Strip club visit: Tíṣà mu ọtí yó ló bá kó àwọn ọmọ kíláàsì lọ ilé ijó oníhòhò

Oríṣun àwòrán, Ethan Miller
Wọn ti le olukọ imọ ẹkọ ẹrọ kọmputa ni ileewe kan to dẹru ba awọn akẹkọ nigba to mu ọti yo to si ko gbogbo wọn lọ si ile ijo awọn onihoho.
Iwa ti Ọgbẹni Richard Glenn hu "ko jẹ itẹwọgbà" rara. Wọn ti le e lọ sile kuro ni Longridge Towers School ni ilana ofin ileewe naa. Ko si ni ba wọn ṣiṣẹ fun odidi ọdun mẹta.
Ẹni ọdun marunlelaadọta ni Ọgbẹni Glenn to si gba pe oun jẹbi iwa aidaa to hu si awọn ọmọde eyi ti wọn fi le e danu.
Ni ileewe to ti n kọni yii, owo ileewe ọmọ kan to £4,850 (N2,756,433.48) ni saa kan.
Igbimọ to n koju iwa aṣemaṣe kan gbọ wipe o jẹ́ ọkan lara awọn adari to ko awọn ọdun mẹrindinlogun si ogun ninu irinajo igbafẹ ẹkọ lọ si Costa Rica lọjọ karun oṣu keje ọdun 2019.
Iroyin ni o yẹ ko wa nibẹ titi di ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kan naa ṣugbọn lẹyin ọjọ mẹfa, awọn alakoso eto naa le e kuro tori ihuwasi rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ihuwasi rẹ lasiko naa niyii:
- Biba awọn ọmọde mu ọti pọ
- O n jẹ ki awọn akẹkọọ kan mu ọti bo tilẹ jẹ pe wọn ko tii to ọjọ ori mejidinlogun ti ofin gba laye lati mu ọti.
- O tun dunkoko pe oun yoo "gba ori" ọmọ kan oun "yoo si pa omiran".
- O sọ fun ọmọ kan pe: Mo wa ninu iṣoro - waa wọ iṣoro"
- Lẹyin to dunkoko mọ ọmọ kan, o fnu ko o ni ogogo ori o si sọ fun pe "daadaa lo wa".
- O ko diẹ lara awọn ọmọ naa lọ sile ijo onihoho.
- O huwa bakan bakan si obinrin to n dari irinajo wọn lọ nigba to fẹ́ ran an lọwọ si abẹ iboji to wa.
- O bọ ara rẹ sihoho niwaju obinrin kan ninu ile itura ti wọn jọ pin, bo tilẹ jẹ pe wọn gba pe kii ṣe pe o ni eredi ikọkọ tabi fun ibalopọ".
Igbimọ aṣewadii ni o fi diẹ lara awọn akẹkọọ naa to wa ni ikawọ rẹ sinu ewu.
O fi kun un pe "ko sohun to jọ mọ ọrọ ija tabi ete ibalopọ" ninu kiko awọn akẹkọ naa lọ si ile ijo ti wọn ti maa gbe ara wọn le itan jo amọ Ọgbẹni Glenn ni ko boju mu o si lodi si ofin bi ko ṣe le ko ara rẹ ni ijanu.
- Gbogbo ẹ̀yin ẹgbẹ́ tẹ́ẹ ní ìpínu láti da ètò àbò àti àláfíà Nàìjíríà rú, ká ṣọ́ra o!
- Ìdí tí a fi lé àwọn Fulani 42 tó ya bo agbègbè Okitipupa padà sí ìpínlẹ̀ wọn - Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo
- Kò sí àwáwí fún ìwà Baba Ijesha àmọ... -Yomi Fabiyi
- Bola Tinubu: Ọlọrun kò ní gbà kí Naijiria tún la ogun abẹ́lé míràn kọjá
O ni oun ko le rantiohun to ṣẹlẹ gan tori bi oun ṣe ti yo. Wọn fi aworan awọn ọpọlọpọ tikẹẹti ọti to ra ni ile ijo ọ̀hún han igbimọ, wọn si ni o tẹ awọn lọrun pe ihuwasi rẹ lodii gbaa si ohun to tọ si akọṣẹmọṣẹ.
Igbimọ ni "ọpọlọpọ igba ni Ọgbẹni Glenn n ta gọọgọọ̀ labẹ akoso ọti torinaa ko si anfani to lee fi ṣe bi eeyan gidi tabi ṣe ggẹb bi obi ti iwulo rẹ ba yọju.
Bẹẹ si ni orilẹede ajoji lawọn ọmọ to wa ni ikawọ rẹ yii wa nibi oju ọlọmọ ko too ti wọn si dara le e fun itọsọna ati abo wọn.
Mr Glenn jẹ akọṣẹmọṣẹ olukọni ati adari irinajo ti wn ni ireti pe yoo ṣe eto ti wọn lọ fun daadaa lai si ewu to si yẹ ko mọ iwa hihuwasi rẹ.
"Lẹyin to ba ti lo ọdun mẹta ijiya rẹ nile tan, Ọgbẹni Glenn yoo nilo lati ṣẹṣẹ kọ iwe ranṣẹ pe ki wọn gbe ote ọhun kuro", igbimọ alakoso aṣemaṣe lo sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images















