Ológun Sani Abacha
Àwọn àsìkò tó lààmìlaaka nínú ayé olóògbé
Ó ti pé ogún ọdún ti ológun Sanni Abacha ti kú
O fí ipa darí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí iṣèjọba rẹ̀ sí kú fún títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú
kòlàkòsagbe ní ọ̀rọ̀ Abacha jẹ nílù rẹ̀. Ààrẹ Muhammadu Buhari to bẹ lórí àléfà to jẹ ológun nigbà kan ri, ti fí àwọn aṣeyorí kan jìí, wípé o ṣe ojú pópó, o mú ìdàgbàsókè bá ètò-ẹ̀kọ́ àti ètò ìlèra.
Èyí ni àwọn ǹkan ti ó ṣe lójú ayé rẹ̀:
- ogúnjọ́ osù Agẹmọ1943
Kano Nàìjíríà
Abi ologun Sanni Abacha ni Ipínlẹ̀ Kano, ìhà aréwá Nàìjíríà - 1963
Kaduna Nàìjíríà
Jáde nílé ẹ̀kọ́ ologun ti Kaduna, o tun lo gboyè kún ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì - 1965
Nàìjíríà
Fẹ́ Maryam Jiddah níyàwó. Tí tọkọtayà náà bí ọmọ mẹ́wàá, tí ọ̀kan nínú wọn sì pada dí - 1967-72
Ìhà Gúúsù Nàìjíríà
Abacha jagun fún Nàìjíríà nígbà ogun Biafra, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ni gòkè nínú ìpò iṣẹ́ ológun - 1983
Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà
Ó bọ́ sí ojú táye nítorí ipa tí kó nínú ìdìtẹ̀ gbàjọba tó wáyé lọ́jọ́ kọkandílọ́gbọ̀n oṣu Ọpẹ́, tí wọn fi lé ìjọba alágbádá Ààrẹ Sheu Shagari kúrò lórí àléfà ti Muhammadu Buhari sì dí ààrẹ ológun - 1985
Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà
Wọn dìtẹ̀gbàjọba yọ Ọgágun Buhari ti Abacha pẹ̀lú náà lọ́wọ́ sí tí wọn sì fí Ọgágun Ibrahim Babangida, lẹyìn náà ló tún gba ipò gíga lẹnú iṣẹ́ ológun - Ọjọ́ kejìlá oṣù okúdù1993
Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà
Ètòn ìdìbò àwa-ara-wa tí gbogbo ènìyan ti ń retí wáye, tí èsì ìdìbò sì tí n wòye pé oníṣòwò olówó kan Moshood Abiola, tí ọgágun Ibrahim Babangida sì fagilé e - Ògún1993
Abuja, Nàìjíríà
Abacha lo jẹ mínísítà fún ètò ààbò lẹ́yìn tí Babangida yẹ̀ba tó sí yan ìjọba fìdí hẹẹ́ tí Ernest Shonekan sì jẹ́ ààrẹ - ọjọkẹtàdínlogún, Béélú1993
Abuja, Nàìjíríà
Shonekan kòwé fipò sílẹ̀, ó sì gbé ìjọba fún Abacha, èyí tí ọ̀pọ̀ ènìyàn gbàgbọ́ pé o tún jẹ ìṣọ̀tẹ̀gbajọba míìràn, ìṣèjọba rẹ̀ kún fún títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú, àti gbígbogun ti eni to ba sọ̀rọ̀ lòdì sí ìjọba rẹ̀. - 1994
Nàìjíríà
Moshood Abiola to gbagbọ pé òun lòun jáwé olúbori, kéde ara rẹ wọn sì sọọ sẹ́wọ̀n - 1995
Ogoni Nàìjíríà
Gbogbo àgbáyé ló bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣejọba Abacha tí wọn sì yọ Nàìjíríà kúrò nínú àjọ commonwealth, pá àwọn àjàfẹtọ́ àwọn Ogoni tó lòdì sí ìṣèjọba rẹ̀, lááàrin wọn ni Ken Saro-Wiwa - 1996
Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà
Wọn yan Abacha gẹ́gẹ́ bíi alága ECOWAS - Èrèlé1998
Sierra Leone
Abacha ran àwọn ọmọogun Nàìjíríà lọ sierra Leone láti dìtẹ̀ gbajọba ológun kí ó sì fi ìjọba alagbádá tí ológun tí le ni ọdun kan sẹ́yìn - ọjọ́ kẹ̀jọ oṣu okúdù1998
Abuja, Nàìjíríà
Abacha kú ikú ọkan, wọn sì sin-in lọ́jọ́ kan náà. Nàìjíríà sún sí ìpò ìjọba alágbádá lẹyìn ọdún kan
Olùkópa
olóòtú: Yemisi Adegoke
olùmúgbòòrò:Olawale Malomo
a'selọ́jọ̀: Olaniyi Adebimpe
Orisun Àwòrán: AFP, Getty Images, Nigeria High Commission.
