European Super League: Chelsea, Arsenal, Liverpool, Tottenham Man City, Man United yọ ara wọn kúrò nínú ìdíje Super League tuntun

Football

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu mẹfa to n kopa ninu idije Premier League ti yọ ara wọn kuro ninu idije tuntun, European Super League ti wọn ṣẹṣẹ gbe kalẹ.Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa líìgì bọ́ọ̀lù tuntun tí ó fẹ́ jáde ní Yúróòpù

Manchester City to jẹ ẹgbẹ agbabọọlu akọkọ lati yọ ara rẹ kuro ninu idije naa, lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ni awọn n gbiyanju lati bẹrẹ eto ti yoo mu wọn kuro ninu idije tuntun naa.

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu to ku bii Arsenal, Liverpool, Manchester United ati Tottenham ti gbe igbesẹ lati kuro ninu ẹgbẹ naa.

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ni awọn ti yọ ara awọn kuro ninu ikọ tuntun naa, pe awọn o ṣe ẹgbẹ Super League mọ.

Bakan naa ni Liverpool kede pe awọn ko faramọ igbiyanju idije tuntun Super League to fẹ kuro ni ara European League, nitori naa, awọn o ṣe mọ.

Lẹyin naa ni ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United kede pe awọn ti gbọ ariwisi awọn ololufẹ wọn, ijọba Ilẹ Gẹẹsi ati awọn opomulero inu ẹgbẹ agbabọọlu naa, ti wọn tako liigi tuntun naa, nitori naa, awọn ti yọ ara wọn kuro.

Ẹbẹ ni ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal fi ranṣẹ si awọn ololufẹ wọn ninu lẹta ti wọn kọ ni gbangba si awọn ololufẹ wọn, pe awọn ti gbọ igbe wọn, awọn si ti ṣetan lati jawọ ninu aṣemaṣe ti wọn ṣe pẹlu ẹgbẹ tuntun ti wọn darapọ mọ.

Àkọlé fídíò, Budo Ikoko water problem: Ìyàwó wa ti sá lọ kúrò ní Asa nítorí àìsí omi- Alhaji Sunmonu

Alaga ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham, Daniel Levy ni ki awọn eniyan wọn ma binu si igbesẹ ti wọn gbe.

Bakan naa ni Chelsea kede pe awọn ti bẹrẹ si ni yọ ara wọn kuro, amọ o ṣeni laanu wi pe opin ọsẹ to kọja ni awọn ṣẹṣẹ darapọ mọ Idije Super League ọhun.

Eyi ti wa mu ki Ajọ Idije Super League naa ni awọn yoo tun ero wọn pa lori bi idije tuntun naa yoo ṣe bu iyi kun ere bọọlu.

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

Ọjọ Isinmi ọsẹ to kọja ni wọn kede Idije Super League onigun mejila ti wọn ṣẹṣẹ gbe kalẹ, amọ awọn eniyan bu ẹnu atẹ lu u.

Ninu ọrọ tirẹ, Aarẹ Ajọ Agbabọọlu Ilẹ Yuroopu, UEFA, Aleksander Ceferin ni inu awọn dun si bi awọn ẹgbẹ agbabọọlu mẹfa yii ṣe yọ ara wọn kuro ninu ajọ idije tuntun, Super League naa.

Àkọlé fídíò, hhhhhh

Ceferin ni awọn yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ẹgbẹ agbabọọlu lati ri pe UEFA dara ju ti tẹlẹ lọ, ki ifimọsọkan si jọba ni aarin wọn.

Amọ, awọn ikọ ẹgbẹ agbabọọlu to ku bii Atletico Madrid, Barcelona ati Real Madrid lati Ilẹ Spain ati AC Milan, Inter Milan ati Juventus lati ilẹ Italy ko i tii sọ boya awọn naa yoo kuro ninu Super League ọhun.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Ẹ̀yà Ara Ifọ̀ ní olùkọ́ Adedokun kọ́ wa