Igangan Attacks: Ẹgbẹ́ Arewa àti Iba Gani Adams jọ ń fohùn ránsẹ́ síra wọn lórí ọ̀rọ̀ ìsẹ̀lẹ̀ Igangan

Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Others

Aare Onakakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti daa pada pe o togẹ́ lori ọ̀rọ̀ ikọlu awọ Fulani ni ilẹ̀ Yoruba.

Iba Gani Adams sọ̀rọ̀ yii lasiko to n bu ẹnu atẹ ikọlu naa to waye ni Igangan.

O ni pe iṣekupani to wa ye niluu Igangan to wa lagbegbe Ibarapa ni ipinlẹ Oyo, n ṣafihan pe o ṣeeṣe ki ogun bẹ silẹ ni Naijiria laipẹ.

Gani Adams kilọ fun awọn Fulani lati yago fun ilẹ Yoruba, bi bẹẹ kọ, wọn yoo jẹ iyan wọn niṣu.

Ikọlu naa to waye ni afẹmọju ọjọ Isinmi sọ gbogbo awọn olugbe agbegbe Igangan si hilahilo, lẹyin ti awọn afurasi Fulani darandaran ṣekupa ọp eeyan, ti wọn si tun dana sun ọpọ ọkọ ati ile bii ogun

Àkọlé fídíò, Tunde Gbadamosi: Kìí ṣe Tinubu ní ipò ààrẹ̀ tọ́ sí, ìgbà wo ní ìtan ajá ń kan lèmọ́mù?

Béé, saaju ni ẹgbẹ́ Arewa naa ti fohun ranse si i.

Ẹgbẹ Arewa CNG ti kilọ fun Aarẹ Ọnakakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams pe awọn Yoruba ko gbọdọ gbẹsan iṣẹlẹ ipaniyan to waye niluu Igangan, lagbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo lara awọn Hausa ati Fulani to wa nilẹ Yoruba.

Ẹgbẹ naa sọ pe ikilọ yii ṣe pataki lẹyin ti wọn ni Gani Adams sọ pe awọn eeyan ilẹ Hausa ti kede ogun koju ilẹ nipa iṣẹlẹ ipaniyan to waye niluu Igangan.

Àkọlé fídíò, Magaret Jimoh: Èrè díẹ̀ ti tó mi níbi oúnjẹ ti mò ń tà- Maggie Rice

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Abdul-Azeez Sulaiman fi sita, wọn ni awọn ko ni faramọ ikọlu awọn eeyan ilẹ Hausa nilẹ Yoruba.

"O ṣeni laanu pe pẹlu ipo Gani Adams nilẹ Yoruba, o si n tiraka lati fi iwa bi ologun silẹ.

A ri i gẹgẹ bi ohun to buru jai fún Gani Adams lati sọ pe awọn eeyan ilẹ Hausa lo wa nidi iṣẹlẹ ilu Igangan nigba ti iwadi si n lọ lọwọ lati mọ awọn to ṣiṣẹ naa.

Igbesẹ Gani Adams lati sọrọ yii fihan iru oju tawọn Yoruba fi n wo awọn ẹya Hausa," Sulaiman ṣalaye.

Agbẹnusọ ẹgbẹ CNG fikun ọrọ rẹ pe Gani Adams to n sọ pe awọn eeyan ilẹ Hausa ti kede ogun koju ilẹ Yoruba kan naa lo wa nidi ikọlu awọn alejo niluu Igangan eleyii ti Sunday Igboho ṣe agbatẹru rẹ.

Iba Gani Adams ati eeyan apa oke ọya

Oríṣun àwòrán, Iba Gani Adams

Gani Adams, ṣọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ, nǹkan kò gbọdọ̀ ṣe ará òkè ọya nílẹ̀ Yoruba - Arewa kìlọ̀

Ẹgbẹ awọn ara Ariwa orilẹede Naijiria, Pan-Arewa Socio-cultural organization ti kilọ fun Aarẹ Ọna Kakanfo ti Ilẹ Yoruba, Ọtunba Gani Adams, lati ṣọ ọrọ ẹnu rẹ nipa awọn ara oke ọya ti wọn n gbe ni ilẹ Yoruba.

