Senator Ishaku Abbo: ìdí rèé tí mò fi fi kọ̀wé fi PDP sílẹ̀ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC

Aworan Seneto Abbo

Oríṣun àwòrán, senatorishakuabbo

Sẹnẹtọ Elisha Abbo, ti wọn fi ẹsun kan pe o lu obinrin kan nile itaja eroja ibalopo nilu Abuja ti fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ.

Sẹnẹtọ naa to n soju ẹkun idibo Ariwa ipinlẹ Adamawa sọ pe oun darapọ mọ APC nitori gomina ipinlẹ naa Umaru Fintiri to n dari ẹgbẹ radarada.

Lowurọ ọjọru lo fi ọrọ yi lede ninu iwe to ka seti igbọ awọn ọmọ ile aṣofin agba nilu Abuja.

Kete to kede ọrọ yi lawọn ọmọ ẹgbẹ APC to wa nile figbe bọ nu lati baa yọ pe o darapọ mọ awọn.

Yatọ si ọrọ Gomina to ni ko dari ẹgbẹ bo ti ṣe yẹ, Abbo ni Aarẹ Buhari jẹ iwuri foun nipa pe o kara mọ arisiki awọn ara ilu ju gbogbo awọn aarẹ ti tẹlẹ lọ.

''Loni mo darapọ mọ ẹgbẹ APC ati aarẹ Muhammadu Buhari lati jijọ pawọpọ gbe Naijiria ga''

Ninu alaye to ṣe ninu iwe to ka sita, Abbo tun sọ pe lati igba ti Naijiria ti pada si ijọba awarawa lọdun 1999, ko ti si aarẹ to mu ọrọ arailu lọkunkundun bi ti Buhari.

Iwa fifi ẹgbẹ kan silẹ lati lọ darapọ mọ ẹgbẹ mii jẹ eleyi tawọn oloṣelu Naijiria fẹran lati maa ṣe.

Aworan Sẹnẹtọ Abbo ati Minisita Lai Mohammed

Oríṣun àwòrán, senatorishakuabbo

Yatọ si awọn aṣofin awọn tara ilu dibo yan gẹgẹ bi Gomina naa a maa hu iru iwa yi.

Laipẹ yi ni Gomina ipinlẹ Ebonyi, David Umahi da họwuhọwu silẹ pẹlu bo ti ṣe fi ẹgbẹ PDP silẹ lati lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC to wa lori oye.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́