Recruitment of 50m Army: Tinubu ní 50,000 ní òun fẹ́ pè jáde dípò 50m tóun pè

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gomina ana nipinlẹ Eko, tii tun se asaaju fẹgbẹ oselu APC, Bola Ahmed Tinubu ti kede pe asiwi ati asisọ gbaa ni ọrọ toun sọ lori gbigba aadọta miliọnu ọdọ sisẹ ologun.

Bẹẹ ba gbagbe, lasiko to n gbe idanilẹkọ ọlọdọọdun rẹ kalẹ, ikejila rẹ, ti wọn fi sọri ọjọ ibi kọkandinlaadọrin rẹ, ni Tinubu kede pe ki ijsba apapọ gba aadọta miliọnu ọdọ sisẹ ologun.

O ni ọna yii nikan lọna abayọ si ọpọ ipenija ati isoro to n da ẹka eto aabo Naijiria laamu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ atẹjade kan ti akọwe iroyin fun Bola Tinubu, Tunde Rahman fisita ni awọn ọmọ Naijiria si Tinubu gbọ ni.

Àkọlé fídíò, Blighted Ovum: Obìnrin kan sọ ohun tójú rẹ̀ rí nígbà tí oyún bàjẹ́ lára rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta

O ni asiwi lasan ni Tinubu se pẹlu bo se, nitori ẹgbẹrun lọna aadọta ọdọ pere lo n dagba pe ki ijọba gba si isẹ ologun, kii se aadọta miliọnu to pe jade.

Amọ sa, atẹjade naa fikun pe Tinubu si daba pe ki ijọba gba awọn ọdọ bii miliọnu marun sisẹ labẹ eto ikọ alajumọse fun ipese aabo, ti yoo maa doju kọ awọn ipenija eto aabo

Amin iyasọtọ kan

"Akíkanjú bíi Sunday Igboho ni kí Buhari gbà síṣẹ́ ológun, kìí ṣe ajẹbọ́tà"

Awọn ọmọ gareeji

Oríṣun àwòrán, @Taofeek Ojo

Ọ̀pọ̀ ló tí n gbà ọ̀rọ̀ tí olóye Asíwájú Ahmed Bola Tinubu sọ lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ kọkàndílọ́gbọ̀n oṣù kẹta ọdún 2021, níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀, bí ẹni gba igbá ọtí.

Nibi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí náà tó wáye ni ìpińlẹ̀ Kano ni Tinubu ti sàlàyé pé ojúùtú sí ìsòrò Nàìjíríà sí ètò àbò tó mẹ́hẹ ni kí ìjọba àpapọ̀ tún gba àwọn ọdọ́ tó tó mílíọ̀nù lọ́nà àádọ́ta sẹ́nu iṣẹ́ ológun Nàìjíríà.

Èrò rẹ̀ yìí ni ọ̀pọ̀ ọmọ Nàíjíríà ń fèsì lé lórí, ìdí sì rèé tí BBC Yorùbá fi fọ̀rọ̀ wá àwọn èèyàn kan lẹ́nu wò láti mọ èrò wọn lórí rẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nínú àwọn tí BBC Yorùbá fọ̀rọ̀wálẹ́nu wò ló ní ọ̀rọ̀ tí Tinúbu sọ yiìí kìí ṣe ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòrò ààbò tó ń da Nàíjíríà láàmú, pàápàá jùlọ ni àsìkò tí ọ̀pọ̀ ń pe fún ọlọ́pàá abẹ́lé gẹ́gẹ́ bi ọ̀nà àbáyọ.

Awọn ologun Naijiria

Oríṣun àwòrán, @NigerianArmyHQ

Gbígba àádọ́ta mílíọ́nù ọ̀dọ́ síṣẹ́ kọ́ lọ̀nà àbáyọ sí ìṣòrò ààbò - Kunle Olajide

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Dókítà Kunle Olajide tó jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ àgbàagbà Yorùbá (YCE) sàlàyé pé, ọ̀rọ̀ Tinubu yìí kò le jẹ́ òpin si ìsòrò ààbò, ó ni ìwé àti ètò tí Nàìjíríà fí n ṣe ìjọba ni 1960-1963 ló yẹ kí Nàìjíríà padà sí.

Èyí sì ló làá sílẹ̀ pé kí ìjọba ìbílẹ̀ àti ìpínlẹ̀ ma ṣètò ìjọba tírẹ̀, kìí ṣe pé kí mílíọ̀nù lọ́nà àádọ́ta ológun mííràn tún wà lábẹ́ ìjọba àpapọ̀, àgbàra ìjọba apapọ̀ ti pọ̀ ju bí ó ṣe yẹ lọ lásìkò yìí.

" Ọlọ́pàá ìjọba ìbílẹ̀ ni yóò wà lábẹ́ ìjọba ìpińlẹ̀, kìí ṣe pé kí ìjọba àpapọ̀ tún má darí wọn"

Àkọlé fídíò, 'Èmi àti ìyàwó mi ti ń gbé pọ̀ nínú ìgbéyàwó wa fún 60 years', ẹ wá kọ́ ẹ̀kọ́ lẹ́nu àgbà méjì

Irú àwọn ọ̀dọ́ wo ní ìjọba yóò gbà síṣẹ́, ọmọ Ajẹbọ́tà ni àbí Ajẹ̀kúta?

