Civil war Tweet: Àwọn ọmọ Nàìjíríà ké sí Twitter pé kó gbé ìdájọ́ Trump lé Ààrẹ Buhari, ṣùgbọ́n Twitter ní kò jọọ́

Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/Muhammadu Buhari

Ni Ọjọ Iṣẹgun ni awọn alaṣẹ ikanni ikansiraẹni abẹyẹfo Twitter ti kọkọ yọ ọkan lara awọn atẹranṣẹ ti aarẹ Buhari fi si oju opo rẹ lori ikanni naa, @Mbuhari.

Aarẹ Buhari gbe atẹjade awọn ọrọ kan to sọ ninu eyi to ti fi ikils ranṣẹ sawọn to fẹ da orilẹede Naijiria ru ti wọn si n dana sun awọn ohun alumsni ajumsni orilẹede Naijiria pe, "nnkan ariigbọdọ wi kan n bọ lọna fun wọn laipẹ..."

Aarẹ sọ ọrọ naa lẹyin ijiroro rẹ pẹlu alaga ajọ eleto idibo ni Naijiria, INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu lori bawọn eeyan kan ṣe n dana sun awọn ileeṣẹ ati dukia ajọ INEC lawọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria.

Twitter yọ ọkan lara awọn ọrọ to sọ naa nibi to ti sọ pe "pupọ awọn to n ṣiwa hu bayii kere jọjọ lati mọ ọwọja ifẹmiṣofo to waye lasiko ogun abẹlẹ Naijiria"

"Awa ti a wa loju ogun fun ọgbọn ọdun, ti a fara wina ogun abẹle naa yoo ṣe ohun to tọ siwọn gẹgẹ bi o ṣe tọ si wọn."

Àkọlé fídíò, Adebayo Shittu: Èmi kò ṣẹ Abiola Ajimobi nígbà ayé ẹ, òun ló ṣe mi ṣùgbọ́n.....

Kini ohun ti twitter sọ?

Ileeṣẹ Twitter ni awọn ko lee fofin de aarẹ Buhari pe eegun rẹ ko gbọdọ suyọ lori ikanni naa nitori ni ibamu pẹlu awọn ofin to de lilo ikanni ikansiraẹni naa, Aarẹ Buhari ṣi lanfani ikilọ diẹ sii ki wọn to gbe igi lori ojuopo rẹ

wọn ni ijiya to tọ fun ohun to ṣe bayii naa ni ki wọn yọ abala atẹjade rẹ ti ko ba ofin ikanni naa mu.

Sugbọn Twitter ṣalaye pe bi aarẹ ba n tẹsiwaju lati maa tapa si awọ̀n ofin rẹ awọn yoo kuku gbẹsẹle oju opo rẹ ni o.

Ki lawọn ọmọ Naijiria n sọ?

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti gbe pẹrẹgi kana pẹlu aarẹ lori atẹjade to fi sita naa ninu eyi ti wọn ti tọka si bo ṣe mẹnuba ogun abẹle ninu atẹjade naa, ninu eyi ti ẹgbẹlẹgbẹ eeyan ti ku gẹgẹ bi pe aarẹ n gbero ati tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ.

Aworan ojuopo Fayose

Oríṣun àwòrán, Twitter

Awọn kan ke si Twitter lati gbegile oju opo Aarẹ Buhari.

Wọn ni atẹjade ti aarẹ fi sita naa" fi erongba ati ṣe awọn kan ni ijamba" han eyi ti wọn ni o tako ofin elo Twitter ti ileeṣẹ ikansiraẹni naa fi silẹ.

Aworan ojuopo twitter Naijiria kan

Oríṣun àwòrán, Twitter/screenshot

Lara awọn to ti bs si gbangba lori ọrọ naa ni gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe to ni igbesẹ ti Twitter gbe naa fihan pe "aarẹ Buhari ko lagbara kan to le lo lori ikanni ayelujara"

Aworan ojuopo twitter Naijiria kan

Oríṣun àwòrán, Twitter screenshot

O bere ninu atẹjade tirẹ nibẹ pe, "igba wo gan ni aarẹ Buhari yoo lo agbara rẹ gẹgẹ bii apaṣẹ waa lati fi oju Twitter ri mabo" fun yiyọ atẹjade rẹ kuro lori ikanni wọn.

Aworan ojuopo twitter Naijiria kan

Oríṣun àwòrán, Twitter/screenshot

Awọn ero awọn ọmọ Naijiria miran ree:

Aworan ojuopo twitter Naijiria kan

Oríṣun àwòrán, Twitter/screenshot

Aworan ojuopo twitter Naijiria kan

Oríṣun àwòrán, Twitter/screenshot