Nigeria Passport: Iléeṣẹ́ Immigration bẹ̀rẹ̀ ìlànà tuntun fún gbígba iwé ìrìnna

Iwe irinna silẹ okeere ti Naijiria

Oríṣun àwòrán, Nigeria Immigration Service

Ileesẹ to n ri si ìwọlé-wọde ero ati eeyan ni Naijiria, Nigeria Immigration Service, ti kede pe oju opo iforukọ silẹ fun gbigba pasipọọti irinna yoo bẹrẹ isẹ pada ni oru ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa.

Oludari ileesẹ naa, Muhammad Babandede sọ pe ṣíṣí oju opo naa pada yoo fun awọn eeyan to koju oṣuwọn ni anfaani lati fi orukọ silẹ, ti wọn yoo tun le san owó fun oriṣiriṣi ipele pasipọọti to wa.

Oṣu Karùn-ún ni ileesẹ to n ri si ìwọlé-wọde ero ati eeyan da eto naa duro, ko le ri aaye yanju àwọn iforukọ silẹ to wa nilẹ tẹlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi bẹrẹ ti wọn bẹrẹ pada yii, jẹ ibẹrẹ ilana tuntun fun gbigba pasipọọti.

Bawo ni ilana tuntun fun gbigba Passport yoo ṣe ri?

Ori ayelujara ni ileesẹ Immigration ni iforukọ silẹ ati owo sísan fun gbigba pasipọọti yoo ti ma a waye báyìí.

Awọn to fẹ ẹ gba nilo lati lọ si oju opo naa, nitori pe nibẹ ni wọn yoo ti fi gbogbo àwọn iwe ti wọn nilo silẹ fun ayẹwo.

Lara nkan to tun jẹ tuntun ni pe, aaye ti wa ni oju opo ayelujara naa lati ba oluranlọwọ sọrọ, fun ẹnikẹni to ba ni ipenija lasiko to n fi orukọ silẹ, wọn o si tọ ọ sọna.

Lẹyin ti iforukọ silẹ naa ba yanjú, ẹni to fẹ ẹ gba pasipọọti yoo mu ọjọ ti yoo ṣe ifọrọwanilẹnu wo, ibi to ba wu ú, ati akoko to rọrùn fun.

Ori ayelujara naa ni yoo ti ṣe e.

Àkọlé fídíò, Funmi Aragbaiye: Ọlọ́run ní ohun táwọn olórí wa fẹ́ jẹ ni wọn ń wá

Ọsẹ mẹfa ni ṣíṣe ati gbigba pasipọọti tuntun, ti yoo si jẹ ọsẹ mẹta fun awọn to ti gba ri, to fẹ pada gba òmíràn.

Lati asiko yii lọ, ileesẹ Immigration ko ni gba ẹnikeni ti ko ba kọkọ fi orukọ silẹ lori ayelujara laaye ni ọfiisi rẹ.

Ori imeeli ati nọmba foonu ti ẹni naa ba kọ lasiko iforukọ silẹ ni wọn o ti sọ fun ti pasipọọti rẹ ba ti wa nilẹ fun gbigba.

Awọn nọmba ibara ẹni sọrọ si ti wa ti awọn to ba ni ipenija le pe fun iranlọwọ.

Ọgbẹni Babandede tun lo anfaani naa lati gba awọn ọmọ Naijiria ni imọran pe ki wọn mase gba ọna ẹ̀bùrú fi orukọ silẹ nitori gbogbo eto naa ti rọrùn bayii.

Àkọlé fídíò, Teachers retirement age and years of service: Ìrírí àwọn àgbà olùkọ́ ṣì wúlò fún àwa ọ̀dọ́

Bakan lo kilọ fun awọn to n fi gbigba pasipọọti ṣe iṣẹ aje lati dẹ́kun rẹ, ki wọn o ma ba a foju wina ofin.

Ọdun 2019 ni Aarẹ Muhammadu Buhari pàṣẹ pe ileesẹ to n tẹ owó fun Naijiria nikan, lo ni àṣẹ lati ma a tẹ pasipọọti irinna silẹ okeere.