Eyi ko ṣẹyin ọrọ ti Gani Adams sọ lẹyin ti awọn afurasi Fulani darandaran ṣekọlu si ilu Igan

gan nipinlẹ Ọyọ, ti ọpọ ẹmi si ba iṣẹlẹ naa lọ.

Gani Adams ni iṣekupani to wa ye niluu Iganganyii n ṣafihan pe o ṣeeṣe ki ogun bẹ silẹ ni Naijiria laipẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ, ẹgbẹ Arewa ninu ọrọ agbẹnusọ ẹgbẹ naa sọ, Abdul-Azeez Suleiman, o ni awọn fi ikilọ ranṣẹ si Gani Adams pe eera ko gbọdọ rin awọn ara Ariwa to wa ni ilẹ Yoruba nitori iwadii ṣi n lọ lọwọ nipa awọn to ṣekọlu si ilu Igangan naa.

''A ko ni faye gba ikọlu si awọn Hausa kankan ni ilẹ Yoruba nitori wọn n gbẹ nibẹ''

Àkọlé fídíò, Ayelala Idol: Onímọlẹ̀ ní olúwẹri obìnrin ni òrìṣà náà ló ṣe ń pọn omi sínú ẹlẹ́ṣẹ̀

Suleiman ni o ṣe ni laanu pe Gani Adams to di ipo agba mu ni ilẹ Yoruba lo n sọ ọrọ ogun bi ẹ̀ni pe ko i tii gbagbe lọwọ iṣẹ rẹ gẹgẹ bi ajijagbara eleyii to tako iwa ọmọluwabi.

''Ko yẹ ki Gani Adams dede sọ wi pe awọn ara ile Ariwa to wa ni agbegbe naa, lo ṣe iṣẹ yii lai si aridaju to peye nitori iwadii si n lọ lori iṣẹlẹ naa.''

''Eyi fihan wi pe awọn ara ilẹ Yoruba gẹgẹ bi Gani Adams ṣe fihan, ko fẹran awọn ara ilẹ Hausa to wa laarin wọn nitori wọn ti sare n sọrọ ogun ni ilẹ Yoruba''

Ẹgbẹ awọn ara Ariwa naa ni Gani Adams ko tilẹ ṣewadii ki o to ma a sọrọ ogun nitori nigba ti awọn Sunday Igboho ṣekọlu si Seriki, ko si ẹnikẹni to gbe ija wọn nigba naa.

Ìkọlù Igangan tọ́ka si pé ogun ń bọ̀ ní Nàíjíríà láìpẹ́ - Gani Adams

Aworan ile ati ọkọ ti wọn jona

Oríṣun àwòrán, Monsuru Aderoju

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lẹyin ti iroyin ati aworan iṣẹlẹ naa fa ori ayelujara ya, Gani Adams sọ pe awọn eeyan agbegbe oke ọya n mọọmọ lulu ogun ni.

O ni awọn ara oke ọya naa ti ti tẹ ọka nu iru mọlẹ, akoko si ti to fun awọn ọmọ ilẹ Yoruba lati daabo bo ara wọn, lai boju wo ẹyin.

Gani Adams ni "Nigba ti iru nnkan bayii ba n ṣẹlẹ, niṣe lo yẹ ki ẹ dide lati daabo bo ara yin, abi nibo ni awọn ọlọpaa wa lasiko ti awọn janduku yii n pa awọn eeyan wa ni Igangan ?"

