Ọwọ́ EFCC tẹ gbajúmọ̀ 36 tó n ṣe 'Yahoo-yahoo' ní Eko

EFCC

Oríṣun àwòrán, @EFCC

Iroyin abẹle sọ pe laarin ọjọ keje, ọjọ kọkandinlogun ati ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un, ni ọwọ ẹka ajọ EFCC nipinlẹ Eko tẹ wọn.

Awọn afurasi naa, Segun Abiola, Gabriel Ebube, Amoo Tunmise, Anidugbe Mofoluwatu, Victor Enuesike, Precious Godwin, Oluwaseun Afolabi, Tolulpoe Amos, Jane Egonu, Precious Anizoba.

Awọn miran tun ni Abayomi Olanrewaju, Adekunle Oshunsanya, Tang Jude, Ejobi Prince, Kuti Adebayo, Fagbemi Micheal, Salau Oluwasegun, Bellow Azeez, Lare Awoniyi David, Damilare Sikiru, Jayesimi, ati Samson Ismaila.

Daniel Udoh, Prince Emezue, Raheem Sodiq, Lucky Godday, Ismail Abiodun, Christian Chidera, Ezekiel Ephagba, Collens Ndubuisi,

Awọn miran ni: Peter Odiegwu, Ojo Oluwadamilare, Abayomi Ademola, Otor Junior, Temitope Aiyelabowo, Daniel Oluwafemi ati Chukwuebuka Iroulo. Agbenusọ fun ajọ naa, Wilson Uwajaren sọ fun awọn akọroyin pe awọn agbegbe bi Ikorodu, Sangotedo, Eko Atlantic, Ebute, ni ọwọ ti tẹ wọn.

Àkọlé fídíò, Magaret Jimoh: Èrè díẹ̀ ti tó mi níbi oúnjẹ ti mò ń tà- Maggie Rice

Awọn nkan bi ọkọ ayọkẹlẹ, iwe irinna silẹ okeere, kọmputa 'laptop', ati foonu ni wọn gba lọwọ àwọn afurasi naa. Uwajaren sọ pe ni kete ti iwadii ba pari lori ẹsun ti wọn fi kan wọn, ni wọn yoo gbe wọn lọ sile ẹjọ.

Àkọlé fídíò, Adebayo Shittu: Èmi kò ṣẹ Abiola Ajimobi nígbà ayé ẹ, òun ló ṣe mi ṣùgbọ́n.....