Toyosi Adesanya: Ohun tó ṣẹlẹ̀, gbogbo wa ló kàn àmọ́ ṣe ni à ǹ fọ aṣọ ìdọ̀tí wa níta gbangba,

Toyosi Adesanya ati Laide Bakare

Oríṣun àwòrán, adesanyatoyosi_ileyemi/nstagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọrọ ẹsun ti wọn fi kan gbajumọ osere tiata Yoruba, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Ijesha ti n fun awọn oniruuru ẹgbẹ osere tiata lanfaani lati maa sọrọ soke.

Ọpọ awọn osere tiata yii to ti sọrọ saaju bii Iyabo Ojo, Yomi Fabiyi, Foluke Daramola, Bukky Black, Mr Latin ati Saheed Balogun, ni wọn n gbena woju ara wọn lori isẹlẹ naa.

Amọ awọn osere tiata miran to tun sẹsẹ sọrọ sita lori isẹlẹ naa ni Toyosi Adesanya ati Laide Bakare.

Àkọlé fídíò, 'Iṣẹ wá burẹkẹ síi tórí Covid-19, owó ńlá ló wà nínú dídáná sun òkú, ìsìnkú Zoom, Live streaming'

Awọn osere tiata mejeeji naa ni wọn gbe fidio kan soju opo Instagram wọn lati da si ohun to n waye lagbo tiata naa.

Àkọlé fídíò, hhhhhh

Toyosi Adesanya, to gbẹnu sọrọ lorukọ awọn mejeeji salaye ọrọ pọ ninu awọn ti awọn fẹ sọ sugbọn awọn ko le sọrọ, ti wọn ba lọ bulọọku awọn.

Toyosi ni tawọn pọ ju lagbo tiata Yoruba, ohun to sẹlẹ ti sẹlẹ amọ se ni awọn tun n fọ asọ idọti awọn nita gbangba, ti onikaluku wa n sọ ohun to wu lori isẹlẹ to waye.

"Awọn to ni ka se afọmọ agbo tiata wa ko parọ rara, pe awọn osere ti ko dantọ ti pọ ju, pe awọn to n ba agbo wa jẹ ti pọ ju, se wọn parọ ni.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

O ti wa debi pe o yẹ ki gbogbo wa ronu bayii nitori agbo tiata Yoruba kii se ohun amurele mọ, ki awa ta ni orukọ lati agbo ere tiata Yoruba si mọ ara wa.

Wọn wa n pe awa ni Yeyebrity, ẹ jọọ se bi awọn asiwaju wa se se e ree ni bii ọgbọn ọdun sẹyin, ti awọn kan si ni awọn gbọdọ sọrọ pẹlu tipatipa.

Toyosi ni o dabi ẹni pe awọn ko mọ bi nnkan to sẹlẹ naa se wuwo si eyi to seese ko ba agbo tiata Yoruba jẹ patapata, awọn ti wọn si bajẹ laarin awọn gan mọ pe awọn bajẹ.

Àkọlé fídíò, Wùnmí Toríọlá: Toyin Abraham kìí se ọ̀gá mi nínú tíátà

O wa fara ya lori awọn eeyan ti kii jade taara ta lati sọrọ amọ ti wọn maa n sa pamọ sabẹ ọrọ mii tawọn eeyan kan ba sọ sita lati maa ju oko ọrọ miran.

"Idile nla kan soso lo yẹ ka jẹ. Nnkan to sẹlẹ yii ba wa gidi nitori ẹni to ba ni idanilẹkọ gidi nipa isẹ tiata yoo mọ pe o ba wa nitori bi awọn asiwaju ti se kọ ree.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ojoojumọ ni idarudapọ n waye, to si yẹ ka kọkọ bọ ni ogun onijẹsa de yii naa, ka to wa maa wa ọna abayọ nitori ohun to ba se ọrẹ rẹ, se ọ pẹlu.

Àkọlé fídíò, Bọlanle Ninalowo: Ọ̀rẹ́ lásán àti olóore mi ni Mercy Aigbe

Oju ti ọrẹ mi, oju ko ti mi, oluwarẹ ko ni ojuti ni, nitori nnkan to se Ijesha, nnkan to se gbogbo wa ni. Ko wa yẹ ki ẹnikẹnni maa wa ohun ti ko sẹlẹ jade."

Toyosi Adesanya fikun pe ko yẹ ki gbogbo awọn osere tiata to n gba ọrọ Baba Ijesha mọ ara wọn lọwọ bii ẹni gba igba ọti de debi pe awọn onworan awọn ni yoo maa gba awọn nimọran.

Amọ o ni eyi ti n ri bẹẹ nitori awọn ko serious, ko si si ifọwọsowọpọ laarin ara wọn, to si n beere pe se ọna abayọ si isẹlẹ to waye, eyi ti ko dara ree?

"Kii se ọna abayọ ree rara ni a n se yii nitori o ti n di nnkan miran, yoo si dara ki a maa sọrọ pẹlu ọpọlọ pipe nitori a ni ẹgbẹ ati asaaju.

Àkọlé fídíò, Mama Rainbow: iṣẹ́ tíátà kò ta sánsán mọ́ bíi ti ayé àtijọ́

A ti wa n ba debi pe wọn ti n bi wa pe ki ni pataki ẹgbẹ wa gan? Ẹ saanu wa, ẹ ma jẹ ko bajẹ, a ko ni ọna miran ta fi n jẹun, ẹ jẹ ka pe aaro ati ọdọfin inu wa."

Toyosi ni nnkan to sẹlẹ, nnkan buruku ni, kaka ki awọn si pe ara awọn jọ, n se ni awọn tun n ja, to si rọ awọn abiyamọ to n ja lori ọrọ yii, pe ki wọn se diẹdiẹ.

Bakan naa lo rọ wọn pe ki awọn mase ta ara awọn nu nitori eyi ko le se awọn ni anfaani.