TB Joshua biography: Tí kìí bá ṣe rélùwéè tó bàjẹ́ lójú ọ̀nà, iṣẹ́ ológun ní kò bá ṣe

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPEI
Kii se iroyin mọ pe Wolii Temitope Balogun Joshua ti dagbere faye lẹni ọdun mejidinlọgọta.
Amọ o yẹ ka mọ ohun kan tabi meji nipa oloogbe naa, tii se gbajumọ ojisẹ Ọlọrun kaakiri agbaye.
Ọjọ Kejila osu Kẹfa ọdun 1963 ni wọn bi ojisẹ Ọlọrun naa nilu Arigidi Akoko nipinlẹ Ondo.
Akọsilẹ ta ri ko jọ nipa igbe aye agba wolii naa lori ayelujara loju opo Wikipedia fi han pe ọpọ isẹlẹ manigbagbe lo waye lasiko to n bọ nile aye.
- Wòlíì TB Joshua sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ lọ́jọ́ Satide tó kú - Ìjọ COAN
- Ẹ wo ọ̀rọ̀ àwọn Wòlíì tó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ saájú nípa làásìgbò EndSARS
- Wo ọ̀rọ̀ tí TB Joshua sọ tó mú kí Youtube àti Facebook kọjú ìjà sí i?
- TB Joshua, Apostle Suleman, Odumeje, D.K Odukoya 'ń gun orí òkè àdúrà nítorí COVID-19'-Wò báwọn èèyàn fi wò wọ́n
Lara rẹ ni pe osu mẹẹdogun, eyiun ọdun kan ati osu mẹta ni wolii Joshua lo ninu iya rẹ, ki wọn to bii.
Bakan naa ni ori ko ọmọ tuntun jojolo naa yọ lọwọ iku ojiji ni ọjọ keje ti wọn bi nigba ti ibugbamu kan waye ni ibudo iwakusa kan to wa lẹba ile awọn obi rẹ.

Oríṣun àwòrán, TB Joshua Ministries
Se ni ariwo bu gbamu, ti okuta si fọn kan orule ile wọn, amọ ọba oke sọ ọmọ naa, ti ko si fara pa.
Nigba to n rin, TB Joshua bẹrẹ ile ẹkọ alakọbẹrẹ nile ẹkọ St Stephen Anglican nilu rẹ laarin ọdun 1971 si 1977.
Nigba to wa nile iwe girama, pasitọ kekere ni wọn maa n pe Temitope nitori ifẹ to ni si bibeli amọ Joshua ko pari ile ẹkọ girama rẹ.
Oniruuru isẹ ni Joshua se ko to jẹ eeyan laye, lara rẹ ni kiko igbẹ adiẹ nile ọsin adiẹ kan.
Bakan naa lo tun maa n seto ile ẹkọ bibeli fun awọn ọmọde, to si tun maa n lọ sile ẹkọ bibeli lọwọ irọlẹ.
Joshua gbero lati dara pọ mọ ileesẹ ologun amọ erongba rẹ yii lo ja si asan nigba ti ọkọ reluwe to wọ bajẹ lọna, lasiko to n lọ sile ẹkọ awọn ologun.
Nigba to ya lo ri iran ọrun nibi to ti gba ifami ororo yan pe ko da ijọ kan silẹ, eyi to se lọgan, to si pe orukọ ijọ naa ni The Synagogue Church Of All Nations ( SCOAN).
O si le ni olujọsin bii ẹgbẹrun mẹẹdogun to maa n peju sibi isin lọsọọsẹ ninu ijọ naa, ti wọn si maa n wa lati oniruuru orilẹede jakejado agbaye.
Isẹ ami ati iyanu ti TB Joshua se nile aye:
Oludasilẹ ijọ SCOAN naa lawọn eeyan kan ni o se ọpọ "isẹ iyanu ojukoroju" ko to jade laye, ti awọn alawọ dudu ati funfun si maa n ya wa sile ijọsin naa fun adura ati isẹ iyanu.
Awọn "isẹ iyanu'ni wọn lo da lori awọn ailera ti ko se wosan loju lasan, to fi mọ ọgbẹ ara, ti wọn si tun ni o wo arun asekupani HIV/AIDS lara awọn eeyan kan.
Bakan naa ni iroyin tun gbalẹ lasiko kan pe Joshua maa n lo omi kan to ti ya si mimọ lati sisẹ iyanu lara awọn eeyan to ni ipenija ara bii awọn arọ, afọju, aditi fun iwosan.
Awọn eeyan miran ni aabo to daju wa fun awọn, ti awọn ba ti lo 'omi iye' ọhun, ti wọn si tun fun awọn ti ko le wa sinu ile ijọsin naa mu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Aláìmọ̀kan àti òmùgọ̀ ló ń pè fún ìdásílẹ̀ Yorùbá Nation - Aregbesola
- Gbogbo ǹkan tí à ń ṣe láti jà fún ''Yoruba Nation'', ìjà àwọn bàbá wa là ń gbé - Sunday Igboho
- Àgbẹ̀ míì tún fara gbọgbẹ́ ìbọn ní Igangan láti ọwọ́ afurasí darandaran
- Ìjọba ẹ ṣọ́ra! gbígbégilé ojú òpó Twitter tako ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ Naijiria - Gómínà Ṣeyi Makinde
- Ìwádìí tí bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí Olùkọ́ lu akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn án pa
- Ìjọba àpapọ̀ kéde ìjìyà fún àwọn tó ṣì n lo Twitter ní Naijiria
- Mọ̀ si i nípa ìtàn eégún Gelede àti pàtàkì eégún náà sí àwọn obìnrin nílẹ̀ Yoruba
- Wo àwọn nkán tó ṣẹlẹ̀ níbi ìwọ́de Yoruba Nation tó ti wáyé sẹ́yìn
Koda, lọdun 2013, eeyan mẹrin ni wọn tẹ pa ninu ijọ SCOAN to wa ni Ghana nigba ti isin kan to se nibẹ mu ki ọpọlọpọ ero ya wa, ti inu ijọ naa ko si le gba wọn.
Bakan naa ni ariwo gba ilẹ kan nigba ti Joshua kede pe omi iye oun le wo arun Ebola to n pa eeyan lojiji san.
O wa gbe igo omi iye bii ẹgbẹrun mẹrin ati owo to to ẹgbẹrun lọna aadọta Dọla ransẹ si orilẹede Sierria Leone, ti arun Ebola ti n ba wọn finra.



















