Insecurity in Nigeria: Ẹ̀sìn Islam kò fàyè gba kí èèyàn máa san owó ìtúsílẹ̀ fún àwọn ajínigbé - Sheikh Maqari

Abuja Mosque

Oríṣun àwòrán, @dn_magazine

Eekan ẹlẹsin Islam kan, Sheikh Ibrahim Maqari ti sọ pe o lodi si ẹsin Musulumi ki eeyan maa san owo itusilẹ fun awọn ajinigbe.

Oniwaasi naa to jẹ igbakeji Imaamu agba ni Mọṣalaṣi ijọba apapọ to wa niluu Abuja ni ẹsin Islam ko faye gba ki eeyan maa san owo itusilẹ fun ajinigbe tabi ẹni to ba n gbogun ti i.

Lasiko to n sọrọ nibi akanṣẹ adura oṣu Ramadan, o ni sisan owo itusilẹ fun awọn ajinigbe yoo tubọ maa kii awọn ọdaran naa laya lati tẹsiwaju ninu iṣẹ aburu ti wọn n ṣe ni.

O ni "Ọlọrun ko faye gba ki eeyan san owo itanran fun ọta rẹ tabi ko san owo itusilẹ lati tu ẹni ti wọn ji gbe silẹ nitrori haram ni."

Nigba to n kin ọrọ rẹ lẹyin, Imaamu naa sọrọ lati inu hadith kan, nibi to ti sọ pe ojiṣẹ kan lọ ba Anọbi Muhammad (SAW), to si bere lọwọ rẹ ohun to yẹ ki eeyan ṣe ti wọn ba doju ija kọ ọ pẹlu ohun ija oloro.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, Anọbi sọ fun ọkunrin naa pe ni ṣe lo yẹ ko ba ọta naa ja kaka ko fun ni owo itusilẹ.

Àkọlé fídíò, Tóò bá fẹ́ràn àti máa pọ́n ọ̀rọ̀ tàbí èèyàn lé, ẹ̀kọ́ ráńpẹ́ yìí yóò wúlò fún ọ

Ẹnu ọjọ mẹta yii ni ṣẹlẹ ijinigbe di tọrọfọnkalẹ ni Naijiria.

Bi ẹ ko ba gbagbe, nnkan bii ọsẹ meji ṣeyin ni awọn agbebọn ji awọn akẹkọọ fasiti Greenfield gbe ni opopona ilu Kaduna si Abuja, ti wọn si ṣeleri pe awọn yoo pa awọn akẹkọọ naa lẹyin ti wọn ti kọkọ pa marun un ninu wọn, ayafi ti wọn ba gba ọgọrun miliọnu naira owo itusilẹ.

Ṣugbọn gomina ipinlẹ ọhun, Nasir Ahmad el-Rufai ti fesi pe oun ko ni owo itusilẹ kankan lati san.

Àkọlé fídíò, 'Oyenusi ló mú mi wọ ẹgbẹ́ adigunjalè kó tó di pé mo b'Ólúwa pàdé'