Àkọlé fídíò, Kò sí ìgbà kankan tí Yorùbá jókòó pé ki Igboho lọ kéde ìyapa kúrò ní Nàíjíríà

"Koda, awọn ọdaran naa ko yọ aafin Asigangan ti ilu Igangan silẹ lasiko ikọlu naa, a si gbọ pe wọn ti gbe ori ade naa lọ."

Aare Ona kakanfo sọ siwaju si pe ọjọ mẹta ṣaaju ikọlu naa ni adari ikọ Amotekun ni ilẹ Yoruba, ajagunfeyinti Kunle Togun ke gbajare pe awọn Fulani darandaran ti ya bo ilẹ Yoruba.

O ni "Mo kin ọrọ rẹ lẹyin, mo si pe fun aabo kaakiri ilẹ Yoruba, ṣugbọn bayii ti awọn Fulani kọlu Igangan, mo gbagbọ pe afojusun wọn ni lati da rogbodiyan ati ogun silẹ ni ilẹ Yoruba."

Amin iyasọtọ kan

Gani Adams ni oun ko ni la oju oun silẹ ki awọn ọdaran darandaran maa ta ẹjọ alaiṣẹ silẹ, bii iru eyii ti wọn ṣe ni Igangan.

O ṣalaye pe ni bayii ti awọn eeyan oke ọya ti bẹrẹ si n lu ilu ogun nilẹ Yoruba, oun ko ni dakẹ.

Aare Onakakanfo naa sọ pe eeyan ẹlẹran ara ni awọn ti wọn ge ẹmi wọn kuru ni Igangan, bẹẹ si ni wọn ni ẹbi ati ara pẹlu, ko si yẹ ki iku wọn lọ lasan.

Lẹyin naa lo kilọ fun awọn ọdaran darandaran lati jina rere si ilẹ Yoruba.

O tun ke si awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ati awọn gomina ni gbogbo ilẹ Yoruba, lati daabo bo awọn eeyan wọn.

Amin iyasọtọ kan
Aworan aafin Asigangan ti wọn jona

Oríṣun àwòrán, Monsuru Aderoju

Ẹ̀mí mẹ́sàn-án tún ṣòfò ní Igangan, agbébọn jo ilè, ọkọ àti ààfin Ọba

Awọn ara ilu Igangan nijọba ibilẹ Ibarapa ti n ke gbajare pẹlu bi awọn afurasi agbebọn ṣe ya wọ ilu naa.

Ninu ikọlu ọhun to waye lalẹ ọjọ Abamẹta ọpọ ile, ọkọ ati aafin Asigangan ilu Igangan ni wọn sọna si.

Eeyan mẹsan ni a gbọ pe wọn pa nigba ti awọn iroyin miran ni iye eeyan to ku fẹrẹ to mejila.

Amọ ṣa ileeṣẹ BBC Yoruba fidi ọrọ mulẹ nipa isẹlẹ naa ati bo se waye.

Gẹgẹ bi igbakeji alaga ẹgbẹ idagbasoke ilu Igangan, arakunrin Azeez Adelere Saminu se wi lasiko to n ba wa sọrọ, deede ago mẹwa abọ alẹ ọjọ Satide lawọn ṣadede bẹrẹ si ni gbọ iro ibọn.

Aworan aafin Asigangan ti wọn jona

Oríṣun àwòrán, Monsuru Adewumi

''Gbogbo eeyan ko ti sun, ta fi bẹrẹ si ni gbọ iro ibọn. Awọn ọdẹ ilu la kọkọ ro pe wọn n yinbọn soke ṣugbọn a pada ri wi pe awọn Fulani ni.''

Adelere ṣalaye pe lootọ oun ko foju ri awọn agbebọn yii ṣugbọn oun n gbọ ti wọn n sọ ede Fulani nigba ti wọn n ṣe ikọlu sawọn.

