Corornavirus in Nigeria: Ènìyàn 28 kú lẹ́yìn ààrùn Coronaviris láàrín ọjọ́ kan

Oríṣun àwòrán, Lagos
Ó kéré tán ènìyàn méjídínlọ́gbọ̀n ló tí pàdánù ẹ̀mí wọn lááàrín wákàtí mẹ́rínlélógún sọ́wọ́ ààrùn corornavirus.
Àwọn ènìyàn yìí kú jákèjádò àwọn ilé ìwòsàn àládáni àti ti ìjọba jákèjádò orílé-èdè Nàìjíríà.
Èyí jẹyọ nínú àkọsílẹ̀ àjọ tó ń mójú tó àjàkálẹ̀ ààrùn ní Nàìjíríà tí wọ́n sì gbe jáde sójú òpó twitter àjọ náà.
- Akeredolu pè fún wíwọ́gilé iléègbìmọ̀ aṣòfin àgbà, àwọn aṣofin àgba ní tẹnu ara rẹ̀ ló ń sọ
- Ọ̀gá àgbà NECO papòdà- Kà nípa bí Ọjọ́gbọ́n Obioma ṣe kú
- Nǹkan kò burú tó báyìí ní ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn tí mo kọrin pé kí Ọlọ́run bá wa tún Nàijíríà ṣe- Funmi Aragbaye
- A ti rí ọmọ ilé kéú 11 míì nínú àwón tí agbébọn jí gbé ní ìpínlẹ̀ Niger
Àtẹ̀jáde náà fi hàn pé láàrín ọgbọ̀n ọjọ́, osù kaarun sí ọjakọkànlélagbọ̀n oṣù karun ni èyí ṣẹlẹ̀.
Sáájú àsìkò yìí ni àjọ yìí ti kéde pe ènìyàn mẹ́jọ péré ló kú ni àwọn ilé tó n kó àwọn aláàrùn covid-19 sí jákèjádò Nàìjíríà.
Wọ́n ni lẹ́yìn tí àwọn ènìyàn yìí lùgbàdì ààrùn covid-19 ni wọ́n jẹ́ ìpè Ọlọ́run.

Àwọn ènìyàn méjìdínlélọ́gbọ̀n tó ti kú gẹ́gẹ́ bi NCDC ṣe sọ pọ̀ sì láti orí ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjì àti métàlélọ́gọ́ta ni ìbẹ̀rl inú oṣù kaarún sí ẹgbẹ̀rún méjì àti ènìyàn mọ́kàndílọ́garún ni òpin oṣù tó kọja.
Bákan náà ni àwọn ènìyàn tó ti gba ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn àyẹ̀wò ààrùn coronavirus ni ẹ̀ẹ̀mejì ti wọ́n ko si ni ààrùn náà mọ́ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì àti ìgba le díẹ̀.
Ẹ̀wẹ̀, ìwádìí tún fi hàn pé àwọn tó lùgbàdì ààrùn Covid-19 láàrín ọjọ́ kíní oṣù karun si ọjọ́ kọkànlélagbọ̀n oṣù karun ti peléké síi.
Lásìkò tó n sọ̀rọ̀ lórí àwọn àyípadà yìí olórí ẹ̀ka àlámójútó àjọ NCDC Elsie Ilori sọ fún àwọn akọroyin pé iye àwọn ènìyàn tó kú yìí kàn fò sókè láàrín wákàtí mẹ́rìnlélógún nítori pé ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀ ni ko fí àwọn àkọsílẹ̀ wọn sọ́wọ́ tẹ́lẹ̀.
Ilorin fi kun pé, wọ́n fi akọsílẹ̀ wọn ránṣẹ̀ lẹ́yìn ti àjọ NCDC kan nípa pé kí àwọn ìpínlẹ̀ fi àkọsílẹ̀ wọn ránṣẹ́ lórí ọ̀rs ààrùn covid-19

Oríṣun àwòrán, Lagos













