Cannabis Plantation: Akeredolu rọ ìjọba láti tẹ́wọ́ gba ọ̀gbìn igbó ká lè yọ lọ́fìn ọrọ̀ àjé tó mẹ́hẹ

Ẹnikan gbe igbo lọwọ ati aworan gomina Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, NDLEA/Rotimi Akeredolu

Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu ti rọ ijọba Naijiria lati pa ilana ati èrò atijọ ti, eyi to ni irugbin eṣu ni igbo jẹ.

Akeredolu sọ pe ijọba le ṣe eyi, nipa gbigbe ofin kalẹ fun amojuto ọgbin ati kata-kara igbo.

O ni obitibiti owo ni kata-kara ọgbin igbo yoo mu wọle fun Naijiria, ti yoo si tun jẹ orisun ọrọ aje míì, to ba mojuto daadaa.

Gomina Rotimi Akeredolu gbe imọran yii kalẹ nibi ipade apero kan to waye lori anfaani ati iwulo ọgbin igbo ni Naijiria, eyi to waye nilu Akurẹ lọjọ Aje.

Akeredolu kesi awọn ile aṣofin agba mejeeji ni Naijiria, lati ṣe ọkan akin, ki wọn si ṣe atunse si ofin ajọ to n gbogun ti oogun oloro ni Naijiria, NDLEA, lori lilo igbo.

O ni iwulo ti igbó ni fun eto ilera, pọ ju aleebu rẹ lọ.

egbòogi olóró igbo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ló ń fara pamọ́ mu igbò

Gomina Akeredolu sọ pe imọ ijinlẹ ti fihan pe orisun ọrọ aje ni igbo, ti wọn ba se amulo rẹ bo ṣe yẹ.

Nigba to sọrọ lori awuyewuye to n waye lori bo ṣe n polongo pe ọgbin igbo di itẹwọgba, Akeredolu sọ pe oun ko deede ma a polongo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni, irinajo ti oun ati awọn ọmọ igbimọ alasẹ rẹ lọ si orilẹ-ede Thailand ni saa rẹ akọkọ gẹgẹ bi gomina, lo la oun loju si awọn anfaani rẹpẹtẹ to wa lara igbó.

O ni iyalẹnu lọ jẹ fun oun lati ri i ni Thailand pe awọn aginju nla ni ijọba fi n gbin igbo, to si gba awọn to n lo egboogi oloro ni ilokulo tẹlẹ si iṣẹ aje.

O ni kii se pe oun n polongo pe ko di okoowo ti oriṣiriṣi eeyan yoo ma a ṣe, a fi àwọn ti ijọba ba fun ni àṣẹ.

Àkọlé fídíò, Funmi Aragbaiye: Ọlọ́run ní ohun táwọn olórí wa fẹ́ jẹ ni wọn ń wá

"Awọn oogun ati nkan elo ti wọn fi igbó ṣe wa ni awọn ile itaja ogun ni Naijiria, sugbọn o ṣeni laanu pe ilẹ okeere ni wọn ti n fi owo gọbọi ko wọn wọle.

"Nkan ti mo n sọ ni pe ki a fi aaye gba ọgbin igbó, fun lilo awọn ileesẹ to n ṣe oogun oyinbo fun ilera."

O fi kun ọrọ rẹ pe ipinlẹ Ondo wa lara awọn ibi ti wọn ti ni igbo to dara julọ ni agbaye.

Nigba ti oun naa n ṣorọ, aṣoju ile igbimọ aṣofin níbi ipade apero naa, to tun jẹ agbenusọ ile, Asofin Benjamin Okezie Kalu sọ pe, oun satilẹyin fun erongba Gomina Akeredolu lori sísọ ọgbin igbo di nkan ti ko lodi si ofin ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Ayelala Idol: Onímọlẹ̀ ní olúwẹri obìnrin ni òrìṣà náà ló ṣe ń pọn omi sínú ẹlẹ́ṣẹ̀

Bakan naa, Alaga igbimọ to wa fun ọrọ ilẹ okeere nile aṣofin, Tolu Akande-Sadipe sọ pe ireti wa pe atunse aba ofin lori awọn oogun oloro, ti wọn ti ṣe agbeyẹwo rẹ fun igba keji yoo mu igba ọtun ba ọgbin igbó fun lilo eto ilera.