FRSC: Ẹ gbé ìbọn fún àwọn ọmọ àjọ ẹ̀sọ́ ojú pópó- Emir Ilorin

Ẹ gbé ìbọn fún àwọn ọmọ àjọ FRSC- Emir Ilorin

Emir ilú Ilorin àti alága àwọn lọ́balọ́ba ní ìpínlẹ̀ Kwara Alhaji Zulu Gambari tí tí tẹpẹlẹmọ́ pé ó ṣe pàtàkì kí ìjọba àpapọ̀ gbé ìbọn fún àwọn ẹlẹ́sọ̀ ojú pópó.

Ó ní èyí ṣe pàtàkì kí àwọn èsa àbò ojú pópó lé máa dá ààbò bo ara wọn lọ́wọ́ àwọn kọ̀rọ̀sìlú ènìyàn lójú pópó.

Emir sàlàyé ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tí adarí ẹkùn RS8 tó jẹ́ olú ilé iṣẹ́ àjọ náà ni ìlú Ilorin Corp Marshal Clement O. Oladele ṣàbẹ̀wò si ààfin rẹ̀.

Emir Zulu Gambari sàlàyè nǹkan tó ti kojú sáájú kí wọ́n tó ṣe ìdásílẹ̀ àjọ FRSC ló ìbẹẹ̀rẹ̀ ọdún 1990's.

Lẹ́yìn tí wọ́n dá àja náà sílẹ̀ tán ìrírí kan wáyé ni lásìkò tí àwọn ọmọ àjọ náà ń mójútó ìlú kan nípiìńlẹ̀ Oyo lópòpónà Ogbomoso.

Àkọlé fídíò, Magaret Jimoh: Èrè díẹ̀ ti tó mi níbi oúnjẹ ti mò ń tà- Maggie Rice

Ọba náà ni òun gbóríyìn fún àwọn àjọ náà lórí nǹkan ti wọ́n ṣe lọ́jọ́ náà lọ́hun àti pé ìwà akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni wọ́n hù.

Àkọlé fídíò, Adebayo Shittu: Èmi kò ṣẹ Abiola Ajimobi nígbà ayé ẹ, òun ló ṣe mi ṣùgbọ́n.....

Ó ní lásìkò tí òun bá wọ́n sọ̀rọ̀ ni òun mọ̀ pé àwọn nǹkan ribiribi ni wọ́n ń kójú.

Pàápàá jùlọ àwọn onímótò tí wọ́n ń ya ìpánle èyí sì n fi wọ́n sínú ewu.

Emir ìlú Ilorin sọ pé láti àsìkò náà ni òun tí bẹ̀rẹ̀ sí ni pè fún fífún àwọn àjọ ẹlẹ́sọ̀ ààbò ojú pópó ni ìbọn pàápàá jùlọ àwọn tó máa ń yíká fún ààbò.

Ó wá tẹpẹlẹ mọ pé fífún wọn ni ìbọn láti máa ṣààbò ara wọ́n ṣe pàtàkì jùlọ lásìkò yìí nítori bi ọ̀rọ̀ èètò ààbò ṣe n lọ ní orílẹ̀-èdè.