Bola Tinubu: Inú n bí mi sí ìkọlù tó n wáyé ni Borno, Yobe àti ibòmíì

Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, @AsiwajuTinubu

Ọkan pataki lara awọn oloye ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu, ti sọ pe ibinu ati ìpayà ni awọn iṣẹlẹ ikọlu to n waye ni awọn ipinlẹ bi Borno, Yobe, Benue, Niger, Imo, ati awọn ipinlẹ míì ni Naijiria jẹ.

Tiinubu ni àwọn ikọlu naa ti mu ki ọpọ eeyan má fi oju tẹmbẹlu àwọn oṣiṣẹ eleto aabo ni Naijiria, eyi ti ko yẹ ko ribẹ.

Gẹgẹ bi ọrọ ti Tinubu kọ si ori ayelujara Twitter rẹ, o ni akọni ni awọn oṣiṣẹ alaabo ni Naijiria, to n fi ẹ̀mí wọn sinu ewu lati "daabo bo wa".

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sugbọn ṣa, o wa gba awọn ọmọ Naijiria ni imọran pe ki wọn o ma ṣe da ẹnikẹni ni ẹbi, bikose pe ki wọn o wa ni isọkan lati le ṣẹgun ọta.

Ọrọ ti Tinubu kọ soju opo Twitter rẹ

Oríṣun àwòrán, @AsiwajuTinubu

O ni "bo ṣe ri lara ọpọ ọmọ Naijiria to mọ́, inu n bi mi, bẹ ẹ ni ipaya mu mi lori awọn iwa ika ti wọn n hu si awọn eeyan ni ipinlẹ Borno, Yobe, Benue, Niger, Imo ati awọn mii...

"Ijọba gbọdọ tẹsiwaju lati ma a ṣe iwuri fun awọn oṣiṣẹ alaabo, lati ṣa gbogbo ipá wọn ki wọn o le bori idunkooko yii."

O ni gẹgẹ bi eniyan Naijiria, "a ko gbọdọ bẹru, wọn o di pipa run. Níkẹyìn, ipamọra, idajọ ati ikaanu ni yoo pada borí."

Amin iyasọtọ kan

Ko si orilẹede ti kii la inira kọja - Tinubu

Bola Tinubu: Kò sí òóta kan níbẹ̀ pé ìjà wà láàárín èmì àti ààrẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Omoboriowo

Adarí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Progress Asiwaju Ahmed Bola Tinubu ti fèsì lórí kùdìẹ̀kudìẹ tó n bá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fínra, ó ní ko sí orílẹ̀-èdè tí kìí la àsìkò tó nira báyìí kọjá.

Ó ní ìyàtọ̀ tó wà níbẹ̀ ni bi olórí bá ṣe bá ará ìlú sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìpeníja náà àti ọ̀nà láti la gbogbo àsìkò náà kọjá ní ìrọ̀rùn.

Tinubu sọ èyí ní kété tó pari ìpàdé ìdákọ́nkọ́ pẹ̀lú ààrẹ Muhammadu Buhari nile ìjọba nìlú Abuja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Asiwaju Bola Ahmed Tinubu àti alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC nígbà kan ri, olóyè Bisi Akande, ni wọ́n jọ kọ́wọ̀rìn lọ si ìbi ìpàdé náà.

Abẹwo naa si wa gẹ́gẹ́ bi ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ láti fikùnlùkùn lórí ìṣòrò tó n kojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Awọn gende agbebọn

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Bola Tinubu tẹsiwaju pe nǹkan tí ó tọ̀nà jùlọ ni ǹkan tí àwọn ń ṣe lọ́wọ́.

"Fífọwọ́sowọ́pọ̀ láti mú àdínkù bá ìjínígbé àti láti jùmọ wà ni ìsọ̀kan lati mú Nàìjíria tuntun wá fún àrá ìlú. "Wíwà ní àlàáfíà ará ìlú ló ṣe pàtàkì jùlọ.

Lóòtọ́ ni kò sí orílẹ̀-èdè tí kò tíì tí la ìpò yìí kọja, sùgbọ́n bi a bá ṣe bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní yóò sọ bí nǹkan yóò ṣe rí.

A wòó pé ọ̀nà wo ni a lè gbegbà tí yóò fi rọ̀rùn fún àwọn ènìyàn láti gbà á, èyí ni àwọn ìfọ̀rọ̀jomitoro ọ̀rọ̀ tí a ti ṣe pèlú adarí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà."

Àkọlé fídíò, Ogbomoso: Ẹbọ ọkùnrin àti obìnrin tí kò ní ìbálòpọ̀ rí ni wọ́n rú dènà ogun Fulani

Tinubi ni kò sí ààrẹ orílẹ̀-èdè tí yóò fẹ́ kí orílẹ̀-èdè tú mọ́ òun lórí tàbí kí wàhàlà máa ṣẹ̀lẹ̀ níbẹ̀.

