Nigeria Politics: Àwọn gómìnà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ PDP tó darapọ̀ mọ́ APC rèé

Gov

Oríṣun àwòrán, Twitter/@wynny49

Ninu eto oṣelu kaakiri agbaye ni awọn oloṣelu ti maa n fi ẹgbẹ oṣelu kan silẹ lọ omiran, oriṣiriṣi idi si ni wọn fi maa n ṣe bẹẹ.

Awọn idi naa le jẹ nitori afujusun irufẹ oloṣelu bẹẹ tabi ede aiyede ninu ẹgbẹ.

Ni Naijiria, oloṣelu miran yoo ti gori alefa labẹ asia ẹgbẹ kan tan ko to fi ẹgbẹ naa silẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ alatako.

Iwọnyii ni awọn gomina marun un ni Naijiria to ti fi ẹgbẹ moṣelu PDP silẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ APC lati igba ti ijọba ti pada sọwọ alagbada ni Naijiria.

Rochas Okorocha - Imo

Rochas Okorocha jẹ ọkan gboogi lara awọn gomina ẹgbẹ PDP to darapọ mọ APC.

Oṣu karun un ọdun 2013 ni Okorocha fopin si ibaṣepọ to wa laarin rẹ ati ẹgbẹ PDP ni ilu Oweri.

Àkọlé fídíò, Bí o bá bá ààrùn ìpẹ́pẹ́ gbígbẹ lára arẹwà obìnrin rẹ̀, kí loó ṣe?

Nibi ipade ita gbangba kan to waye ni Oweri lati ṣami si ọdun meji rẹ lori alefa ni Okorocha ti kede pe oun ti darapọ mọ ẹbi tuntun, to si rọ awọn ololufẹ rẹ lati tẹle oun lọ si ẹgbẹ tuntun naa.

Abdulfatah Ahmed - Kwara

Ọdun 2014 ni gomina ipinlẹ Kwara, Abdulfatah Ahmed, fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lọ darapọ mọ ẹgbẹ APC.

Lọdun naa lọhun, Ahmedssọ fun awọn akọroyin pe oun darapọ mọ ẹgbẹ tuntun fun anfani awọn eeyan ipinlẹ Kwara.

Ṣugbọn lẹyin ọdun mẹrin, iyẹn lọdun 2018, ni ọkunrin naa yi ohun pada, to si tun pada sinu ẹgbẹ PDP.

Rotimi Amaechi - Rivers

Rotimi Amaechi ni gomina ipinlẹ Rivers laarin ọdun 2007 si 2015.

Amaechi

Oríṣun àwòrán, @wynny49

Lọdun 2014 nigba to ṣi wa lori alefa gẹgẹ bii gomina ipinlẹ naa labẹ asia ẹgbẹ PDP ni o fi ẹgbẹ ọhun silẹ to si darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Lẹyin ti Muhammadu Buhari di Aarẹ Naijiria lọdun 2015 lo yan Amaechi gẹgẹ bii minisita to n ri si irinajo oju popo.

Dave Umahi

Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kọkanla ọdun 2020 ni Dave Umahi fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ to si darapọ mọ ẹgbẹ APC.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ikede naa, Umahi sọ pe oun fi ẹgbẹ APC nitori aiṣododo to wa ninu ẹgbẹ ọhun.

Umahi

Oríṣun àwòrán, @Southeast_trend

Awọn oloṣelu kan n sọ pe Umahi ni afojusun lati gbe apoti ipo Aarẹ lọjọ iwaju lo jẹ ko darapọ mọ APC, ṣugbọn gomina ọhun ti fesi.

O ni "mo fẹ sọ ni gbangba bayii pe, mi o darapọ mọ APC nitori pe mo fẹ di Aarẹ, irọ pata ni gbogbo awọn to n gbe iru iroyin bẹẹ kiri n pa."

Àkọlé fídíò, Eégun àti orò, bí wọ́n ṣe jọ bí Ẹ̀ṣà Egúngún nílẹ̀ Yorùba rèé