''Emi gan ti mo n ba yin sọrọ yii, wọn jo ọkọ mi, aimọye ọkọ ni wọn sun ati ile epo ati ọpọ eeyan lo si ti ku. Eeyan to ku wọn to mẹtala''

Bakan naa lo na ika aleebu si Seriki Fulani, ti Sunday Igboho wa le kuro nilu naa, pe oun lo wa nidi isẹlẹ naa, to si se agbatẹru awọn to wa se ikọlu yii.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho; Seriki Igangan ní kò sí ẹni tó ran àwọn lọ́wọ́ látí ìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ Ibarapa

Awa naa pa lara awọn to ṣe ikọlu si wa

Ọkan lara awọn ọdọ ilu to ba BBC sọrọ, ti o pe orukọ rẹ ni Monsuru Aderoju naa fidi ọrọ ikọlu yii mulẹ.

O ni aridaju ti oun ri ni pe awọn Fulani lo ṣe ikọlu sawọn nitori awọn araalu naa pa lara awọn to ṣe ikọlu yii, taa si ri pe Fulani ni wọn.

Aworan aafin Asigangan ti wọn jona

Oríṣun àwòrán, Monsuru Aderoju

Wọn to bi mẹrin ti awa naa pa. Wọn sun ile epo Adolak, wọn sun aafin Ọba naa.''

O ṣalaye pe ilu ko fararọ lọwọ bayi nitori awọn ọdọ ilu ati agbagba ilu ṣi n kaakiri ilu.

Seriki Fulani: Mi o mọ nkankan nipa ikọlu Igangan

Ọna lati wadi ohun gbogbo, ka si di eyi tii se otitọ mu lo mu ki BBC yoruba tun pe Seriki Fulani lori aago, lati mọ boya lootọ, oun lo wa nidi isẹlẹ naa.

Seriki Fulani, Salihu Abdulkadir si ni pupọ awọn eeyan to ba wa BBC sọrọ saaju n naka aleebu si wipe o wa nidi ikọlu yii.

Lọwọlọwọ ilu Ilorin ni o wa, nibi to fori pamọ si lẹyin ti Sunday Igboho le kuro nilu Igangan nibẹrẹ ọdun yii.

Sunday Igboho ati Seriki Fulani

Ibrahim, tii se ọmọ Seriki, to ba BBC Yoruba sọrọ ni irọ ni ọrọ tawọn araalu n sọ pe baba oun lo ran awọn Fulani lati lọ kọlu wọn nilu Igangan.

O wa n gbarata pe awọn ko mọwọ-mẹsẹ nipa isẹlẹ naa, to si n beere pe ki ni awọn eeyan tun n fẹ lẹyin ti wọn ti le awọn kuro nilu.

''lẹyin ti wọn ti le wa nilu, ṣe wọn tun fẹ ka kuro nile aye ni?''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gbogbo igbiyanju BBC Yoruba lati ba Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo sọrọ lori isẹlẹ yii lo ja si pabo.

Idi ni pe alukoro fun ileesẹ Ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Adewale Osifeso ko gbe ipe wa lati sọ ohun ti wọn mọ nipa isẹlẹ naa, titi di igba ta fi n se akojọpọ iroyin yii.

Àkọlé fídíò, Wakili tẹẹ rí yẹn kìí ṣe ẹran rírọ̀, ó ń díbọ́n ní o - Iba Gani Adams

Kini Gomina Seyi Makinde sọ lori ikọlu yii?

Gomina ipinlẹ Oyo Seyi Makinde naa ti da si ọrọ to wa nilẹ.

O ni oun ti gbọ iroyin buruku nipa ikọlu to waye ni Igangan ati pe oun ti pe awọn ara ilu pe ki wọn fi ọkan balẹ.

O ṣalaye pe awọn agbofinro ti kapa iṣẹlẹ naa.

Lọwọlọwọ, akọwe ẹgbẹ idagbasoke Igangan, Lawal Akeem fi to BBC leti pe, awọn n ṣe ipade pẹlu ọga ọlọpaa agbegbe naa.