

Funmi Awelewa

Oríṣun àwòrán, funmiawelewa/Instagram

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ Orijafunmi Awelewa, lọ tí ń janu lójú òpó Instagram láti gbé sẹ́yìn gbajúgbajà òṣèré olólùfẹ́ wọn, tó sọ̀kò ọ̀rọ̀ lu àwọn akẹ́gbẹ́ rẹ̀.

Àwọn akẹẹgbẹ́ rẹ̀ yìí ló ní wọ́n fẹ́ràn láti má sanwó iṣẹ́ tí wọ́n bá bẹ akẹ́gbẹ́ wọ́n láti kópa nínú sinimá agbéléwò.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe kọ́ soju òpó instagram rẹ̀, "ṣe ẹrí àwọn akẹ́gbẹ́ wa nínú eré tíátà, wọ́n fẹ́ràn láti máa bá àwọn ènìyàn ṣe, tí wọ́n bá rí àǹfààní lọ́dọ̀ ẹni náà ní.

Ọmọ Iya mi jà f'órí rẹ̀. Awọ́n ènìyàn fẹ́ran láti lo ènìyàn, kì wọn sì já jù sílẹ̀ bí náírà márùn-ún àlòkù"

Orijafunmi ṣàlàyé pé kí gbogbo àwọn akẹ́gbẹ́ òun gbajumọ nǹkan tí yóò gbé oúnjẹ́ òòjọ́ wá sórí tábìlì wọ́n, nítorí lẹ́yìn ó rẹyìn, àwọn àti ẹbí nìkan ni yóò kojú nnkan tó bá jẹyọ.

Funmi Awelewa

Oríṣun àwòrán, funmiawelewa/Instagram

Ó fi kú pé kò sí anfaani kankan nínú kí ènìyàn jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká lai ni kọ́bọ̀ lápò.

Ó wá ké sí àwọn akẹ́gbẹ́ rẹ̀ pé bí wọ́n bá pe oun si iṣẹ́, kí wọ́n ṣetán láti sanwó isẹ́ òun.

Gbajúgbajà òṣèré náà, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Morili ni, ọ̀pọ̀ àwọn tó wà lókè kò ṣetán láti fà àwọn tó wà nílẹ̀ sókè, orí ara wọn nìkan ni wọn ń dù.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ló ti wá ń kín ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn pé, ọ̀rọ̀ Funmi Awelewa jána, àwọn òṣèré tíátà mìíràn pẹ̀lú wà lára àwọn tó gbàrùkù tí nǹkan ti Funmi sọ.

Díẹ̀ lára àwọn tó kín Funmi lẹ́yìn lórí ọ̀rọ̀ náà rèé

Awọn eeyan to ti Funmi Awelewa lẹyin

Oríṣun àwòrán, funmiawelewa/Instagram