ENDSARS: Mínísítà fún Iléesẹ́ Ọlọ́pàá sọ pé ìjọba yóò rí dájú pé irú rògbòdìyàn #ENDSARS kò wáyé mọ

Minisita fun ileesẹ ọlọpaa Naijiria, Muhammad Dingyadi sọ pe ijọba apapọ ti pinnu lati ri i daju pe rogbodiyan kankan bi eyi to waye lasiko iwọde #ENDSARS, ko waye mọ ni Naijiria.Ile ijọba nilu Abuja ni Dingyadi ti sọ ọrọ yii, gẹgẹ bi iwe iroyin abẹle, The Punch, ṣe jabọ iroyin, lẹyin ipade ti Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe pẹlu awọn ọmọ igbimọ eto abo gbogboogbo.
Dingyadi ni Aarẹ Buhari sọ pe gbogbo àwọn ti ti ọrọ kan, to fi mọ awọn ọdọ, ni ijọba yoo sisẹ pẹlu wọn, lati ri i pe iru iṣẹlẹ naa ko waye mọ, ati lati fi eto alaafia mulẹ ni Naijiria.Lori ibeere ti awọn akọroyin bi Minisita naa pe boya ki kọlu awọn to ba fẹ ẹ ṣe iwọde wá lara igbesẹ ti ijọba yoo gbe, Dingyadi ni "lori ọrọ #ENDSARS ti ẹ beere, nkan ti a n sọ ni pe ijọba yoo tẹsiwaju lati ma a jiroro, ati lati
ma a tẹti si nkan ti awọn ti ọrọ kan ba n sọ." Ko si tun ni ṣe ohunkohun lai sọ fun wọn, lati le dena iru rogbodiyan #ENDSARS to mu ki awọn kan ba dukia ijọba ati ti araalu jẹ."

Oríṣun àwòrán, Twitter/houseNGR
Sugbọn ṣa, awọn ọmọ ilẹ igbimọ asoju-sofin to wa lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP, ti kilọ fun ijọba apapọ lati sọra ṣe lori awọn ọrọ to ṣuyọ nipasẹ iwọde #ENDSARS.Bakan naa ni wọn rọ ọ lati bu ọwọ fun awọn ọdọ.Wọn ni ijọba gbọdọ tẹlẹ awọn ilana eto isejọba awaarawa, lati yanju ọrọ awọn ti ọlọpaa mú nitori ipa ti wọn ko ninu iwọde naa, lai tẹ ẹtọ wọn loju.Olori àwọn aṣofin naa, Kingsley Chinda, sọ ninu atẹjade kan pe awọn igbesẹ ti ijọba ti gbe lori ọrọ naa, fihan pe ijọba ko bọ̀wọ̀ fun araalu, tabi naani wọn.








