Anthony Joshua vs Pulev: Anthony Joshua rọ̀jò ẹ̀ṣẹ́ lu Pulev

Oríṣun àwòrán, Reuters
Nnkan yan lalẹ ọjọ Satide, ọjọ kejila oṣu kejila ọdun 2020 nigba ti awọn akanṣẹjẹun meji, Anthony Joshua ti ilẹ Gẹẹsi ati Kubrat Pulev ọmọ Bulgaria.
- Kí ni abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò Anthony Joshua fi n wu àwọn ọmọ Naijiria tí gbogbo wọn fẹ́ tan mọ́ ọ?
- Báyìí ni àgbàọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ̀lù Diego Maradona ṣe wọ káà ilẹ̀ lọ lólú ìlú Argentina
- Ohun mẹ́wàá pàtàkì nípa Maradona àti ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ẹlẹ́sẹ̀ ayò Diego Costa rèé
- Àwòrán rèé nípa bí 'Hand of God' ṣé dí inagijẹ Diego Maradona
Lẹyin o rẹyin Anthony Joshua lo bori nigba to fi ẹṣẹ ja Pulev bs bi apo irẹsi nigba ti ija wọn wọ ipele kẹsan.

Oríṣun àwòrán, EPA
Pẹlu abajade ija ẹṣẹ kikan naa, Anthony Joshua ṣi ni agba ọjọ akanṣẹ to di bẹliti ẹyẹ WBO, WBA ati IBF mu bayii.

Oríṣun àwòrán, PA Media
Ija naa ti wọn ja lati aṣalẹ ọjọ Satide wọ kuutkutu owurọ ọjọ Aiku ni igba kejilelogun ti Joshua yoo fi ẹṣẹ ja akanṣẹjẹun miran bọ ni apo irẹsi, iyẹn Knockout lati igba to ti bẹrẹ si ni kan ẹṣẹ jẹun, eyi si ni igba keji ti Pulev yoo kuna lati igba to ti n ja ẹṣẹ jẹun.

Oríṣun àwòrán, Reuters