Ó ní ó ṣe pàtàkì kí ará ìlú fọ́wọ́sowọ́pọ̀ ni òye, ati láti pinnu pé àwọn yóò borí ìpèníjà yìí.

"Kò sí olórí orílèdè tàbí ààrẹ tí yóò fẹ́ kí ọ̀rọ̀ élẹ́yàmẹ̀yà, ẹ̀sìn àti àwọn nǹkan mííràn ba ilú jẹ́ mọ́ òun lórí, ó wá pè fún amójúto àti agbéyẹ̀wò gidi àti ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀kan.

Bákan náà ni Tinubu bẹ̀nu àtẹ́ lu ọ̀rọ̀ tó n lọ ní àwọn ìhà ibì kan pé bí òun kìí ṣe ṣe wọle-wọde pẹ̀lú ààrẹ Muhammadu Buhari túmọ̀ sí pé ààrín àwọn kò gún.

Ó ní "Kò sí nǹkan tó n jẹ́ pé ààrín àwọn kò gún, tà ni dókìtà wa? se orí ayélujara ní àwọn ènìyàn yóò fi máa wo bi ǹkan ṣe rí láàrín àwọn ènìyàn méjì''

Àkọlé fídíò, Olugbon of Igbon: ‘Rubber Stamp’ làwọn aṣòfin àpapọ̀, wọn kò ṣojú aráàlú

"Mí ò nílò láti máa dàá láàmú ni gbangba ita ni gbogbo ìgbà; àbí ṣe ó yẹ ni? Rárá, onírúurú ọ̀nà ni à n gbà wo nǹkan, nítorí náà kò sí nǹkan tó jọ

bẹ́ẹ̀.

Tinubu tún fi idi ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé, ààrẹ Muhammadu Buhari kò ni lo wákàti kan kọja àsìkò rẹ nígbà ti sáà rẹ̀ bá tan, kò le tàpá sí òfin Nàìjíríà.

Amin iyasọtọ kan

Aráàlú, ṣé ẹ fẹ́ kí oko ọ̀gbìn oúnjẹ yin di ojú ogun ni àbi kó mú irè oko jáde?

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Twitter/APC

Asaaju gboogi ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni Naijiria, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti ni awọn esu beleke bii eeyan lo wa lẹyin idarudapọ to n ṣẹlẹ lorilẹede Naijiria.

Tinubu ni awọn to fẹ ba ọjọ ọla Naijiria jẹ lasiko to ku diẹ ki aṣeyori de ni wọn da rogbodiyan silẹ, ti wọ n da alaafia orilẹede yii ru.

O sọ ni ibi ayẹyẹ aṣekagba ikẹkọjade ni Fasiti fun eto ọgbin, Federal University of Agriculture, Makurdi, ni ipinlẹ Benue.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Tinubu to gba ami ẹyẹ Honorary doctorate nibẹ ni, iṣẹ agbẹ ni ọna abayo si iṣoro iya ati iṣẹ to n koju awọn ọmọ Naijiria.

''Asiko itusilẹ lo yẹ ki igba yii jẹ fun awọn araalu tori asia orilẹede to ni ''alaafia ati iṣọkan'' ni opomulero orilẹede Naijiria.

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Asiwaju Bola Tinubu

Amọ awọn eniyan ibi ti wọn n ṣekọlu si awọn agbẹ lo n fi ebi pa awọn eniyan ni Naijiria.

Nitori ti ko ba si ounjẹ ni orilẹede, awọn eniyan a jẹun ọta wọn nitori awọn eniyan ti ko si owo ni ọwọ wọn, ko ni le jẹun to tọ.''

Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ni awọn ọmọ Naijiria gbọdọ pinnu boya wọn fẹ ki oko ti wọn n gbin ounjẹ si jẹ ibudo ogun, tabi ko pada si ibi ti wọn ti n fun awọn eniyan ni ounjẹ.

Àkọlé fídíò, Hisham Wadan: Ìlanilọ́yẹ̀ nípa àrùn ojú ló mú mi ṣe fíìmù Lost in London

Tinubu ni lasiko ọwọn gogo ounjẹ yii, ijọba nilo ati pese ọna igbalode ti wọn yoo ma a lo lati fi ṣe eto ọgbin ati ipese ounjẹ fun awọn eniyan.

Bakan naa ni Tinubu rọ ijọba lati pese iranwọ ati ẹyawo fun awọn agbẹ lati le e ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ, ki iṣoro ọwọn gogo ounjẹ le dopin ni Naijiria.