Baba Ijesha: Mr Latin ní àwọn kò bá ti lé afurasí náà dànù tó bá jẹ́ pé ọmọ ẹgbẹ́ TAMPAN ni

Oríṣun àwòrán, Mr Latin/eminent pictures
Ẹgbẹ awọn oṣere tiatia Yoruba ni Naijiria, TAMPAN, ti wẹ ọwọ wọn kuro ninu ọrọ Baba ijesha, lẹyin ti wọn fẹsun kan pe o ba ọmọ ọdun mẹrinla se asemase.
Aarẹ ẹgbẹ naa, Bolaji Amusan, ti ọpọ eeyan mọ si Mr latin lo kede bẹẹ, ninu fidion kan to gbe jade loju opo Intagram rẹ, nibi to ti sọ pe oṣere naa kii ṣe ọmọ ẹgbẹ awọn.
Gẹgẹ bi Mr Latin ṣe sọ, awọn eeyan kan ti n ke si ẹgbẹ naa lati le Baba Ijesha kuro ninu ẹgbẹ ọhun, ṣugbọn o ni yoo sọro fun oun gẹgẹ bii Aarẹ ẹgbẹ lati yọ ọwọ ẹni ti kii se ọmọ ẹgbẹ kuro lawo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Orí yọ ẹ́ o Baba Ijesha tí mi ò rí fídíò èpè tí wọ́n ní ò ń ṣẹ́, ǹkan tí mi ò bá ṣe fún ẹ... - Iyabo Ojo
- Ẹ má da ẹnikẹ́ni lẹ́bi, ẹ jẹ́ ká wà ní ìṣọ̀kan láti borí ọ̀tá - Tinubu
- Ìwádìí fihàn pé Baba Ijesha bá ọmọdé lòpọ̀, a kò gba béèlì rẹ̀ - Ọ̀gá Ọlọ́pàá Eko
- Wo ohun mánigbàgbé mẹ́fà nípa Gbenga Adeboye lẹ́yìn ọdún 18 tó kú
- Ọjọ́ àkọ́kọ́ tí Baba Ijesha bá ọmọ mi lòpọ̀ ní mo ti mọ̀ àmọ́ kò sí ẹ̀rí - Princess
- Ọlọ́pàá kò lè dá wa dúró, á ṣe ìwọ́de Yoruba Nation l‘Abeokuta lọ́la - Yoruba Nation Agitators
- Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn tẹ ara wọ́n pa, ariwo ẹkún sọ
- Saidi Balogun figbe ta pé wọn ń ba òun lórúkọ jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Iyabo Ojo gbé fídíò jáde nípa bí ọwọ́ ṣe tẹ Baba Ijesha
O ni "Lẹnu ọjọ mẹta yii ni awuyewuye ti n lọ lori ọrọ Ọgbẹni Lanre Omiyinka, Baba Ijesha, mo si ti paṣẹ fun ẹka ti ọrọ kan ninu ẹgbẹ wa lati fi ọrọ lede pe awa gẹgẹ bii ẹgbẹ ko fọwọ si ohun ti Baba Ijesha ṣe.
Gẹgẹ bii Aarẹ TAMPAN, ohun to yẹ ki n ṣe niyẹn, mo si ti ṣe bẹẹ.
Ṣugbọn awọn eeyan n pariwo pe ki a jawe lọ rọkun nile fun Baba Ijesha ninu ẹgbẹ, mi o lagbara lati le Ijesha kuro ninu ẹgbẹ nitori ki ṣe ọmọ ẹgbẹ TAMPAN."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Latin ni oun ko ni agbara lati le ẹni ti kii ṣe ọmọ ẹgbẹ oun kuro ninu ẹgbẹ.
Bo tilẹ jẹ pe Latin ni oṣere ni Baba Ijesha ni tootọ, o si tun jẹ apanilẹrin pẹlu, to tumọ si pe iṣẹ kan naa wọn jọ n ṣe, ṣugbọn oriṣiriṣi ẹgbẹ lo wa ti TAMPAN si jẹ ọkan lara wọn, ṣugbọn Ijesha ko si ninu ẹgbẹ TAMPAN.
Agba oṣere naa tẹsiwjau pe, ko si ẹni ti ori rẹ pe lawujọ ti yoo fọwọ si iwa ifipabanilopọ, ka to wa sọ iwa ifipa ba ọmọde lo pọ, ti yoo si ni ki ẹni to ba wu iru iwa bẹẹ ma jẹ iya to tọ labẹ ofin.
O ni "Gbogbo wa ti a jẹ baba, iya, ẹbi ati obi lo n sọ wi pe iwa yẹn ko dara, mo si jẹ ọkan lara awọn eeyan to bu ẹnu ẹte lu iwa naa."
Ki niofin TAMPAN sọ?
Latin tẹsiwaju pe ko si oun ti oun le ṣe lori iṣẹlẹ naa niwọn igba ti Baba Ijesha kii ṣe ọmọ ẹgbẹ TAMPAN ti oun jẹ Aarẹ fun.
O ṣalaye siwaju si pe to ba jẹ ọmọ ẹgbẹ oun ni wọn fi irufẹ ẹsun naa kan, awọn yoo ti kọkọ ni ko lọ rọkun nile fun igba diẹ na, titi ti awọn agbofinro yoo fi ṣe iwadii wọn lori ẹsun ọhun.
Gẹgẹ bo ṣe sọ "Ti wọn ba dajọ fun pe o jẹbi ẹsun naa, a maa yọ kuro ninu ẹgbẹ wa patapata."
- Iyabo Ojo fi ẹ̀hónú hàn ní àgọ́ ọlọ́pàá Panti láti tako béèlì Baba Ijesha
- Ẹ̀yin tí Baba Ijesha bá ọmọ tàbí àbúrò yín lòpọ̀ láìtọ́, ẹ fi ẹjọ́ ṣùn mí - Princess Comedian
- Mò ń ké tantan, tí Buhari kò bá fí ipò sílẹ̀, ìbò 2023 kò ní wáyé - Father Mbaka
- Gbogbo abiyamọ aye ẹ gba wá, wọ́n ti fẹ́ tú Baba Ijesha silẹ - Iyabo Ojo figbe ta
- Iyabo Ojo gbé fídíò jáde nípa bí ọwọ́ ṣe tẹ Baba Ijesha
"To ba dẹ jẹ pe wọn fi silẹ pe ko jẹbi, yoo lọ gba fọọmu tuntun lati darapọ ẹgbẹ wa, ti a si joko le ọrọ rẹ lori gẹgẹ bii ofin ẹgbẹ wa ṣe sọ, lati jiroro lori pe boya ka gba pada sinu ẹgbẹ tabi ka ma ṣe bẹẹ."
Lẹyin naa lo ni oun gẹgẹ bii ẹnikan ko fọwọ si iwa ti wọn fẹsun rẹ kan Baba Ijesha pe o wu.



















