Aṣẹ Deji ti Akure nipé kí gbogbo ọjà wà ní títì ní Ọjọ́ Ajé fún ọdún Aheregbe

Arakunrin Rotimi Akeredolu ti kéde pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ti ọjà kankan pa láì gba àṣẹ lọ́wọ́ ìjọba

Gomina Akeredolu

Oríṣun àwòrán, @Akeredolu

Akeredolu to sọ ọrọ yi latẹnu kọmiṣọna rẹ fun eto iroyin, Bamidele Ademola-Olateju wipe ko si igba laaye fun ọba kankan lati ti ọja lorukọ ọdun yowu ti i baa jẹ.

Akeredolu wi pe igbesẹ yi ni ko ṣẹyin bi awọn kan ṣe sa pamọ s'abẹ ọdun Aheregbe to waye nilu Akure to jẹ olu ilu ipinlẹ naa lọjọ aje ọsẹ yi lati ji ẹru awọn ọlọja kan ko ti ko si boju mu to.

Gomina naa fikun pe ko si ọba to gbọdọ paṣẹ titi ọja lai gba aṣẹ latọdọ ijọba ati pe titi naa ko gbọdọ kọja ọja ọba ninu ilu bẹẹ ki ijọba ma baa fi imu awọn to ba wa nidi ọdun naa dan'rin.

Ọdun Aheregbe ti o maa n waye lọdọọdun nilu Akure lo maa n mu ki wọn ti gbogbo ọja ati ibutaja ni ilu naa fun ọjọ kan gbako.

Ẹwẹ, aheregbe ti ọdun yi lo mu ọpọ aruwo dani nibi aigbora eni ye se n waye laarin Deji ti ilu Akure ati Iralepo Isinkan nipa titi ọja Isikan lọjọ ọdun Aherehbe.

Aheregbe festival: Deji Akure kò leè pàṣe láti tí Ọjà Isinkan nítorí kìí ṣe ara Akure

Aworan

Oríṣun àwòrán, Google

Ọpọlọpọ ariyanjiyan lo ti ṣuyọ lori ọdun Aheregbe ti wọn ma n ṣe ni ilu Akure ni ipinlẹ Ondo.

Ninu atẹjade ti Deji ti ilu Akure, Oba Aladetoyinbo Aladelusi fi lede lo ti paṣẹ pe ki gbogbo ọja ni ilu Akure wa ni titi ni Ọjọ Aje, Ọjọ Kejilelogun, Oṣu Kẹjọ, ọdun 2022.

Ninu atẹjade naa ni ọba ti ni titi pa awọn ọja naa wa lara iṣẹṣẹ ilu naa, ti o si pọn dandan ki awọn eniyan tẹle aṣẹ naa.

''Ko gbọdọ si ọja kankan ti yoo ṣi ni ilu Akure''

Ninu atẹjade ti ọba fi lede naa lo ti ni ki ẹnikẹni ma pa atẹ ọja abi ki wọn ṣi ṣọọbu wọn lasiko ọdun naa.

Wọn ni ko ni si aaye fun ọja kankan lasiko ọdun naa nitori wọn gbọdọ tẹlẹ aṣẹ ọba ati iṣẹṣe.

Bakan naa ni wọn fikun un pe awọn to n ta oogun nikan ati ileewosan lo ni aṣẹ lati ṣi ile itaja wọn.

‘’A rọ gbogbo awọn ọlọja ati oni ṣọọbu lati tẹle aṣẹ naa.’’

Amọ wọn fikun un pe awọn eniyan lee rin lasiko naa, ti ọkọ si le ṣiṣẹ.

Laelae, Ọja Isinkan kii ṣe ara Akure, awọn ọlọja lee ṣi ṣọọbu wọn- Ọba Isinkan

Aworan

Oríṣun àwòrán, Google

Iralepo ti ilu Isinkan, Ọba Oluwagbemiga Ajimokun Olofin- Adimula ti ni ọja Isinkan ko si lara ibi ti aṣẹ Deji ti ilu Akure yoo ti rinlẹ lori ọdun Aheregbe.

Ninu atẹjade to fi lede lo ti kọkọ ki Deji Akure ku oriire to si salaye idi ti ọja Isinkan yoo fi ṣi ni ọjọ ọdun naa.

‘’Isinkan ati ilu Akure jọ pin ala ni agbegbe Imogun , ki a to de ile ijọsin Saint Thomas ni Isinkan.’’

‘’Bakan naa ni omi Owena pin Isinkan sọtọ kuro ni ara ilu Ondo nitori naa ko si ohun to kan ilu Isinkan pẹlu ọdun ti ilu Akure n ṣe pẹlu iṣẹṣẹ wọn.’’

Ko si ohun to jọ ọ, ọja Isinkan gbọdọ wa ni titi pa- Deji ti Akure

Lẹyin ti ọba Isinkan fi esi lede pe Isinkan kii ṣe ara Akure ni Deji kede pe dandan gbọgbọ ọja ni ilu Akure to fi mọ Isinkan ni yoo ṣi.

Ti wọn si kan an ni ipa pe ile itaja oogun ati ileewosan nikan ni o ni aṣẹ lati ṣi, ti wọn si rọ awọn eniyan lati tẹle aṣẹ naa pẹlu adura pe ‘’Akure a gbe wa o’’.