Coronavirus Updates: Ìjọba Naijiria fòfin de arìnrìnàjò láti India, Brazil àti Turkey nítorí Covid-19

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba Naijiria ti kede pe oun yoo fofin de awọn arinrinajo lati orilẹ-ede India, Brazil ati Turkey lẹyin ti arun Covid-19 burẹkẹ sii lawọn orilẹ-ede naa.
Ninu atẹjade kan ti igbimọ amuṣẹya to n ri si ọrọ Covid-19 ni Naijiria fi lede, wọn ni awọn fofin de awọn arinrinajo naa fun ọsẹ mẹrin gbako, bẹrẹ lati ọjọ kẹrin, oṣu ti a wa yii.
Bo tilẹ jẹ pe ijọba Naijiria ko tii ti papakọ ofurufu rẹ mọ awọn orilẹ-ede mẹta ọhun, ṣugbọn o ni awọn ko ni gba ki ẹnikẹni to ba ti bẹ awọn orilẹ-ede naa wo lati ọsẹ meji sẹyin lanfaani lati wọ Naijiria.
- Àlàyée Fídíò bí Baba Ijesha ṣe ṣe aṣamaṣe pẹ̀lú ọmọ Princess rèé
- 'Wọ́n ti pa ọ̀rẹ́ mi o, wọ́n ti sín in'! Ọ̀rẹ́ Iniobong Umoren tó dàwátì ní Akwa Ibom pariwo síta
- Buhari, wá nǹkan ṣe sí ètò àbò tó mẹ́hẹ ní Naijiria kó tó pẹ́ jù - Alaafin, Ooni
- Orí yọ ẹ́ o Baba Ijesha tí mi ò rí fídíò èpè tí wọ́n ní ò ń ṣẹ́, ǹkan tí mi ò bá ṣe fún ẹ... - Iyabo Ojo
Atẹjade naa ni "Ẹnikẹni to ba ti bẹ awọn orilẹ-ede bii Brazil, India ati Turkey wo laarin ọsẹ meji ki wọn to wa si Naijiria ko ni ni anfaani lati wọle."
"Ṣugbọn ofin tuntun yii ko kan awọn ti ọkọ baalu wọn gba awọn orilẹ-ede naa kọja."
Ijọba apapọ tun ti parọwa si awọn eeyan ilu lati ṣọra fun awọn irinajo silẹ okeere ti ko ba ṣe pataki lasiko yii, paapaa si awọn orilẹ-ede ti arun naa ti n milẹ titi.
Wọn ni igbesẹ yii ṣe pataki lati daabo awọn araalu lọwọ arun naa.
Lọwọ yii, apapọ awọn to ti ni Covid-19 ni Naijiria ti le ni 165,000, awọn 155,109 ti ri iwosan nigba ti eeyan 2,063 ti ba arun naa lọ.
- Àsìkò ti tó kí wọ́n yọ Buhari lórí oyè kí àlááfíà lè padà sí Naijiria - PFN, Kukah, Ighodalo
- 'Senior' Bukky Black, ìtìjú ńlá lẹ jẹ́ fún ìran obìnrin àti ìyá- Iyabo Ojo
- Ọlọ́run Ọba ti pa ẹ̀gàn mi rẹ́, a bímọ l'Amẹrika - Lizzy Anjorin
- Ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí bíì Boko Haram ti dínkù lásìkò ìjọba Buhari- Fayemi
- A kò bá ti lé Baba Ijesha àmọ́ kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ TAMPAN, a kò sì fọwọ́ sí ìwà tó hù - Mr Latin













