Unilorin Rape Case: Ẹ̀bí Blessing Olajide tí wọn pa ṣàlàyé bí ikú rẹ̀ ṣe jẹ́
BBC Yoruba de ile awọn obi ati alagbatọ Blessing Olajide, akẹkọọ Fasiti Ilorin, ti iroyin ni wọn fipa balopọ titi doju iku, ko ṣeeṣe keeyan ma ba wọn sọkun.
Akọroyin gbiyanju titi amọ Baba Blessing kọ lati fọhun ẹwẹ ẹgbọn rẹ to tun jẹ alagbatọ to n gbe lọdọ rẹ lo ba BBC Yoruba sọrọ.
Arabinrin Dupe Shittu to n gbe ni Tanke, Ilorin sọ ẹkunrẹrẹ iru eeyan ti Blessing jẹ nile ati nita.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wòlíì TB Joshua sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ lọ́jọ́ Satide tó kú - Ìjọ COAN
- Ìtàn ayé TB Joshua tó lo ọdún kan àti oṣù mẹ́ta nínú ìyà rẹ̀
- Aláìmọ̀kan àti òmùgọ̀ ló ń pè fún ìdásílẹ̀ Yorùbá Nation - Aregbesola
- Gbogbo ǹkan tí à ń ṣe láti jà fún ''Yoruba Nation'', ìjà àwọn bàbá wa là ń gbé - Sunday Igboho
- Àgbẹ̀ míì tún fara gbọgbẹ́ ìbọn ní Igangan láti ọwọ́ afurasí darandaran
- Ìjọba ẹ ṣọ́ra! gbígbégilé ojú òpó Twitter tako ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ Naijiria - Gómínà Ṣeyi Makinde
- Ìwádìí tí bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí Olùkọ́ lu akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn án pa
- Ìjọba àpapọ̀ kéde ìjìyà fún àwọn tó ṣì n lo Twitter ní Naijiria
- Mọ̀ si i nípa ìtàn eégún Gelede àti pàtàkì eégún náà sí àwọn obìnrin nílẹ̀ Yoruba
- Wo àwọn nkán tó ṣẹlẹ̀ níbi ìwọ́de Yoruba Nation tó ti wáyé sẹ́yìn
"Bíi akọbi ọmọ ni oloogbe Omowumi gẹgẹ bi emi ṣe maa n pe e jẹ si mi. O ti to nkan bii ọdun mẹfa to ti n gbe pẹlu mi".
O ṣalaye pe nkan bii ago mẹjọ aarọ ọjọ keji oṣu kẹfa ti oun jade nile, Blessing lo si ilẹkun fun oun to si ti i pada torinaa oun fi i si ile ni.
"Nigba ti mo maa fi de ni irọlẹ, oku Blessing ni mo ba ninu ile".
Dupe ni oun lọ si ọdọ ọlọpaa kiakia lati pe wọn ki wọn wa wo nkan to ṣẹlẹ, wọn dẹ wa, wọn wa ni kawọn pe ọkọ agboku lati wa gbe e.
"Blessing jẹ ọmọ ti ko lagbaja, to fẹran lati maa ka iwe ẹ, o fẹran ọmọde, ko na awọn ọmọ mi ri o ko dẹ si iṣẹ tẹẹ fun Blessing ti ko le ṣe.
(Alagbatọ Blessing kan sẹkun): Mo n rọ gbogbo agbaye ki wọn ba mi wa ẹni to pa ọmọ mi jade".
Awọn obi Blessing ni awọn o fura si nkankan, ko si fi ẹjọ ẹnikankan sun awọn.
Amọ o ni lootọ ni "a ba iwe pelebe kan ti wọn fi si i lara, wọn kọ 'Unforgiveness from University of Ilorin' wọn tun fi kaadi idanimọ rẹ naa si i lara gẹgẹ bii ọmọ ileewe Unilorin".
Ẹbi ni awọn ọlọpaa ati alaṣẹ ileewe Fasiti Ilorin ti wa yọju si awọn wọn si n gbe igbesẹ to tọ.
Ẹwẹ nigba ti BBC Yoruba kan si agbodegba fun Fasiti Ilorin, Ọgbni Kunle Akogun jẹ ko di mimọ pe bo tilẹ jẹ pe kii ṣe inu ọgba ileewe ni iṣẹlẹ naa ti waye, awọn aṣoju ileewe ti lọ ṣebẹwo ibanikẹdun si ẹbi oloogbe to jẹ akẹkọọ onipele ikẹrin ninu imọ ẹkọ Eto Ọgbin.
O gba imọran pe ki awọn akẹkọọ maa sọ ibi ti wọn ba n lọ fun akẹgbẹ wọn ki wọn si mọ iru ọrẹ ti wọn yoo maa ko.
Awọn akẹgbẹ Blessing atawọn akẹkọọ Unilorin ti n ṣe iwọde lati ja fun idajọ ododo lori iku Blessing.

