Igangan Attacks: Sunday Igboho ní ológun dá òun lọ́nà láti wọnú ìgbó wá afurasí ọdaràn

Sunday Igboho ninu mọto ni Igangan

Oríṣun àwòrán, Screen shot/Koiki Media

Lẹyin ikọlu to waye niluu Igangan lagbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo, ajijagbra to tun jẹ ajafẹtọ ọmọniyan, Oloye Sunday Igboho ti ṣabẹwo siluu ọhun.

Gẹgẹ bii fidio to wa loju opo ayelujara fun agbẹnusọ ajijagbara naa, Olayomi Koiki se sọ, se ni awọn olugbe ilu naa n fo fayọ lasiko ti Igboho balẹ sinu ilu naa tan.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, afojusun Igboho ni lati wọ inu igbo kijikiji to wa niluu naa lọ pẹlu erongba lati ṣawari awọn afurasi to ṣiṣe laabi ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn ọdaran Fulani darandaran yoo ṣekọlu si Igangan, ikọlu to waye kẹyin yii gba omi loju eeyan.

Iroyin ni ko pẹ ti Igboho atawọn ẹmẹwa rẹ gunlẹ sinu ilu naa tan, ti awọn ọmọ ogun naa de.

Sunday Igboho ninu mọto ni Igangan

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Igbagbọ ọpọ eeyan ni pe awọn ọmọ ogun yoo da alaafia pada sinu ilu ọhun.

Ṣugbọn Olayomi Koiki jabọ pe ko din ni ọkọ ayọkẹlẹ mẹwaa ti awọn Ologun naa gbe wa pẹlu erongba lati da Sunday Igboho lọna, ko ma baa wọ inu igbo naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn ọmọ ogun to lọ Igangan ko fẹ ki Igboho mu awọn afusari to kọlu ilu naa ni.

O ṣalaye pe awọn olugbe ilu ọhun ko gba awọn ọmọ ogun naa laaye lati wọ ilu wọn, eyi to mu wọn da awọn ologun naa pada lẹnu ibode ilu ọhun pẹlu ọgbọn ati awada.

Iroyin naa ni Igboho si wa ninu igbo naa, to n wa awọn afurasi ọdaran to kọlu ilu Iagnagan lọjọ Aje kiri lati mu wọn.

Ti ẹ ko ba gbagbe, oru mọju ọjọ Abamẹta si ọjọ Aiku ni awọn afurasi Fulani darandaran kọlu ilu naa, ti wọn si ṣekupa ọpọ eeyan, bakan naa ni wọn tun jo ọpọ dukia bii ile ati ọkọ.

Àkọlé fídíò, Ayelala Idol: Onímọlẹ̀ ní olúwẹri obìnrin ni òrìṣà náà ló ṣe ń pọn omi sínú ẹlẹ́ṣẹ̀

Akọroyin BBC to ṣabẹwo si ilu naa lọjọ Aje jabọ pe nnkan ti awọn afurasi naa bajẹ ko lonka.

Lara awọn ibi to foju ganni, ti awọn afurasi naa dana sun ni Aafin Asigangan ti ilu Igangan, to jẹ ori ade ilu naa.

Ti ẹ ba ranti daadaa, agbegbe Ibarapa yii naa ni okiki Sunday Igboho ti kọkọ bẹrẹ si n milẹ titi losu kinni ọdun yii.

Akoko yii, tii se osu kinni ọdun 2021 lo fun awọn Fulani to n gbe lagbagbe ọhun ni gbedeke ọjọ meje, lati fi ibẹ silẹ lẹyin ti wọn fi ẹsun ipaniyan ati ijinigbe kan wọn.

Agbegbe yii naa ni awọn OPC ti fi panpẹ ofin mu arakunrin kan ti wọn n pe ni Iskilu Wakili, ti wọn sọ pe oun ni baba isalẹ fun awọn ọdaran darandaran lagbegbe naa.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson Shomolu Bariga ní 'Restructuring'ti bọ́ aṣọ kò bá Omọyẹ mọ́!

Ọpọ awọn alẹnulọrọ lawujọ lo ti bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu ikọlu naa, to fi mọ awọn eeyan bii gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu ati Aarẹ Onakakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams atawọn eeyan mii.

Lẹyin o rẹyin, o ṣe ni laanu pe titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ, awọn agbofinro ko tii ri ẹnikẹni gbamu gẹgẹ afurasi to wa nidi ikọlu ọhun.