Ogun rape: Bàbá ọdún 52 fi ipá bá ọmọ rẹ̀ ọdún mẹ́wàá lòpọ̀

Obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọkunrin kan, Kayode Adeniyi ẹni ọdun mejilelaadọta tim ko si gba ọlọpaa lọri ẹsun pe o fipa ba ọmọbinrin rẹ lopọ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, sọ ninu atẹjade kan to fi sita pe ọwọ tẹ ọkunrin naa lẹyin tawọn kan mu ẹjọ rẹ wa si agọ ọlọpaa to wa lagbegbe Agbado.

Ẹgbọn mọmọ ọmọdebinrin naa to jẹ ọmọ ọdun mẹwaa lo mu ẹjọ naa lọ si agọ ọlọpaa.

Ẹgbọn mọmọ ọmọdebinrin naa ṣalaye fawọn ọlọpaa pe baba ọmọbinrin ọhun fi ipa mu un wọle nibi to ti fi pilo di i lẹnu ki o to fi ipa ba a lopọ.

Lẹyin naa ni a gbọ pe DPO, CSP Kehinde Kuranga ran awọn ọlọpaa lọ sibẹ nibi ti wọn ti fi ọwọ ofin mu ọkunrin naa.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye siwaju si Ọgbẹni Adeniyi jẹwọ pe lootọọ loun fi ipa ba ọmọ naa lopọ.

O ni ọkunrin naa jẹwọ ọbẹ loun fi ṣẹru ba ọmọdebinrin ọhun latii rii pe oun ba ni sun ni tipa.

Ọgbẹni Oyeyemi sọ pe iwadii fihan pe ọkunrin naa ti maa n fipa bawọn ọmọbinrin mẹta lopọ ki ọwọ palaba rẹ to segi bayii.

Ẹwẹ, kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Ajogun ti paṣẹ pe ki ajọ to n ri si ọrọ ẹbi tẹwọgba ẹjọ naa.