UNILORIN: Akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Ilorin dágbére fáyé lẹ́yìn tí àwọn kan fipá báa lòpọ̀

UNILORIN

Oríṣun àwòrán, @im_sirmayor

Akẹkọọ imọ nipa eto ọgbin kan ni fasiti Ilorin, Olajide Omowumi ti dagbere faye lẹyin ti iroyin ni awọn kan fi ipa ba lopọ titi ti ẹmi fi bọ lẹnu rẹ.

Oloogbe ọhun to jẹ ọmọ bibi ilu Oke-Opin Ekiti, nipinlẹ Kwara ni a gbọ pe o ku lẹyin iṣẹlẹ ifipabanilopọ naa ni Tanke, to wa niluu Ilorin.

Nigba ti BBC kan si agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ajayi Olasunkanmi lori iṣẹlẹ ọhun, o ni lootọ ni akẹkọọ naa ti jade laye.

Olasunkanmi sọ fun BBC pe "Lootọ ni a ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ootọ si ni arabinrin naa ti ku, a si ti gbe oku rẹ lọ sile igbokusi, ṣugbọn a ko tii le sọ boya ni ṣe ni wọn fi ipa ba lopọ."

"O digba ti awọn eleto ilera ba ṣe iwadii ti wọn ti wọn si fi idi rẹ mulẹ pe ifipabanilopọ lo ṣekupa a, ṣugbọn a ko tii le sọ bayii titi di igba ti wọn ba pari iṣẹ ti wọn."

Olasunkanmi fi kun pe awọn naa ti bẹrẹ si n tọpinpin awọn to wa nidii iṣẹlẹ ọhun.

Àkọlé fídíò, Adebayo Shittu: Èmi kò ṣẹ Abiola Ajimobi nígbà ayé ẹ, òun ló ṣe mi ṣùgbọ́n.....

Nigba to n ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe jẹ, o ni ọdọ ẹgbọn oloogbe ọhun lo n gbe.

O ṣalaye pe "Ọdọ ẹgbọn rẹ lo n gbe, ẹgbọn rẹ ọhun de lati ibi iṣẹ lo ṣakiyesi pe wọn ti tilẹkun yara ọdọ wọn."

"Ẹgbọn rẹ naa ti pe ẹrọ ilewọ rẹ ṣaaju ṣugbọn ipe ọhun ko wọle, o ba ilẹkun yara wọn ni titi pa ṣugbọn lẹyin to ri anfani lati wọ inu yara naa tan lo ṣakiyesi pe aburo rẹ ti dagbere faye."

Gẹgẹ bo ṣe sọ, wọn ba ni ihoho ọmọluabi ti wọn ti de ọwọ rẹ sẹyin, bẹẹ ni wọn fi aṣọ di ẹnu rẹ ṣugbọn o ti di oloogbe.

Agbẹnusọ ọlọpaa naa pari ọrọ rẹ pe Ihoho lo wa, oju egbo si wa loju ara rẹ pẹlu iwe kekere kan ti wọn kọ akọle kan si pe "UNILORIN kii dariji eeyan."

O sọ pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ okodoro ohunn ti wa niddi iṣẹlẹ.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí