Ogun NYSC: Àjọ NYSC lé àgùnbánirọ̀ 96 padà nítorí oyún, àìlera míràn

Awọn agunbaniro

Oríṣun àwòrán, Peace ben williams blog/ nairaland

Ajọ agunbanirọ lorilẹede Naijiria ni ipinlẹ Ogun ti ṣalaye pe agunbanirọ mẹrindinlọgọrun ninu awọn agunbanirọ ti wọn fi ṣọwọ si ipinlẹ naa ni wọn le pada kuro nibi eto ifinimọle ti wọn maa n ṣe fawọn agunbanirọ ki wọn to bẹrẹ isinruulu wọn.

Àkọlé fídíò, Bí o bá bá ààrùn ìpẹ́pẹ́ gbígbẹ lára arẹwà obìnrin rẹ̀, kí loó ṣe?

Alakoso ajọ agunbanirọ NYSC ni ipinlẹ Ogun, Belinda Faniyi, ṣalaye ni ilu Sagamu, nibi eto ibura fawọn agunbanirọ ti wọn ṣẹṣẹ fẹ bẹrẹ isinruulu ni ipinlẹ Ogun wipe awọn agunbanirọ naa ni wọn da pada nitori pe wọn loyun, wọn n tọ ọmọ lọwọ atawọn ailera miran.

Àkọlé fídíò, Eégun àti orò, bí wọ́n ṣe jọ bí Ẹ̀ṣà Egúngún nílẹ̀ Yorùba rèé

O ni idi ti eyi fi waye nipe awọn iṣẹ alagbara ati ere idaraya gbogbo ti awọn agunbanirọ yoo maa ṣe lasiko eto ifinimọle naa yoo lewu fun awọn to loyun, awọn to n tọ ọmọ tabi ni ailera yoowu ni agọ ara wọn.

Labẹ eto ati ilana eto agunbanirọ lorilẹede Naijiria, o loju awọn eeyan to lee kopa ninu eto naa