Abuja-Kaduna, Katsina Kidnap: Bí àwọn agbébọn ṣe jí ASP Ọlọ́pàá méjìlá gbé lójú ìbọn rèé

Oríṣun àwòrán, AFP
Lati ọjọ mẹwaa sẹyin ni awọn igbakeji supiritẹ́ndẹ́ẹ̀tì mejila ti ko sọwọ awọn agbebọn ni ilu kan laarin ipinlẹ Katsina si ipinlẹ Zamfara ṣugbọn nibayii, iroyin ijinigbe wọn ti gbode kan tori ohun ti awọn iyawo wọn sọ.
Ẹbi awọn ọlọpaa naa sọ fun BBC pe, ṣe ni wọn n lọ si ipinlẹ Borno lati lọ ṣe akanṣe iṣẹ kan ni ipinlẹ Zamfara nigba ti awọn agbebọn da wọn lọna ti wọn si ji wọn gbe.
Iyawo ọkan lara wọn sọ fun ileeṣẹ BBC pe oun ko tii gbọ latọdọ ọkọ oun fun odidi ọjọ mẹta afi igba ti oun lọ si bareke awọn ọlọpaa nibi to ti gbọ pe wọn ji ọkọ oun gbe.
O fi kun un pe oun pada gba ipe latọdọ ọkọ oun ṣugbọn ranpẹ lo jẹ, to n ṣalaye nkan ti wọn n foju ri lọwọ awọn ajinigbe ọhun.
"O pe mi lori ago lọjọru, o si sọ fun mi pe oun wa lọwọ awọn ajinigbe, ti ọkan lara awọn ajinigbe naa si sọ fun mi pe ki n lọ maa wa miliọnu kan naira owo itanran."
O ni oun ko tii gbọ ohùn ọkọ oun lati ọjọ naa ṣugbọn awọn ọlọpaa ti pe oun lati maa wo itanran ọhun.
Obinri naa ṣalaya pe "eeyan kọọkan wa ni a fẹ da 800,000 naira lati gba awọn eeyan wa ti wọn jigbe silẹ, a ko lee sun bayii , adura ni a si n gba ki a le ri wọn layọ ati alaafia."
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni ọkan lara awọn obinrin ti wọn ji ọkọ rẹ gbe fi ọmọ marun un silẹ fun oun ti oun n tọju lati igba iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Nigba ti BBC kan si agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Zamfara ati Katsina ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ, wọn ni awọn ko gbọ ohun kankan nipa iṣẹlẹ ọhun.
Ṣugbọn sibẹ, awọn obinrin naa ko dakẹ ẹkun pe ki ijọba ba wọn wa ọkọ awọn ri.
Ẹbi awọn lọgalọga mejila lẹnu iṣẹ ọlọpaa ti wọn jigbe lojuna wọn lọ si ilu Zamfara, ipinlẹ Borno ti n damu bayii.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Àwọn agbébọn tí jí àwọn ọmọ fásitì Zaria mẹ́jọ ní òpópónà Abuja sí Kaduna - Gomina El- Rufai

Oríṣun àwòrán, Twitter/Gov Kad
Ijọba ipinlẹ Kaduna ti kede pa awọn agbegbọn ti ji awọn ọmọ ileewe giga fasiti Ahmadu Bello Fasiti ni opopona Abuja si Kaduna.
Kọmisọnna fun ọrọ abẹle, Samuel Aruwan lọ fi lede ninu atẹjade pe adari ileewe giga naa lo fi to ijọba leti.
O ni adari ileewe giga Ahmadu Bello University, Zaria, Prof. Kabir Bala, fi to ijọba leti wi pe awọn ọmọ ileewe awọn mẹjọ wa lara awọn eniyan ti wọn jigbe ni ọpopona naa.
Amọ, awọn kan sọ wi pe awọn akẹkọọ to le ni ọọdunrun to jẹ akẹkọọ imọ Ede Faranse n lọ si ipinlẹ Eko fun eto ẹkọ ni French Language Village ni iṣẹlẹ naa waye.
Wọn tun fi orukọ akẹkọọ mẹjọ naa sita ti awọn agbebọn jigbe naa.
Bakan naa ni kọmisọnna fi kun un wi pe awọn agbebọn ṣe ikọlu si agbegbe Albasi, ti wọn si pa eniyan mejila ni opin ọsẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nasir el-Rufai
Nibayii, awọn araalu agbegbe naa ti sa kuro ni ilu, ki awọn agbegbọn naa ma tun pada wa.
Kọmisọnna fun ọrọ abẹle, Samuel Aruwan ni awọn agbofinro ti bẹrẹ si ni wa awọn agbegbọn ọhun.
Amọ, awọn eniyan ti bu ẹnu atẹ lu ijọba ipinlẹ Kaduna nitori wọn ko fi eto aabo sipo ni awọn oju popo ati awọn agbegbe to wa ni igberiko ipinlẹ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El- Rufai ti fi ọrọ ikẹdun sọwọ si awọn ti wọn padanu eniyan ninu ikọlu agbebọn naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
El-Rufai wa parọwa si awọn eniyan lati fkanbalẹ nitori awọn ti bẹrẹ si ni sọ awọn agbebọn naa, ti awọn yoo si fi wọn jofin.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3

















