UFC 261: Kamaru Usman gba ife ẹ̀yẹ UFC Welterweight lẹ́yìn tó sán bàǹtẹ́ ìyà fún Jorge Masvidal

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajẹkun iya ni Jorge Masvidal jẹ lọwọ Kamaru Usman to jẹ ọmọ Naijiria lasiko ifẹṣẹkubiojo to waye ni aarin awọn mejeeji ni Florida.
Awọn mejeeji jijakadi lati figagbaga lori ẹni ti yio gba Ami Ẹyẹ UFC welterweight.
Ijakadi naa to waye ni Jacksonville ni Florida ni Kamaru ti ṣe bẹbẹ laarin awọn ololufẹ rẹ to le ni ẹgbẹrun lọna marundinlogun, 15,000 to wa wo iran.
- Chelsea, Arsenal, Liverpool, Tottenham Man City, Man United yọ ara wọn kúrò nínú ìdíje Super League tuntun
- Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ Mourinho, akọ́nimọ̀ọ́gbá Tottenham
- Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa líìgì bọ́ọ̀lù tuntun tí ó fẹ́ jáde ní Yúróòpù
- Wo ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú eré ìdárayá Squash fún àgbéga ìlera àti ọrọ̀ ajé rẹ
- Aráàlú gbá Rotimi Makinde lọ́rọ̀ torí ọ̀rọ̀ tó kọ nípa ẹ̀ṣùn tí wọn fi kan Baba Ijesa
- Ọwọ ọlọ́pàá tẹ afurasí méjì pẹlú orí òkú ní ibójì
- Ikọlù agbébọn tó jó ilé Gómìnà ìpínlẹ̀ lọ́wọ́ òṣèlú nínú-Ìjọba Imo
Ijakadi naa waye lati fi idi rẹ mulẹ ẹni gan an to kujuwọn lati gba UFC welterweight laarin awọn mejeeji.
Ni saa akọkọ idije naa, round one, awọn mejeeji lo ṣe daradara ti wọn si sa ipa wọn lati fi agba han ẹnikẹji.
Amọ ni saa keji idije naa, round two, Kamaru to ti rẹkẹ Masvidal fi akọ han to si lu u ni alubami.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eleyii ti mu ki Usman lamilaaka ju ti tẹlẹ lọ, ti o si ti di igba mọkandinlogun si ẹyọkan, 19-1 ti o ti fakọyọ ninu idije ifẹṣẹkubiojo.
Ninu ọrọ rẹ, Kamaru ni ohun ti sọ fun awọn eniyan pe oun ṣẹṣẹ mu ẹyẹ bọ lapo ni, nitori naa ki ẹ farabalẹ ma a wo iran oun.
Bakan naa ni Kamaru ni o da oun loju wi pe laipẹ gbogbo eniyan ni yoo ri wi pe oun lo darajulọ gẹgẹ bi afẹsẹkubiojo ni agbaye.

















