Ìwọ́de àwọn olólùfẹ́ Man U fọwọ́ ago sẹ́yìn fún Man City láti gba ife ẹ̀yẹ Premier League

Ero biba lori papa isẹre Old Trafford

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Manchester United lo wa ni ipo keji ninu idije Premier League

Lẹyin tawọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ati Liverpool ti wa ni ikalẹ kaakiri agbaaye lati wo ifẹsẹwọnsẹ wọn to yẹ ko waye lọjọ keji oṣu karun un ọdun 2021, lawọn alaṣẹ idije Premier League kede pe wọn ti sun ifẹsẹwọnsẹ naa siwaju.

Idi abajọ ni pe ọgọọrọ awọn ololufẹ Man U yabo papa iṣere Old Trafford nibi ti wọn ṣe iwọde tako ẹbi Glazer to ra ẹgbẹ agbabọọlu naa lori bi Man U ṣe wa lara awọn ikọ agbabọọlu mẹfa to buwọlu iwe lati yapa lọ da idije European Super League ti ko kẹsẹ jari.

Bakan naa ni wọn lo ifẹhonuhan ti wọn ṣe lati sọ fun ẹbi Glazer pe ki wọn yọwọ lọrọ Man United pe ki wọn ta ikọ agbabọọlu naa ni kiakia.

Awọn alaṣẹ idije Premier League yoo ṣepade pẹlu Man U ati Liverpool bayii lati sọ ọjọ ti ifẹsẹwọnsẹ naa yoo waye.

Niiṣe ni ero kun ita papa iṣere Old Trafford biba, nigba tawọn kan ninu wọn rapala wọle ti wọn si duro sori papa iṣere naa.

Awọn alaṣẹ idije liigi naa sọ pe abo awọn eeyan to wa ni papa iṣere Old Trafford lọjọ Aiku lo ṣe koko.

Manchester United's game against Liverpool was postponed after fans protests at Old Trafford

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Police said groups of protestors began to gather at Old Trafford and separately at the Lowry Hotel, where the Manchester United players were staying

Iroyin tiẹ sọ pe ọlọpaa kan ṣeeṣe nibi to ti n dari awọn ololufẹ Man U to yabo papa isẹre Old Trafford.

Manchester United lo wa ni ipo keji lọwọ yii lori tabili idije Premier League, nigba ti orogun wọn, Manchester City wa loke tente.

Manchester City ko ba gba ife ẹyẹ Premier League lọjọ Aiku to ba jẹ pe Man U fidi rẹmi ti Liverpool ti ere bọọlu naa ba waye.

Bi ọrọ ṣe ri bayii, City ni lati jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ kan sii lati gba ife ẹyẹ Premier League ti saa bọọlu yii.