Prince Harry and Meghan: Ọmọbakùnrin Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí, Harry àti ìyàwó rẹ̀ bímọ tuntun

Meghan and Harry (file photo)

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọmọọbakunrin Harry ati iyawo rẹ Meghan Markle ti polongo ọmọbinrin tuntun jojolo ti wọn ṣẹṣẹ bi.

Ninu atẹjade ti tọkọ-taya naa fi lede ni wọn ti sọ wi pe ni ayọ ati alaafia ni ọmọ awọn keji wọle wẹrẹ fun wọn.

Atẹjade naa ni orukọ ọmọ tuntun naa ni Lilibet "Lili" Diana Mountbatten-Windsor, ti wn bi ni owurọ Ọjọ Kẹrin, Oṣu Kẹfa, ọdun 2021.

Tọkọ-taya fikun wi pe layọ ati alaafia ni iya ati ọmọ wa lọwọlọwọ, ti inu wọn si dun pẹlu iroyin ayọ naa.

Ninu ọrọ rẹ, Ọmọọbakunrin Harry ni idi ti awn fi sọ ọmọ tuntun jojolo naa ni Lilbet ni pe nigba ti Ọbabinrin Elizabeth wa ni kekere o ṣoro fun lati pe orukọ ara rẹ , ti baba rẹ si ma a n pe e ni Lilibet bi oun fun arar rẹ ṣe le pe orukọ ara rẹ.

Harry ati Meghan

Oríṣun àwòrán, Misan Harriman/The Duke and Duchess of Sussex

Lati igba naa wa ni wọn ti n Ọbabinrin Elizabeth ni Lilibet, ti ọk rẹ Duke ti Edinburgh to jade laye laipẹ yii naa n pe bẹẹ gẹgẹ bi orukọ to ni ifẹ si.

Bakan naa ni Ọmọọba Harry fikun pe awọn tun sọ orukọ ọmọ naa ni Diana lati fi bu ọla fun iya oun to papoda ninu ijamba ọkọ ni dun 1997, nigba ti Harry wa ni ọmọ ọdun mejila.

Ọmọọbabinrin Charlotte to jẹ ibatan Lili, to si jẹ ọmọ ẹgbọn Harry naa n jẹ orukọ Diana lati bu ọla fun mama wọn to papoda naa.

Prince Harry and Meghan under a tree

Oríṣun àwòrán, Sussexes

Ọjọ Ayajọ ololufẹ lagbaye, Valentines Day ti ọdun 2021 yii ni Ọmọọba Harry ati iyawo rẹ kede pe awọn n reti ọmọ keji jojolo laipẹ.