Diego Maradona: Ohun mẹ́wàá pàtàkì nípa Maradona àti ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ẹlẹ́sẹ̀ ayò Diego Costa rèé

Maradona

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Erin wo, ajanaku sun bi oke! Gbogbo agbaye papaa julọ awọn ogbontarigi agbabọọlu atawọn ololufẹ ere bọọlu lo n ṣe idaro Diego Amando Maradona to jade laye l'Ọjọru lẹni ọgọta ọdun.

Ilumọọka elege ara ni agbabọọlu ọmọbibi orilẹede Argentina, Maradona jẹ, koda awọn eeyan kan gbagbọ pe oun ni agbabọọlu to dantọ julọ ninu iwe itan.

Maradona wa lati idile ti wọn ko ṣaaba rọwọ fi họri, o si goke agba di agbaọjẹ agbabọọlu kaakiri agbaaye.

Maradona gba ami ẹyẹ pẹlu oriṣiiriṣii ẹgbẹ agbabọọlu lorilẹede Argentina, Italy ati Spain.

Eyi ti ọpọ eeyan ko le gbagbe laelae ni idije ife ẹyẹ agbaye eyi ti Maradona gba pẹlu orilẹede rẹ lọdun 1986.

Lara awọn abawọn ti awọn eeyan ṣaaba maa n tọka si ni mimu oogun oloro ati ọti lile nigba to n gbabọọlu.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Ohun mẹwaa pataki to yẹ ki o mọ ree nipa Diego Maradona

1. Maradona gbarada nigba to gba ami ẹyẹ liigi ọjẹwẹwẹ Argentina pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Boca Juniors lọdun 1982.

2. Lọdun 1984, Maradona fi ikọ agbabọọlu Boca Juniors silẹ lọ si Napoli lorilẹede Italy.

Oun lo ṣagbatẹru bi Napoli ṣe gba ami ẹyẹ Serie A ti wọn gba lọdun 1987 ati 1990, ami ẹyẹ Serie A meji pere ti wọn gba ninu itan wọn.

Diego Maradona

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Diego Maradona gba ife ẹyẹ agbaye ọdun 1986

3. Maradona nikan ni balogun ẹgbẹ agbabọọlu to ṣoju orilẹede rẹ fun akoko to pọ julọ.

Igba mẹrindinlogun ọtọtọ ni Maradona ṣoju Argentina ninu idije ife ẹyẹ agbaye.

4. Ọmọ ọdun mẹẹdogun ni Maradona wa nigba to bẹrẹ si ni maa gbabọọlu lẹyin to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Boca Juniors logunjọ oṣu kẹwaa ọdun 1979.

5. Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keji ọdun 1977 ni Maradona bẹrẹ si ni ṣoju orilẹede Argentina.

Diego Maradona

Oríṣun àwòrán, Rex Features

Àkọlé àwòrán, Maradona lagbabọọlu ti o pegede julọ nidije agbaye ọdun 1986

Ọmọ ọdun mẹrindinlogun lo wa nigba naa, orilẹede Hungary ni Argentina koju lọjọ naa.

6. Ẹgbẹ agbabọọlu Argentinos Juniors ti fi orukọ Maradona sọ papa iṣere wọn, Estadio Diego Armando Maradona ni papa isẹre naa n jẹ bayii.

7. Lọdun 1996, Maradona sọ pe ''mo ti loogun oloro, mo si n loogun oloro, mo si maa loogun lọ laelae.''

8. Lọdun 2000, ajọ to n ṣagbatẹru ere bọọlu lagbaaye, FIFA fi ẹbun agbabọọlu to dantọ julọ ninu iwe itan fun Maradona ati Pele orilẹede Brazil.

9. Maradona sọ fun ra rẹ pe Dalma ati Giannina ni ojulowo ọmọ oun nigba ti awọn yoku jẹ aṣiṣe atipe tori owo oun loun fi bi awọn ọmọ yoku.

10. Wọn sọ ẹlẹsẹ ayo Diego Costa to jẹ ọmọbibi orilẹede Brazil to n ṣoju Spain lorukọ Maradona.

Àkọlé fídíò, Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá: Kọ̀ síi nípa iṣẹ́ tí oúnjẹ ń ṣe lára níbí