Ikire Apomu bank robbery: Adigunjalè kọlu bánkì méjì àti àgọ́ ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, @File Foto
Ikọ adigunjale ṣe ikọlu si banki meji ni Ikire ati Apomu nipinlẹ Ọsun
Ọjọ buruku, eṣu gbomimu ni Ọjọbọ jẹ nilu Ikire ati Apomu, nipinlẹ Ọsun, lasiko ti awọn adigunjale yabo banki meji.
Bo tilẹ jẹ pe tòsí ara wọn ni wọn wa, ijọba ibilẹ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni awọn ilu mejeeji wa. Ikire ni olu ilu fun ijọba ibilẹ Irewọle, Apomu si jẹ ti ijọba ibilẹ Isọkan.
- Agbébọn pa ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá nígbàkan rí, Christopher Deja
- Lẹ́kṣọ́rà fásitì FUOYE kan tún kó sí gbaga ẹ̀sùn aṣemáṣe pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́
- Ènìyàn 28 kú lẹ́yìn ààrùn Coronaviris láàrín wákàtí 24 ní Nàìjíríà
- Ọwọ́ ikọ̀ Amọtẹkun ba Mutiu Abdul-Rasheed, afurasí tó ń ta ẹ̀yà ara èèyàn ní Ibadan
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ ìjọba, dẹndẹ ìyà yóò jẹ orí yín bí Nàìjíríà bá pínyà pẹ́rẹ́, toríi Yoruba Nation! - Oluwo
Bakan naa ni awọn adigunjale naa kọlu agọ ọlọpaa kan.
Ileesẹ ọlọpaa sọ pe lootọ ni awọn ikọlu naa waye.
Iroyin sọ pe bi aago marun-un aabọ irọlẹ si mẹfa ni awọn adigunjale naa dé, ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn bo ṣe wù wọn lati da ibẹru silẹ.
Awọn ileesẹ iroyin abẹle sọ pe First Bank to wa ni Ikire, ati Access Bank to wa ni Apomu ni wọn ja lólè.
Iroyin tun sọ pe First Bank ni wọn kọkọ kọlu, ki wọn o to lọ si Access.
A gbọ pe ilu Ikoyi ni awọn adigunjale naa gba wọlé, ti wọn si pin ara wọn si ọna meji, ki wọn o to kọlu agọ ọlọpaa ni Ayedaade.

Oríṣun àwòrán, @Fisayo Soyombo
Lẹyin naa ni wọn wọ awọn banki naa, ti ọkan lara wọn wa ni agbegbe Oke-Ola.
Banki keji wa ni ibi ti ko jina si aafin Akire ti ilu Ikire.
Sugbọn awọn adigunjale naa gba oju ọna Orile-Owu salọ nigba ti awọn ọdẹ ibilẹ ati ọlọpaa koju wọn.
Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i le sọ iye owo ti awọn adigunjale naa gbe lọ, àmọ́ eeyan bi i mẹrin ni wọn pa ninu ikọlu mejeeji.
- Twitter kò dá sí ọ̀rọ̀ IPOB àti Nnamdi Kanu, bó ṣe wù wa la ṣe lè darí Nàìjíríà- Lai Mohammed
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ ìjọba, dẹndẹ ìyà yóò jẹ orí yín bí Nàìjíríà bá pínyà pẹ́rẹ́, toríi Yoruba Nation! - Oluwo
- Aàrẹ Muhammadu Buhari gba àmì ẹ̀yẹ Adarí tó dára jùlọ
- UNILAG jáwé lọ gbélé ẹ fún àwọn olùkọ̀ méjì tí BBC tú àṣírí wọn nínú fíìmù 'Sex For Grades'
- Bíi ti UK, USA, Germany, France lẹ ó lè ṣe ẹ̀sìn tó bá wù yín yàlàyòlò ní orílẹ̀èdè Yorùbá Nation - Igboho
- Wo bí àwọn arúgbó ṣe le jẹ́ ìgbádùn ètò tí Buhari fi lọ́lẹ̀ fún wọn