Bákan náà ni Arakunrin Akin Adeyi, tó jẹ́ àgbà ọjẹ́ lórí ètò àbò ni ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ìmọ̀ràn tí ó dára sùgbọ́n kìí ṣe ǹkan to le so èsò rere.

Adeyi ní ọ̀nà wo ni ìjọba yóò gbé èyí gbà? "irú ọ̀dọ́ wò ni à ń sọ? Ṣé àwọn ajẹbátà ni àbí àwọn Ajẹ̀kúta"?

Arakúnrin Adeyi fí kun pé, ọ̀nà tí ìjọba fi ń gba àwọn ọmọogun gan sẹ́nu iṣẹ́ kò tọ̀nà tó, oní ọ̀pọ̀ àwọn tó n wọ iṣẹ́ ológun jẹ́ ọmọ olówó.

Ó ní kìí sí ṣe ìfẹ́ wọn ni bí kò ṣe pé àwọn òbí wọ́n ní ẹsẹ̀ níjọba tàbí nítorí pe wọn kò rí ọ̀nà àbáyọ mííràn.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Asa: Ìyàtọ̀ tó wà láàrin ìlànà ìpolówó ọjà láyé àtijọ́ àti òde òní

"Ọ̀pọ̀ ọmọ Ajẹbọ́tà ni kò tílẹ̀ le dá ẹgbẹ́ rẹ̀ fọ́ léti láti kékére, sùgbọ́n àwọn ló ni sabuke tí ìjọba ń bèèrè fún, àwọn ló tún ni ànfàni láti lọ si ilé ẹ̀kọ́ ológun "Defence Academy", nítorí bàbá wọ́n mọ ọ̀gá ológún.

"Awọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ jagunjagun gangan wà ní garaji, ṣe Sekau tó n fí imú Nàìjíría dánrin kàwé ni"? ìrú Sunday Igboho ìwé kí lo kà, sùgbọ́n ó tó ìjà gbè"

Adeyi ní láti ibi ìgbani ṣíṣẹ́ ni ìṣòro Nàìjíríà tí bẹ̀rẹ̀, tí ìjọba bá lé mójú tó èyí, tí wọ́n si kó àwọn tó ṣetan láti ṣe iṣẹ́ ológún síṣẹ́, ni ọ̀nà àbáyọ yóò tó wà.

Ọ̀rọ̀ Ọ̀ba Adetokunbo Tejuosho tí ìlú Kemta náà kò yàtọ̀ sí àwọn èyí àwọn tókù sọ, òní kìí ṣe èyí ló kàn nínú gbogbo ǹkan tó n ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ ni Nàìjíríà, nítorí pé abk ìjọba àpapọ̀ náà wọ́n yóò tún wà.

Àkọlé fídíò, 'Òde ìnáwó làwọn èèyàn ma ń rò bí wọ́n bá rí Ankara, ìgbà tí wọ́n rí i lára àga tí mo ṣe, ẹnu wọn ò padé mọ́'

O ní o ṣe pàtàki láti ló àwọn elétò ààbò tí abẹ́le, àwọn ará ìlú tó mọ ojú òpó ìlú tọ̀, nítorí tí wàhálà bá bẹ́ sílẹ̀ ní ìlú, àwọn ni yóò mọ̀ bí wọ́n yóò ṣe rí àwọn ọ̀daran mú.

Ẹ pe ìpàdé àwọn ọ̀dọ́ láti ṣàlàyé ìdí tí Nàíjíríà kò fi le pín - Ọba Tejuosho

Ọba Tejuosho ni lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ǹkàn tó n gbónà lọ́wọ́ ni Nàìjíríà ni tàwọn ọ̀dọ́ tó ń jìjàgbàra pé kí Nàìjíríà pín, ìgbẹ́sẹ̀ tó yẹ ni àsìkò yìí pé kí wọ́n pé àwọn ọ̀dọ́ yìí jọ láti sàlàyé bí ǹkan ṣe rí, àti ìdí tí wọn ko fi le pín ni àsìkò yìí.

"Gbogbo àbájade ètò Confab tó wáyé lásìkò ìjọba Jonathan lọ́dún 2014, àwọn àbájáde tí wọ́n ṣe lásìkò àpérò Confab náà, níbo ni wọ́n dàá sí?"

"Kí ni ìdí tí ìjọba kò fi ṣe àmúlò ǹkan ti àwọn lọ́balọ́ba àti ọ̀tọ̀kùlú ìlú lọ jíròrò lé lórí àti ọ̀pọ̀ owó tí wọn ná lásìkò náà, ṣe gbogbo rẹ̀ kàn ṣòfò ni?"

Àkọlé fídíò, Bed Wetting: Tolulope Joseph ní ò lé ní ogún ọdún tí òun fi tọ̀ sílé kí ìwòsàn tó dé

Ọba Tejuosho pẹ̀lú fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, àwọn tó wà ní ìgbéríkò kìí mọ bi ọ̀rọ̀ ìgbànisíṣẹ́ ṣe ń lọ, nítorí wọ́n kìí fi lọ àwọn lọ́bálọ́ba àti àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀.

"Èyí túmọ̀ sí pé àwọn tó lẹni lóke lọ n wọ iṣẹ́ òhún tó sì jẹ́ pé, nígbà míràn wọ́n ń ṣe nítori wọ́n bá ara wọ́n nibẹ̀ ni.