Father Mbaka ń bínú sí Buhari nítorí ó kọ̀ láti fún àwọn agbaṣẹ́ṣe rẹ̀ níṣẹ́ - Iléeṣẹ́ Ààrẹ

Fr Ejike Mbaka

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adoration Ministry Enugu Nigeria

Ileeṣẹ Aarẹ ti fesi si ọrọ Alufa ijọ Aguda mimọ, Rev Fr Ejire Mbaka, lẹyin to ke si Aarẹ Muhammadu Buhari lati kọwe fipo silẹ ti ko ba le mojuto eto abo to mẹhẹ ni Naijiria.

Ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ fun Aarẹ lori ọrọ to n lọ ati ipolongo, Garba Shehu fi lede, o ni Fr Mbaka kii ṣe ohun to n fi ara rẹ pe fun awọn araalu.

Garba ni Mbaka kọ ẹyin si Aarẹ Buhari lẹyin ti ko ri nnkan ja jẹ labẹ rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bo ṣe sọ, Mbaka ko awọn agbaṣẹṣe mẹta kan wa sọdọ Aarẹ nile ijọba to wa niluu Abuja ṣugbọn Aarẹ kọ lati fun awọn agbaṣẹṣe rẹ niṣẹ akanse, eyi ti ko dun mọ Mbaka ninu.

Fr Ejike Mbaka

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adoration Ministry Enugu Nigeria

O ni "Yoo jẹ ohun iyalẹnu fun awọn ara ilu lati ri Fr Mbaka to n sọ pe ki Aarẹ kọwe fi ipo silẹ, tabi ki awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin yọ nipo lẹyin to ti kọkọ ṣatilẹyin fun Aarẹ yii kan naa nigba meji ọtọtọ."

"Ohun to ṣẹlẹ ni pe Fr Mbaka pe fun ipade kan pẹlu Aarẹ, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe Mbaka ko awọn agbaṣẹṣe mẹta lẹyin wa sibi ipade naa, to si sọ pe ki wọn fun awọn agbaṣẹṣe naa ni iṣẹ fun atilẹyin ti oun ti ṣe fun Aarẹ ṣaaju."

Shehu ni gẹgẹ bii ẹni to maa n bọwọ fun ofin ati alakalẹ ijọba, Aarẹ Buhari taari ohun ti Mbaka beere si ẹka ti ọrọ naa kan ṣugbọn igbesẹ naa ko dun mọ Mbaka ninu, lo jẹ ko kọ ẹyin si Aarẹ.

Àkọlé fídíò, Ogbomoso: Ẹbọ ọkùnrin àti obìnrin tí kò ní ìbálòpọ̀ rí ni wọ́n rú dènà ogun Fulani

Amugbalẹgbẹ Aarẹ naa pari ọrọ rẹ pe idi ti awọn ko ṣe fi aworan Mbaka lede lasiko to ko awọn agbaṣẹṣe naa wa sile ijọba ni pe, awọn ko fẹ ki awọn alatilẹyin rẹ binu si.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju ni Fr Mbaka ti kọkọ n ṣalatilẹyin fun Aarẹ Muhammadu Buhari, koda o sọ nigba kan ri pe Ọlọrun lo ran Buhari lati tun Naijiria ṣe.

Mbaka sọ lọdun naa lọhun pe "Lẹyin ti awọn eeyan Ọlọrun gbadura, ni Ọlọrun gbọ adura naa to si fi Muhammadu Buhari ṣọwọ si wa."

"Yala ẹ korira rẹ ni o tabi ẹ fẹran rẹ, apẹrẹ pe adura wa ti gba ni Buhari jẹ."

Alufa naa sọ fun awọn to n tẹti si iwaasu rẹ lọjọ naa pe, itẹsiwaju Naijiria ni Buhari n fẹ ati pe awọn kan ko ba ti ta Naijiria ni gbanjo to ba jẹ pe awọn to n ṣe ijọba tẹle lọ ṣi wa lori alefa.

Àkọlé fídíò, Olugbon of Igbon: ‘Rubber Stamp’ làwọn aṣòfin àpapọ̀, wọn kò ṣojú aráàlú

Ṣugbọn Mbaka yi ọrọ rẹ pada lẹyin ti ikọlu lemọlemọ bẹrẹ si n waye kaakiri Naijiria.

Eyii to mu ko sọ pe ki Aarẹ kọwe fipo silẹ tabi ki awọn aṣofin yọ bi ẹni yọ jiga ki ileeṣẹ Aarẹ to fesi.

Atẹjade ti ọọfisi Aarẹ fi lede naa ti da họwuhọwu silẹ lori ayelujara, bi awọn kan ṣe n sọ pe oun ti oju Mbaka n wa lo ri.

Amọ awọn mi n sọ pe itiju nla gba ni bi odidi ileeṣẹ Aarẹ ṣe le huwa ibanilorukọjẹ ti wọn hu si Fr Mbaka. nipasẹ atẹjade naa.

