Farmers-Herders Crisis: Ohun ìbànújẹ́ ló sẹlẹ̀ ní Igangan, ìjọba, ẹ dìde bí o ti yẹ- Oba Lamidi Adeyemi

Igangan

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Oba Adeyemi

Alaafin ti Oyo, Oba Lamidi Adeyemi ti banujẹ́ gidi lori isele isekupani to waye ni ilu Igangan ni ijoba ibile Ariwa Ibarapa ni ipinle Oyo to wa ni guusu Iwo oorun Naijiria.

Laaro ọjọ Aiku ni iroyin ibanuje naa gba igboro kan pe awọn agbebọn kọlu Igangan nibi ti wọn ti sun ọpọlọpọ ile nina ti wọn si pa awọn mii.

Koda, wọn sun aafin Oba Ashi ti ilu Igangan.

Bode Durojaye to jẹ adari ẹka eto ifitonileti fun Aafin Oba Lamidi Adeyemi lo fi atẹjade naa sita.

O ni Kabiesi ni asiko ti to ki ijọba koowa gbajumọ ọna abayọ si i soro eto aaabo yii lẹyẹ o sọka.

Bakan naa lo banuje lori ipo ti ọrọ ẹlẹyamẹya de duro ni Naijiria ni eyi to yẹ ko jẹ agbara orilẹ-ede yii sugbọn ti ko ri bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Snail Slim Soap: Wo ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú lílo ọ̀ṣẹ tí wọn fi omi ìgbín ṣe láti fọ ojú?

Aalfin Oyo gba awọn ẹsọ alaabo lati samulo awon ara ilu ati ọpọlọ pipe awọn iolugbe ileto kọọkan.

Oba Lamidi Adeyemi ni pe laisi eto aabo to mọyan lori, ko le si idagbasoke kankan paapaa ninu eto ọrọ aje.

Kabiesi ni ki ijọba ni ẹka ksskan gbe igbesẹ to kan lati daabo bo awọn ara ilu to n se ijọba le lori.

Àkọlé fídíò, Tunde Gbadamosi: Kìí ṣe Tinubu ní ipò ààrẹ̀ tọ́ sí, ìgbà wo ní ìtan ajá ń kan lèmọ́mù?

Àgbẹ̀ míì tún fara gbọgbẹ́ ìbọn ní Igangan láti ọwọ́ afurasí darandaran

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni agbẹ miran tun ti fara gba ọgbẹ ọta ibọn nilu Idiyan, lẹba ilu Igangan, lagbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo, lati ọwọ afurasi Darandaran.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Punch ti salaye, ọkunrin kan tii se ara orilẹede Benin, Kaptain Kaston ni afurasi darandaran yinbọn mọ lẹba oko rẹ.

Ọkunrin agbẹ naa, tii se ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ti wọn yinbọn mọ ni ejika, ni wọn tun sa ni oniruuru ọgbẹ ni gbogbo ara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ariwo Kaston to n pa pẹlu irora, ni awọn ero ọna to n kọja lọ gbọ, ti wọn si sare gbe digba digba rele iwosan.

Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ, oludasilẹ eto idagbasoke fun ilu Igangan, Oladiran Oladokun salaye pe ọjọ Ẹti ni isẹlẹ naa waye.

Àkọlé fídíò, Adebayo Shittu: Èmi kò ṣẹ Abiola Ajimobi nígbà ayé ẹ, òun ló ṣe mi ṣùgbọ́n.....

"Awọn afurasi ọdaran mẹta lo kọlu oloogbe naa lẹba oko rẹ ladugbo Abojukopo nilu Idiyan, ti wọn si sọ fun pe ko gbọdọ kede pe Fulani lo kọlu oun."

Bakan naa ni aburo ọkunrin naa, Pascal Kaston naa ni wọn ti fi isẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti, ti wọn si ti wa sibi isẹlẹ naa lọjọ Ẹti.

"Wọn yinbọn mọ, ti wọn si tun fi ada ṣa. Wọn ko ge ọwọ rẹ amọ ọpọ ọgbẹ wa ni ọwọ rẹ.

O laju nile iwosan laarọ oni, ti ara rẹ si ti n ya diẹdiẹ.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí
Amin iyasọtọ kan

Àwọn agbébọn fi ìbọn fọ́ ẹnìkan l'étí, wọ́n tún jí oníṣòwò kan gbé lọ

Agbebọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn eeyan ijọba ibilẹ Dambatta nipinlẹ Kano ti fidirẹmulẹ pe awọn afurasi agbebọn kọlu wọn , ti wọn si gbe ọkunrin oniṣowo kan lọ.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe ni nkan bi aago mẹwa aabọ owurọ ni Ọjọbọ ni ilu Kore, to wa ni ijọba ibilẹ naa, ni awọn agbebọn naa wọle, ti wọn si n yinbọn.

Wọn ni ibọn naa ba obinrin kan ati ọmọ rẹ.

Bakan naa ni wọn sọ pe eeyan mẹfa ni wọn tu kọlu .

Botilẹ jẹ pe ko si ẹni to ku, iroyin sọ pe ibọn ba ọmọ kekere kan ni eti.

Awọn olugbe ilu naa sọ pe ko si oṣiṣẹ alaabo kankan to wa ni arọwọto lati doola wọn lasiko ti awọn agbebọn n ṣiṣẹ ọwọ wọn.

Wọn sọ pe ọpọ eeyan ni ẹru ba, ti awọn kan si sa wọ inu igbo lọ.

Àkọlé fídíò, Teachers retirement age and years of service: Ìrírí àwọn àgbà olùkọ́ ṣì wúlò fún àwa ọ̀dọ́

Alaga ijọba ibilẹ Dambatta, Muhammad Abdullahi Kore sọ pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye, to si sọ pe Emmanuel ni orukọ ẹni ti wọn ji gbe ọhun.

O ni oniṣowo ni ọkunrin naa ni ilu Kore.

Ninu iroyin mii, inu ibanujẹ ati ọfọ ni awọn eniyan ilu Magami ati Mayabaya ni ijọba ibilẹ Gusau nipinlẹ Zamfara wa, lẹyin ti awọn agbebọn kọlu wọn.

Ọjọru ni wọn sọ pe awọn agbebọn naa pa eeyan mẹtadinlogun, ati awọn agbẹ, ko to di pe wọn ko awọn ẹran ọsin wọn lọ.

Àkọlé fídíò, Magaret Jimoh: Èrè díẹ̀ ti tó mi níbi oúnjẹ ti mò ń tà- Maggie Rice

Ninu oko ni awọn agbẹ naa wa nibi ti wọn ti n ṣiṣẹ, ki ikọlu naa to waye.

Ẹnikan ti ori ko yọ ninu ikọlu naa, amọ ti ko fẹ ki a darukọ rẹ sọ pe awọn ti sin oku eeyan mẹsan-an lara wọn.

Gbogbo igbiyanju BBC lati ba agbẹnusọ ọlọpaa ni ipinlẹ Zamfara sọrọ lo ja si pabo.