Obasanjo: Obasanjo ní bí àwọn adarí ṣe ń ṣàkóso wa ń pa ìràwọ̀ ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ọlọpọlọ pípe tó ń dá bírà lágbáyé

Oríṣun àwòrán, other
Aarẹ orilẹede Naijiria nigbakanri, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti pariwo sita pe ilẹ to n ṣan fun ibanujẹ ati ipayinkeke ni Naijiria bayii dipo wara ati fun oyin.
Oloye Ọbasanjọ ṣalaye wi pe lootọ wara ati oyin ni Eleduwa fi ṣe anfani fun orilẹ-ede yii ṣugbọn awọn aṣiwaju ati adari to n ni ko jẹ ki ileri Eleduwa o ṣẹ mọ orilẹede Naijiria lara.
Oloye Ọbasanjọ woye ọrs yii nibi ayẹyẹ ifilọlẹ iwe kan ti wọn kọ nipa rẹ eleyi to waye ni gbọngan nla Oluṣẹgun Ọbasanjọ Presidential Library nilu Abẹokuta ipinlẹ Ogun.
- Èmi ò lè káwọ́ gbera kí Nàìjíríà bàjẹ́ lójú mi o, Alaafin sọ̀rọ̀ sókè
- Aṣọ ìkọ̀kọ̀ ni ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó mi, mi ò kí ń sá a níta gbangba - Saheed Balogun
- Ẹ leè rán àwọn Àgùnbánirọ̀ lọ sójú ogun, wọ́n kójú òsùwọ̀n - Ọ̀gá àjọ NYSC
- Ṣé lóòtọ́ ni wọ́n fipá bá akẹ́kọ̀ọ́ UNILORIN lòpọ̀ títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lára rẹ̀?
- 'Títí ọdún mẹ́wàá gbáko! A o ni kó Àlùbósà lọ sílẹ̀ Ibo, kí la rí gbà nígbà tí ojà Sasha jóná?'
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ ìjọba, dẹndẹ ìyà yóò jẹ orí yín bí Nàìjíríà bá pínyà pẹ́rẹ́, toríi Yoruba Nation! - Oluwo
O ni gbogbo awọn alẹnulọrọ ninu idagbasoke orilẹ-ede Naijiria ṣi lanfani ati yi kadara buruku yii pada o nitori ko si ẹya, ẹkun tabi ipinlẹ ti eeyan lee de lorilẹede Naijiria ti ko ni ri awọn ọlọpọlọ pipe.
O fi kun un pe pẹlu bi nnkan ṣe ri lorilẹ-ede Naijiria bayii, ko si bi awọn ọmọ Naijiria to jẹ ọlọpọlọ pipe ṣe lee ṣe aṣeyọri nile.
Amọṣa o ni gbogbo agbaye lawọn ọmọ Naijiria ti n ṣe daradara.
Obasanji ni awọn bii Akin Adeshina to n dari Banki idagbasoke Afirika, ADB; Mohammed Barkindo to n dari ajọ awọn orilẹ-ede elepo rọbi lagbaye, OPEC;
O tun darukọ: Benedict Oramah to n dari banki fun idagbasoke karakata soke okun, Afrexim Bank, Ngozi Okonjo-Iweala to n dari Ajọ karakata lagbaye, WTO ati Amina Mohammed to jẹ igbakeji akọwe agba ajọ iṣọkan agbaye, UN.
Aarẹ orilẹede tẹlẹ lorilẹede naa ni o yẹ ki awọn to n tukọ orilẹ-ede Naijiria beere idi ti awọn eeyan wọnyi ati omilẹgbẹ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria miran fi n da bi ẹdun, rọ bi owe lagbaye ṣugbọn ti orilẹ-ede Naijiria fi da bo ṣe da.
O ni o daju pe bi awọn eeyan wọnyi ba wa lorilẹ-ede Naijiria ni, irawọ wọn yoo ti wọmi, iyẹn bi a ba tilẹ le gburo wọn rara.
- UNILAG jáwé lọ gbélé ẹ fún àwọn olùkọ̀ méjì tí BBC tú àṣírí wọn nínú fíìmù 'Sex For Grades'
- Wo bí àwọn arúgbó ṣe le jẹ́ ìgbádùn ètò tí Buhari fi lọ́lẹ̀ fún wọn
- Òṣìsẹ̀ 170 tí Ajimobi lé ni Lautech ni ń o gbà padà, owó osù márun wọ́n yoo di sísan- Gómínà Oyo
- Pope Francis ṣe àyípadà òfin nínú ìjọ Aguda, ó sọ nkan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àlùfáà tó bá ní ìbálòpọ̀ kò tọ́
- Ìdí rèé tí Twitter kò fi le gbé ìdájọ́ Trump lé Ààrẹ Buhari
- Àwọn adigunjalè pa èèyàn bí mẹ́rin, níbi ìkọlu bánkì méjì ni Ikire àti Apomu