Amin iyasọtọ kan

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Mò ń ké tantan, tí Buhari kò bá fí ipò sílẹ̀, ìbò 2023 kò ní wáyé - Father Mbaka

Buhari ati Mbaka

Oríṣun àwòrán, MBuhari Twitter

Alufa ijọ Aguda mimọ, Rev Fr Ejire Mbaka ti tẹnumọ pe ki aarẹ Buhari fi ipo silẹ ni kiakia, ki iya to bẹrẹ si ni jẹ awọn to wa ni ipo ni Naijiria.

Mbaka sọ eyi lasiko to n ba awọn eniyan ijọ rẹ sọrọ ni ita gbangba ni ilu Enugu, ti o pe akọle rẹ ni ''ki lo fa ẹkun awọn ọmọ Naijiria?''

O ni awọn ọmọ Naijiria n sunkun nitori awọn adari yii ti kuna patapata lai ni ojutu mọ.

Nitori naa, o kesi aarẹ Buhari lati fi tọwọtọwọ fi ipo silẹ gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria.

Lori ọrọ wi pe o pẹlu awọn adari ẹsin to gbadura fun aarẹ Buhari lati wọle gẹgẹ bi aarẹ, Father Mbaka ni lootọ ni oun gbadura fun aarẹ Buari nitori woli ni oun.

Ụkọchukwu Ejike Mbaka

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adoration Ministry Enugu Nigeria

Mo gbadura fun aarẹ Buhari ko wọle gẹgẹ bi aarẹ, amọ Samuel naa gbadura fun Saulu

''Ohun ti mo ri lo jẹ ki n gbadura fun aarẹ Buhari nigba naa, amọ nkan ti yipada bayii''

''Ṣebi Samuẹli ninu Bibeli naa gbadura fun Saulu, to si fi ami ororo le ni ori, amọ ki lo gbẹyin ọba Saulu''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nitori naa mo ni igbagbọ ninu aarẹ Buhari nigba kan ri, lo jẹ kki n gbadura fun un nigba naa, amọ o ti bọ bayii.

Bakan naa ni mi o ni nọmba ẹrọ ilewọ aarẹ Buhari tabi boya ani ipade kankan ni igba kan ri, kii pe mi, mi o si ki n pe e.

Àkọlé fídíò, Olugbon of Igbon: ‘Rubber Stamp’ làwọn aṣòfin àpapọ̀, wọn kò ṣojú aráàlú

Ẹyin aṣofin, ẹ yọ Buhari ni ipo to ba kọ lati fi ipo silẹ

Father Mbaka fikun wi pe nkan buruku ni ki awọn agbebọn ma a pa awọn ọmọ Naijiria ni ojoojumọ, ki aarẹ Buhari si dakẹ lai sọ ohunkohun.

''Ko si akọnimọọgba agbabọọlu kankan ti yoo ma a wo awọn agbabọọlu rẹ niran ki wọn ma a kuna, lai wa nkan ṣe si''

''Nitori naa ni mo n ke tantan pe ki awọn ile aṣofin mejeeji dibo lati yọ aarẹ Buhari ni ipo, ti ko ba fi ipo silẹ fun ara rẹ ni kiakia.

''Amọ, ti ẹyin aṣofin ba kọ lati yọ Buhari ni ipo, nkan buruku ni yoo bẹrẹ si ni ṣẹlẹ si awọn olori nipo.''

''Bẹẹ si ni owo ti ẹ n ko pamọ fun idibo ọdun 2023, ti ẹ ko tọju awọn araalu, oju yin a ja nitori idibo ọdun 2023 le ma waye.''

Fada Mbaka

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adoration ministries

Nitori asiko n bo ti wọn ba sọ wi pe ki e di ipo mu ni Naijiria, awọn miran a salọ patapata''

Ẹni ki awọn ọdọ ṣiṣẹ agbẹ, awọn Fulani darandaran n ba ere oko wọn jẹ, wọn si n pa wọn bi ẹran

Bakan naa ni Father Mbaka sọrọ lori ọrọ ajẹ to dẹnukọlẹ ati ai si iṣẹ fun awọn ọdọ ni Naijiria.

Father Mbaka ni awọn adari n lo owo to yẹ fun awọn araalu lati fi tọju ara wọn, ti iya ati iṣẹ si n ba awọn eniyan finra.

''Ibinu Ọlọrun n bọ fun gbogbo awọn adari ni Naijiria bẹrẹ lati ori aarẹ Buhari''

''Talo le sọ boya Ọlọrun fun ara rẹ lo ṣi ẹwọn ni Owerii, nitori iya aitọ ti wọn fi n jẹ awọn eniyan''

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

Ẹjẹ n ke ni ilẹ Yoruba nitori iṣekupani to n waye nibẹ

Father Mbaka fikun wi pe ko si ibi ti isinmi wa lorilẹede Naijiria nitori iṣekupani to n waye lojoojumọ.

Lati Ilẹ Yoruba, Ilẹ Ariwa ati Ilẹ Igbo ko si ibi ti itajẹsilẹ kosi

Nitori naa ki awọn adari wa si gbangba, ki wọn tọrọ idariji ẹṣẹ lọwọ awọn ọdọ, ki wọn si fun wọn ni iṣẹ.