Onion traders: Àwọn Hausa yari pé wọn o ní ta Àlùbósà fún Ibo mọ torí ààbò

Awon onisowo alubosa ni iha Ariwa Naijiria ti so kiko alubosa lọ sí iha Guusu - Ila Oorun rọ bayii.Awọn adari ẹgbẹ alalubosa at'awọn ontaja ni awọn ṣe ipinu yii torí aisi abo.

Aliyu Isa ni tita alubosa fún wọn tún di ọjọ mii ọjọ ire."A o ni kó alubosa fawon ilẹ Ibo afi bi abo to daju ba wa koda ko to ọdun mẹwa".

Ni Ọgbọn ọjọ oṣu karun ọdun 2021 ni awọn jaguda já ọkọ ajagbe meji to kun fún alubosa ni ìjọba ibilẹ Mbaise, ipinlẹ Imo.

Àkọlé fídíò, Adebayo Shittu: Èmi kò ṣẹ Abiola Ajimobi nígbà ayé ẹ, òun ló ṣe mi ṣùgbọ́n.....
Ọkọ Alubosa

Koda fidio oko alubosa naa ti wọn ja gba gba ori ayelujara kan. Isa sọ fún BBC pe ipinu awọn lati ma kó alubosa wo iha Guusu-Ila Oorun ko lee lopin titi di igba ti ijọba ba da alafia kikun pada koda o ni wọn o kọ bí yóò bá tó ọdún mẹwàá.

O ni ohun tó ṣẹlẹ si ọja awọn at'awọn eeyan wọn ni ọjọ Aiku ọsẹ to kọja ti wọn wọ wahala pẹlu bi awọn janduku ṣe lu wọn ti wọn ji gbogbo alubosa naa.

Bí aiko alubosa sita yóò ṣe pa awọn eeyan laraAwọn àgbẹ to n gbin alubosa ni awọn ara ilẹ Ibo nikan ni igbesẹ náà yoo pa lara.Ni ti àwọn to n ta a, won yoo kan darii kiko alubosa naa lọ si ibomiran ni.

"Onion traders cut supply from northern Nigeria" to southeast after Mbaise attack

"A o tẹsiwaju lati maa ko lọ fun iha Guusu - Iwọ Oorun Naijiria.Torinaa, a o fikun iye ti a n ko lọ sibẹ, bakan naa, a n ko lọ sí Niger Republic, Burkina Faso, Ghana ati Ivory Coast".

O ni torinaa, awọn o kuta pe awọn o ko lọ fún àwọn Ibo."Nkan mii to tun ṣẹlẹ ni pé ina jo alubosa to to ọpọlọpọ biliọnu naira torinaa ìyẹn gan yóò din iye alubosa ti a n ko jade lọwọ".

Fun idi eyi, Aliyu Isa ni oun ngbadura ki alafia jọba toripe aisi abo kii ṣe ohun to dara rara o si n sakoba fún ọpọ eeyan.

Iru iṣẹlẹ yii to ti waye ri ati ọna abayọNinu oṣu kẹta ọdun 2021, ìṣòro ọwọn gogo ounjẹ náà da awọn ara Guusu laamu torí wọn fi ẹsun kan pe awọn Hausa di ọna, wọn kọ lati ko ounjẹ wole.

Iroyin sọ pe apapọ ẹgbẹ awọn to n sin maalu ni Naijiria ti wọn wa ni iha Ariwa lo fi dina awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ki wọn ma le ko ounjẹ lọ sí ilẹ Ibo.

Amo idi eyi ko fi bẹẹ ye ọ si gba ijọba apapọ lati da sii ki idena naa le kuro .

Koda, ibinu ẹgbẹ yìí gan ta ba ilẹ Yoruba tori iwe kan to jade latowo ẹgbẹ wọn ni wọn n binu pe awọn o ri nkankan gba gẹgẹ bii gba ma binu fun ọja awọn ti wọn padanu nigba ti ọja Sasha ni Ibadan, ipinlẹ Oyo jona raurau.