Ẹ má wá sí Aso Rock wá bámi, eni tí egbẹ́ APC bá ti gbé sílẹ̀ ni yóò wọlẹ́ – Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti fi lede pe ẹni ti ẹgbẹ oṣelu APC ba ti ṣe atilẹyin fun ni oun yoo satilẹyin fun ni ọdun 2023.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun aarẹ Buhari, Garba Shehu gbe jade lo ti sọ pe aarẹ Buhari ko ni satilẹyin fun ọmọ ẹgbẹ tẹlẹ kankan ati awọn oloṣelu to ni ẹjọ pẹlu ẹgbẹ APC ni ileẹjọ
Garba Shehu ni akinkanju ọmọogun ni aarẹ Buhari lọjọ gbogbo, paapaa fun ẹgbẹ oṣelu APC.
Nitori naa ẹni ti ẹgbẹ osẹlu ba ti fa silẹ ni oun yoo ṣe atilẹyin fun.
APC lo satilẹyin funmi ni ọdun 2015,2019 ti mo fi di aarẹ - Buhari
‘’Ikilọ yii wa fun awọn ti wọn n kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC lọ si ẹgbẹ oṣelu miran pẹlu ero wipe aarẹ yoo se atilẹyin fun wọn.’’
‘’Nitori naa ẹnikẹni to ba tako alakalẹ ẹgbẹ ko gbọ̀dọ sọ pe aarẹ Buhari mọ nipa iṣesi oun.’’
‘’Ẹgbẹ oṣelu APC lo satilẹyin fun mi ni ọdun 2015 ti mo fi wọle, ti wọn si tun sa gbogbo ipa wọn lati ri pe mo wọle fun saa keji’’
‘’Nitori naa ki ẹnikẹni ma wa bami fun atilẹyin yatọ si awọn ti ẹgbẹ oṣelu APC ti fa ni ọwọ si oke.’’
Amọ Aarẹ Buhari naa fikun un pe ki ẹnikẹni ma ro wi pe oun ni wọn n ba wi nipa atẹjade yii nitori ipinnu aarẹ ni lati sagbatẹru fun ẹgbẹ.
Bakan naa ni aarẹ ni oun ko ni dẹkun igbiyanju lati mu ẹgbẹ naa goke ati lati ri pe ifimọṣọkan wa lati oke de isalẹ ẹgbẹ naa.
Aarẹ tun kilọ fun awọn to n gbe ahẹsọ ọrọ ni Ile Ijọba ni Aso Rock lati tẹ ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ, ki wọn ma ba da wahalẹ silẹ ninu ẹgbẹ ati ni iṣejọba oun.












