Ondo Cow Death: Ọba Akungba ní Fulani tó ni màálù tó kú níkan ló mọ omi tí wọn mu

Ondo

Alale ilu Akungba Akoko, Oba Isaac Adeyeye, Ajimo kẹta ti tẹnumọ pe, ko si ẹni to lee sọ pato ohun to ṣekupa awọn maluu to ku lojiji ni ilu Akungba.

Ọba Adeyeye lo sọ bẹẹ fun BBC Yoruba lasiko to n fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye.

Saaju ni ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti sọ fun BBC lọjọ Isẹgun pe iwadii ti fihan pe, omi kan to seese ko ni majele ninu ni awọn maalu to ku naa mu, amọ iwadii si n tẹsiwaju.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni nitori iṣẹlẹ naa ko ṣoju ẹnikẹni ayafi awọn darandaran to mọ ibi ti wọn rin si lati lọ da ẹran wọn, lo le e sọ iru omi ati koriko ti awọn ẹran maalu naa jẹ.

Òkú màálù

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àrá abàmì kan ṣe ikú pa màálù tó lé lógún

''Omi to dara lo wa ni Akungba ati agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, a si ti tun wo awọn omi naa, ẹja wa ninu rẹ to n ṣere, nitori naa, kii ṣe omi inu ilu ni wọn mu.''

Alalẹ ilu Akungba fikun pe ni kete ti oun gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ni oun paṣẹ fun ẹni to ni maluu naa pe ko ma titori owo ti yoo padanu, maa ta oku ẹran fun awọn eniyan o.

''Kiakia naa ni mo kan si ijọba ibilẹ ati ijọba ipinlẹ lati fi iṣẹlẹ naa to wọn leti''

Àkọlé fídíò, Onpetu Ijeru: Akala ní torí Aláàfin kò ṣúgbàá òun fún sáà kejì, ló ṣe ní kí pín ipò alága

''Awọn eleto ilera ijọba ibilẹ si ti wa sibẹ, wọn si ti lọ sin awọn maluu naa.''

''Ki wọn to lọ sin wọn, wọn kọkọ quarantine ibi ti iṣẹlẹ ti ṣẹlẹ, ti wọn si da 'chemical' si wọn lara, ki wọn to lọ sin wọn''

''Mo si tun kilọ fun awọn eniyan lati ṣọra fun ẹran maalu jijẹ lasiko yii nitori nkan to le pa malu ọgbọn lẹẹkan naa, le pa ọmọ eniyan.''

Oku awọn malu naa

Oríṣun àwòrán, @todays_echo

Àkọlé àwòrán, Igbo oro ni ori oke Ọwa ni ara ti san pa awọn malu naa

Alale ilu Akungba Akoko, Oba Isaac Adeyeye, Ajimo III ni ọlọpaa ṣi n ṣewadii iṣẹlẹ naa lọwọ, amọ awọn eniyan ṣi gbọdọ yẹra fun ẹran namọ lasiko yii.

Amin iyasọtọ kan

Ìbẹ̀rù títa òkú màálù bíi námọ̀ fún aráàlú gbòde l'Ondo

Ondo
Àkọlé àwòrán, Igba akọkọ kọ niyi ti maluu ti ko din ni ọgbọn maluu yoo ṣa dede ku lagbegbe Akungba ni ipinlẹ Ondo.

Ọba ilu Akungba Akoko, Oba Isaac Sunday Adeyeye, Ajimo III, ti fi ikilọ sita fun awọn eniyan ara agbegbe naa lati ṣọra fun ẹran maalu jijẹ lasiko yii ki wọn ma ba jẹ oku ẹran.

Eyi ko ṣẹyin iṣẹlẹ arameriri to ṣẹlẹ ni ijọba ibilẹ naa, nigba ti maluu to le ni ọgbọn fo sanlẹ ku ni agbegbe naa.

Ọba Adeyeye ni awọn ti kilọ fun awọn alapata lagbegbe naa lati maṣe ta awọn oku ẹran naa nitori ilera awọn eniyan.

Bakan naa ni o fikun pe, alapata kankan ti wọn ba gbamu to n ta oku ẹran yoo foju wina ofin.

ONDO

Oríṣun àwòrán, OTHERS

''O ṣeeṣe ki awọn ẹran to ku naa jẹ koriko to ni majẹle nigba ti wọn n ko wọn da kiri.''

''Nitori naa mo ti paṣẹ pe ki ẹnikẹni maṣe ta oku ẹran maalu naa nitori ko tilẹ tii si ẹni to mọ nkan to ṣekupa wọn''

''Awọn maalu naa sadede fo sanlẹ ku ni nitori o le e jẹ omi ti wọn mu ''

Ọba ilu Akungba naa fikun pe awọn ti kesi awọn eleto ilẹra ni ijọba ibilẹ naa lati wa ṣewadii iṣẹlẹ, ki wọn si gbe igbesẹ to yẹ.

Àkọlé fídíò, Blighted Ovum: Obìnrin kan sọ ohun tójú rẹ̀ rí nígbà tí oyún bàjẹ́ lára rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta

Ni aago mẹjọ, alẹ Ọjọ Aje ni wọn ni iṣẹlẹ naa ṣẹ lagbegbe Ibaka ni ilu naa.

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, irufẹ iṣẹlẹ yii naa ti waye ni ilu Ijarẹ ati ilu Ikarẹ Akoko ni ipinlẹ Ondo kan naa ni ọdun 2019.

Amin iyasọtọ kan

Kàyééfì ńlá! Kí ló tún pa ọgbọ̀n Màlúù lójijì l'Ondo?

Oku awọn malu naa

Oríṣun àwòrán, @todays_echo

Àkọlé àwòrán, Igbo oro ni ori oke Ọwa ni ara ti san pa awọn malu naa

Ariwo ki ree, emi lo tun ba eyi wa lo gba igboro kan niluu Akugba Akoko ni ipinlẹ Ondo lojumọ ọjọ Iṣẹgun nigba ti iroyin kan sigboro pe ko din ni ọgbọn maluu lo ti ṣa dede ku lagbegbe kan ni ilu naa.

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, ilu Akungba ni fasiti Adekunle Ajasin, AAUA fikalẹ si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni alẹ ọjọ Aje ni wọn ni iṣẹlẹ naa ṣẹ lagbegbe Ibaka ni ilu naa.

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, irufẹ iṣẹlẹ yii naa ti ṣẹlẹ ni ilu Ijarẹ ati ilu Ikarẹ Akoko ni ipinlẹ Ondo kan naa ni ọdun 2019.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Asa: Ìyàtọ̀ tó wà láàrin ìlànà ìpolówó ọjà láyé àtijọ́ àti òde òní

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ati pe iwadii ti n lọ lori rẹ.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, ASP TEE-LEO IKORO ṣalaye pe, gẹgẹ bi ohun to tẹ awọn lọwọ, awọn maluu naa ku lẹyin ti wọn mu ninu orisun omi kan naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo naa ni, ohun to ru awọn loju ti awọn n wadi lati ri idahun si bayii, ni lati mọ boya majele wa ninu omi naa ni tabi nnkan miran lo ṣe awọn maluu naa.