Oríṣun àwòrán, Onaopemipo Christopher Owolabi

Oríṣun àwòrán, Olanrewaju Oke

Taló fipá bá Blessing Olajide lòpọ̀ tó tún pa á?
Ní alẹ́ ọjọ́bọ ní ariwo gbòde lórí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú tó ṣẹ̀ sí ọmọ fásìtì Ilorin kan tó wà ní ipele ẹ̀kọ́ kẹta níbi tó ti ń kọ ẹ̀ka láti ní ms nínú ètò ọ̀gbìn.
Ìròyìn sọ pé, ọmọ náà tí àwọn ọlọ́paàá fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olajide Omowumi Blessing to wá láti ìlú Oke- Opin níjọba ìbílẹ̀ Ekiti nípínlẹ̀ Kwara.
Ilé tí òun àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ jọ ń gbé ní agbègbè Tanke-Oke Odò ní ìròyìn náà tí ṣẹ̀ lọ́jọ́ Isẹgun.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ajayi Okasanmu tó jẹ́ agbẹ̀nusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Kwara náà fi ì
dí ọ̀rs náà múlẹ̀ tí ó ṣì fi kun pé àwọn ti bẹ̀rl ìwádìí láti mú ẹni tó ṣe iṣẹ́ aburú náà.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé ti Okasanmi ṣe: Ọmọ náà ń gbé pẹ̀lú ẹgbọ́n rẹ̀ obìnrín , ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ló padà dé láti ibiṣẹ ní nǹkan bi aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ lọ́jọ́ Isegun tí ó bá àbúrò rẹ̀ nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀.
"Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní sáájú ní òun tí n pé aago rẹ̀ títí sùgbọ́n tí ó ń dùn tí kò sí ẹni tó gbée."
Okasanmi ni sàlàyé pé, nígbà ti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ dé láti ibiṣẹ̀ ló bá ilẹ̀kùn ilé ní títì tí kò sì rí ààyè wọlé gbogbo bi ó ṣe kàn ìlẹ̀kùn tó.
Àwọn ará àdúgbò ló bá a já ìlẹ̀kùn tó fí ráyè wọlé.
" Báyìí ni gbogbo wọn bá òkú olóògbé náà nínú ilé tí wan de ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sẹyìn tí wọ́n sì fi àsṣọ díi lẹ́nu pẹ̀lú.
Wọ́n báa ní ìhòhò ọmọlúàbí, tí oonírúurú àpá sì wà lójú ara rẹ̀, ẹnú àti àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ mííràn.
" Bákan náà ni wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ ìwé kan tí wọ́n gbé síi láyà tí wọ́n sì kọọ́ síbẹ̀ pé "Unilorin kìí dáríjí ní"
"Àwọn ènìyàn yìí ló fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn àgọ ọlọ́pàá F'Division léti ni agbègbè Tanke , tí àwọn náà sì yà fótò gbogbo nǹkan tí wọ́n rí níbẹ̀."
- UNILAG jáwé lọ gbélé ẹ fún àwọn olùkọ̀ méjì tí BBC tú àṣírí wọn nínú fíìmù 'Sex For Grades'
- Pope Francis ṣe àyípadà òfin nínú ìjọ Aguda, ó sọ nkan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àlùfáà tó bá ní ìbálòpọ̀ kò tọ́
- Àwọn adigunjalè pa èèyàn bí mẹ́rin, níbi ìkọlu bánkì méjì ni Ikire àti Apomu
- Èmi ò lè káwọ́ gbera kí Nàìjíríà bàjẹ́ lójú mi o, Alaafin sọ̀rọ̀ sókè
- A tí ń gbé ìgbésẹ́ láti kó àwọn tó ja bọ́ọ̀sì akẹ́kọ̀ọ́ gbà ní Ondo- Komisonna Bolaji Salami
- 'Àwọn ọmọ ogun Naijiria pa ọmọ ẹgbẹ́ ISWAP 50 ní Borno'
Ọlọ́pàá bákan náà ló gbé òkú ọmọ náà lọ sí ilé ìwòsàn ìkọ́ni ìjọba apapọ̀, (UITH) fún àyẹ̀wò"
Ẹ̀wẹ̀, gómìnà ìpińlẹ̀ Kwara Abdulrahman Abdulrazaq ni ó jẹ́ nǹkan tó báni lójijì tí ó si kani láyà láti gbọ́ irú ìṣẹ̀lẹ̀ aburú báyìí.
Gómìnà ni ó jẹ́ nǹkan tó bani lọ́kàn jẹ́ gidi tí kò sì yẹ kí irú ẹni tó ṣe abur yìí máa gbé láàrín àwọn ènìyàn, nítorí náà ó rọ gbogbo ará ìlú láti dídé giri lòdì sí irú ìwà aburu yiìí láwùjọ.
Gómìnà fi kun nínú àtẹ̀jáde tí akọ̀wé rẹ̀ Rafiu Ajakaye fọwọ́sí rọ àwọn ẹbi ọmọ náà láti fọwọ́ wọ́nú lórí ọ̀rọ̀ náà àti pé ìjọba kò ní dákẹ́ lórí ọ̀rọ̀ náà.
AbdulRazaq ní òun kò ní faramọ́ irú ìwà bẹ́ẹ̀ láwùjọ.
- Ìjọba Nàìjíríà ṣàfikún owó aàbò fáwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera
- Aṣọ ìkọ̀kọ̀ ni ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó mi, mi ò kí ń sá a níta gbangba - Saheed Balogun
- Nàìjíríà ti di orílẹ̀èdè tó ń ṣàn fún ìbànújẹ́ àti ìpayínkeke- Obasanjo
- Makinde ṣàfikún owó oṣù àwọn àgùnbánirọ̀ ìpinlẹ Ọyọ láti ẹgbẹ̀rún márùn ún sí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún náírà
- Ọwọ́ EFCC tẹ gbajúmọ̀ 36 tó n ṣe 'Yahoo-yahoo' ní Eko























