Bola Tinubu: A kò ní gbà kí ìpinyà dé bá Naijiria

Oríṣun àwòrán, Jubril A. Gawat
Eekan ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Hammed Tinubu ti kilọ pe o ṣeeṣe ki ogun abẹle waye ni Naijiria ti orilẹ-ede naa ba pinya.
Tinubu lo sọ ọrọ naa nibi adura Ramadan to waye niluu Eko, nibi to ti sọ pe o san ki Naijiria wa gẹgẹ bii orilẹ-ede kan ju ko pinya lọ.
Lara awọn eeyan to ti n pe fun ipinya Naijiria ni awọn ajijagbara fun orilẹ-ede Biafra, awọn ẹgbẹ kan nilẹ Yoruba to n jẹ Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Odua atawọn araalu kan ti bi nnkan ṣe ri niluu ko tẹ lọrun.
Tinubu ni ipinya Naijiria ko ṣe itẹwọgba fun awọn ati pe oun ko nibi kankan ti oun yoo lọ ti Naijiria ba pinya.
""Emi ko ni ibi ti mo fẹ lọ, gbogbo eni to ba ti ri ogun lat eyin wa ko ni gvadura fun ogun.
Orileede Naijiria ko ni pinya, awa ko le faramọ, adura wa ni ilọsiwaju ati ọrọ fun orile-ede yii".
Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹri ọhun fi kun un pe, nnkan ko ni ṣẹnu ire ti ogun abẹle ba bẹ silẹ ni Naijiria lasiko yii nitori orilẹ-ede naa si n ba atunbọtan ogun abẹle to ti waye nigba kan ri finra.
O ni "Ọlọrun ko ni gba ki Naijiria tun la ogun abẹle miran kọja, ti a ba ni ki Naijiria pinya, o yẹ ki awọn eeyan ranti ohun ti ogun abẹle da silẹ lawọn orilẹ-ede bii Sudan ati Iraq."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ni "Irufẹ ogun abẹle bẹẹ kii tete tan nilẹ, a ko tii bọ lọwọ ohun ti ogun abẹle ti a ja kẹyin da silẹ, o dara ki wa papọ gẹgẹ orilẹ-ede kan ṣoṣo."
- Wọ́n ti wú òkú Iniobong tí wọ́n pa níbi tó ti ń wá iṣẹ́
- Kò sí ẹ̀rí tó dájú tí a lè lò láti yọ Pantami kúró n'íjọba Buhari- Ilé aṣòfin l'Abuja
- Wo ìdí tí ìjọba Naijiria ṣe fòfin de gbogbo arìnrìnàjò láti India, Brazil àti Turkey
- Orí yọ ẹ́ o Baba Ijesha tí mi ò rí fídíò èpè tí wọ́n ní ò ń ṣẹ́, ǹkan tí mi ò bá ṣe fún ẹ... - Iyabo Ojo
Tinubu pari ọrọ rẹ pe "Mi o nibi kankan ti mo le lọ ti Naijiria ba pin, ati pe ẹni to ba ti ri iriri ogun ri ko ni gbadura ki ogun abẹle miran tun ṣẹlẹ."
Lẹyin naa lo gbadura fun alekun owo ati ọrọ fun orilẹ-ede Naijiria.
Lara awọn to peju sibi adura Ramadan naa ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, igbakeji rẹ, Obafemi Hamzat atawọn oloṣelu miran nipinlẹ Eko.
- Buhari, wá nǹkan ṣe sí ètò àbò tó mẹ́hẹ ní Naijiria kó tó pẹ́ jù - Alaafin, Ooni
- Àsìkò ti tó kí wọ́n yọ Buhari lórí oyè kí àlááfíà lè padà sí Naijiria - PFN, Kukah, Ighodalo
- 'Senior' Bukky Black, ìtìjú ńlá lẹ jẹ́ fún ìran obìnrin àti ìyá- Iyabo Ojo
- Ọlọ́run Ọba ti pa ẹ̀gàn mi rẹ́, a bímọ l'Amẹrika - Lizzy Anjorin
- Ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí bíì Boko Haram ti dínkù lásìkò ìjọba Buhari- Fayemi












