Igangan Attacks: Àwọn òbí ń fi ìpaya kó akẹ́kọ̀ọ́ kúrò nílé ẹ̀kọ́ ní Ibarapa torí àkọ́tun ìkọlù

Oríṣun àwòrán, MOnsuru Aderoju
Ọpọ awọn obi ati alagbatọ la gbọ pe wọn ti bẹrẹ si ya bo awọn ile ẹkọ lawọn ilu bii Ayete, Igangan ati Tapa, ni ijọba ibilẹ Ibarapa lati ko awọn ọmọ wọn kuro nitori bi eto aabo agbegbe naa ṣe ri.
Iroyin ni igbesẹ naa ko ṣẹyin ibẹru awọn obi pe o ṣeeṣe ki ikọlu mii waye lawọn ile ẹkọ naa, lẹyin ikọlu to waye ṣaaju ni Igangan lopin ọsẹ ninu eyi ti ọpọ ẹmi ati dukia ti ṣofo.
Ti ẹ ko ba gbagbe, alẹ ọjọ Abamẹta ni awọn afurasi Fulani darandaran ya bo ọkan lara awọn ilu naa, iyẹn Igangan, ti wọn si jo ọpọ ile ati ọkọ lẹyin ti wọn pa awọn eeyan.
- Sunday Igboho ṣàbẹ̀wò sí Igangan lẹ́yìn ìkọlù, àmọ́...
- Èèmọ̀ rèé o! Bàbá yí pòórá ní ọmọ ọdún 26, ló bá déèdé yọ sí ìlú lẹ́yìn ọdún 63
- Afurasí darandaran tún kọlu Imeko-Afon, ẹ̀mí mẹ́ta bọ́, aráàlú ń sá kúrò nílé
- Ìkọlù Igangan tọ́ka si pé ogun ń bọ̀ ní Nàíjíríà láìpẹ́ - Gani Adams
- Ọ̀rọ̀ tí ọkọ́ mi sọ gbẹ̀yìn nílé ìjọsin lọ́jọ́ tó kú, kún fún ẹ̀rù àti ìpayà - Aya TB Joshua
- Ìjọ RCCG kìí ṣe tí Nàíjíríà níkan, ìjọba kò lè dá wa dúró láti lo Twitter- Pásítọ̀ E. A. Adeboye
Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe naa fidi rẹ mulẹ fun awọn akọroyin pe ko din ni eeyan mọkanla to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Elenpe ti Tapa, Oba Oyekanmi Sunday Titiloye sọ fun awọn akọroyin pe, lootọ ni awọn obi ti bẹrẹ si n ko awọn ọmọ wọn kuro nile ẹkọ.
O ni igbesẹ awọn obi naa ko ṣẹyin ibẹru pe o ṣeeṣe ki awọn ọdaran darandaran tun kọlu ile ẹkọ wọn.
Ọba Titiloye ṣalaye pe "A ko le sun titi ti ilẹ fi mọ lẹyin ti a gbọ pe awọn Fulani n gbero lati ṣakọlu si wa, ṣugbọn a ko mọ akoko ti ikọlu naa yoo waye."
"Ko si awọn agbofinro kankan lagbegbe yii, asiko ti a si nilo iranlọwọ ijọba ree."
Ikọlu to waye ni Igangan naa gba omi loju ọpọ awọn ọmọ ilu naa, ọpọ eeyan ni Naijiria si ti bẹrẹ si fi erongba wọn lede lori ikọlu naa.
Titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ, awọn agbofinro ko tii ri ẹnikẹni gbamu gẹgẹ bii afurasi to wa nidi ikọlu ọhun.



















