India Wedding: Ìyàwó kan ní India wọ sòkòtò fún ayẹyẹ ìgbéyàwó rẹ̀- Wo ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀

Sanjana Rishi ati Dhruv Mahajan lasiko igbeyawo

Oríṣun àwòrán, Sanjana Rishi

    • Author, Geeta Pandey
    • Role, BBC News, Delhi

Ọbinrin onisowo India ati Amẹrika kan, Sanjana Rishi ti salaye idi ti o fi wọ sokoto fun ayẹyẹ imana igbeyawo rẹ ni India.

Rishi ni idi ni pe iru imura sokoto igbalode yii ni oun fẹran julọ laye oun, nitori naa ni oun ṣe wo pe, o yẹ fun igbeyawo oun.

Imura rẹ yii lo ku ki gbogbo awọn alejo lasiko igbeyawo naa maa kọ Ha! Ha!! Ha!!! ewo leyi nibi igbeyawo ibilẹ?

Eyi si da awuyewuye to pọ silẹ lori ayelujara ti awọn eniyan si fọn foto naa ka sori ayelujara.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe olowo ṣe ohun gbogbo tan, wọ́n ni imura rẹ dara pupọ, o si ba igba mu.

Bẹẹ naa ni awọn miran ni laipe yii ni awọn iyawo oju ọna to ku yoo maa wo bi awokọse, wọn yoo si pa iṣẹẹṣẹ ati aṣa ibilẹ wọn ti.

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Asọ igbeyawo rẹ kii ṣe nkan ti eniyan le dede ṣe alabapade rẹ ni orilede India.

Ni orilede India aṣọ ti wọn n pe ni Sari tabi sikẹẹti gigun bulaosi àti sikafu ni wọn maa n wọ gẹgẹ bi aṣọ igbeyawo.

Awọ pupa ni asọ naa ti wọn yoo si fi leesi alawọ wura tabi ayinrin (Gold&Silver) gba leti.

Sanjana Rishi ati Dhruv Mahajan lasiko igbe=yawo

Oríṣun àwòrán, Sanjana Rishi

Ọkan ninu awọn alamojuto iwe iroyin igbeyawo ni ile India, Nupur Metha Puri salaye pe oun ko ti i ri iru imura bẹẹ ri lati igba ti oun ti n se iru iṣẹ naa,

O ni aṣọ India ati awọn ẹsọ ibilẹ India ti wọn gba lọwọ iya wọn tabi iya-iya/ Iya baba wọn ni wọn maa n lo.

Obinrin naa ẹni ọdun mọkandinlọgbọn to fẹ onisowo kan ni Delhi to jẹ ọmọ ọdunn mẹtalelọgbọn lo ṣegbeyawo ni ogunjọ oṣu kẹsan ọdun 2020 ni Delhi

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Ipinnu wọn ni lati ṣe igbeyawo igbalode ni ilẹ Amerika ninu osu kẹsan an, ọdun.

Nibẹ ni iyawo àti ọpọ awọn ọrẹ wọn n gbe ti wọn yoo si se ti ibilẹ ni india ninu oṣu kọkanla, sugbọn Coronavirus bẹ silẹ ti gbogbo nkan si daru.

Rishi ni iṣẹju ti oun ti pinnu lati ṣe igbeyawo naa ni oun ti mọ nkan ti oun yoo gbọ

Imura Sanjana Rishi lasiko igbeyawo

Oríṣun àwòrán, Sanjana Rishi

O ni: "Mo mọ pe oun yo wọ sokoto ati kootu igbalode, iru eyi ti mo wọ gan an ni pato"

Eya ti Italian Gianfranco Ferré vintage ti ọdun 1990.

O ya mi lẹnu gan an ni pe o si wa laye lasiko ti mo setan lati ṣe igbeyawo, ọrọ rẹ ree.

Àkọlé fídíò, Divorcee: Ó sàn kí wọ́n yàgò fúnra wọn ju ki wọ́n ṣe ara wọn léṣe- Fisayo

Ọkọ rẹ, ọgbẹni Mahajan ninu ọrọ rẹ, salaye pe oun ko tilẹ ro o pe iyawo oun yoo wa sibi igbeyawo pẹlu sokoto ati kootu.

" Titi ti mo fi ri, mi o tilẹ ro nkan ti yoo wọ, sugbọn eyi ko tilẹ ni itumọ nitori mo mọ pe gbogbo nkan to ba tilẹ wọ gbogbo rẹ lo ṣe rẹgi lara rẹ"

Sanjana Rishi lasiko iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, Sanjana Rishi

Bi ọpọ eniyan ṣe wa n bere oniruuru ibere, ni Rishi salaye pe oun ko ṣetan lati sọ ohunkohun ti awọn eniyan yoo maa sọ ka, sugbọn ti oun ba ṣe igbeyawo naa ni kọrọ ko si nkan ti yoo ṣẹlẹ.

O ni oun mọ pe kii ṣe gbogbo obinrin lo le wọ nkan to ba wu wọn lọjọ igbeyawo wọn ni India,

Ṣugbọn ni kete ti oun sọ ero oun lori Instagram, ọpọ awọn obinrin iran lo fohun pé nkan to sọ ti fun awọn nigboya lati dide si awọn iya ọkọ ti o maan la le awọn lọwọ.

Paapaa lori iru aṣọ ti awọn yoo wọ lọjọ igbeyawo awọn.

" Inu mi dun gidi lori ọrọ yii laarin kan, sugbọn to ya ọrọ naa damu mi diẹ. Mo n ro pe ṣe mi o ti da wahala silẹ fun aye ati ile awọn kan bayii?"