Insecurity in Nigeria: Fayemi ní ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí bíì Boko Haram ti dínkù lásìkò ìjọba Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/Muhammadu Buhari
Laisi ani ani, awọn agbesunmọmi bii Boko Haram ko ṣọṣẹ mọ bi ti tẹlẹ lati igba ti Aarẹ Muhammadu Buhari ti gori oye lọdun 2015.
Alaga ẹgbẹ awọn gomina ni Naijiria to tun jẹ gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi lo maa sọrọ yii lori eto kan niluu Eko lọjọ Abamẹta .
Fayemi ni ọpọ le maa gbagbọ, amọ o da oun loju pe igbesunmọmi ti dinku lasiko ijọba Muhammadu Buhari.
- Ayọ̀ abara tín-tín! Lizzy Anjorin bímọ sí orílẹ́èdè Amẹrika
- Senior Bukky Black, ìtìjú ńlá lẹ jẹ́ fún ìran obìnrin àti ìyá- Iyabo Ojo
- Iléeṣẹ́ aṣọ́bodè tún fi tírélà kó ìrẹsì lọ lóru mọ́jú ní Ọjà'ba nílú Ibadan
- A kò bá ti lé Baba Ijesha àmọ́ kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ TAMPAN, a kò sì fọwọ́ sí ìwà tó hù - Mr Latin
- Fr Mbaka kọ ẹ̀yìn sí Buhari nítorí kò rí nǹkan jẹ lábẹ́ rẹ̀ - Iléeṣẹ́ Ààrẹ
- Obìnrin tó n wá orí adé láti fi ṣe ọkọ pàdánù ₦51m sọ́wọ́ gbájúẹ̀ l'Eko
Gomina Fayemi pe ijọba APC ṣi niṣẹ lati ṣe lori eto abo to mẹhẹ ni Naijiria, amọ o durọ ilọsiwaju wa lori eto to niiṣe pẹlu igbesunmọmi.
Fayemi ni ''otitọ ni pe ijọba APC ṣe ọpọlọpọ ileri lọdun 2015 ki a to dori ijọba.
Eyi ti ọpọ eeyan fi fẹran wa ni ileri lati fi ọmọniyan ṣe ijọba ti a ba gori aleefa.
Ṣugbọn lati igba ti Buhari ti jẹ aarẹ orilẹede Naijiria, a ko gbọ ki awọn agbesunmọmi maa yin bọmbu bi wọn ti n yin tẹlẹ mọ.
Ti ẹ o ba gbagbe, ki APC to dori oye, wọn yi ado oloro si ile ajọ iṣọkan agbaye, UN niluu Abuja.
Bakan naa ni wọn tun yin bọmbu lawọn ṣọọṣi kan, ilu Abuja ko tiẹ ṣe lọ nigba naa.
Ṣugbọn gbogbo rẹ lo ti lọọlẹ laarin ọdun mẹrin akọkọ ijọba Buhari.''
Fayemi ni iṣoro igbesunmọmi tun ṣẹyọ nitori bi ohun ija oloro ti di tọrọ fọn kale ni Naijiria bayii.












