Grace Oyin Adejobi: Bí mo bá tún ayé wá, ọkọ mi ni màá padà fẹ́
Gbajumọ ni mama Grace Owoola Oyin-Adejobi ti ọpọ eeyan mọ si Iya Osogbo nitori o wa lara awọn obinrin to bẹrẹ ere tiata nibẹrẹ pẹpẹ.
Iya Osogbo, ẹni to sẹsẹ se ọjọ ibi ọdun kejilelaadọrun laipẹ yii ba BBC Yoruba sọrọ lori awọn iriri rẹ nile aye, ajọsepọ pẹlu ọkọ rẹ ati ere tiata.
O fikun pe iyawo marun ni oun fẹ fun ọkọ oun lati mu ki agbo ere tiata rẹ se aseye, ti oun ko si kabamọ nipa igbesẹ naa.
- Olólùfẹ́ mi ṣèèsì fi ọkọ́ gbá mi sí gọ́tà, mo rò pé ọlọ́jọ́ dé ni - Iya Osogbo
- Bí mó bá fojú kan Baba Wande lórí ìtàgé, ṣe ní ẹ̀rù máa ń bà mí - Tafa Oloyede
- Ìtàn ìgbé ayé Isola Ogunsola, akọni mánigbàgbé òṣèré tíátà, olórin àti onílù
- Gbajúmọ̀ agbábọ́ọ̀lù ni ǹ bá jẹ́, ká ní ń ko ṣeré tíátà - Bàbá Wande
- Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Baba Sala ló kọ́ Sunny Ade nísẹ́?
- Fídíò mánigbàgbé nípa ìgbà ayé Bàbá Sala
- Ǹjẹ́ o mọ àwọn òṣèré bí Oyin Adejọbi, Funmi Martins àtàwọn míì tó ti dágbére fáyé?
Grace Oyin Adejobi, ti ọkọ rẹ, Oyin Adejobi naa jẹ gbajumọ osere tiata tun fikun pe ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni oun ati ọkọ oun ti pade, ti aanu rẹ si maa n se oun tori ipo akanda ẹda to wa.
Nigba to n salaye idi ti ko fi tẹsiwaju lẹnu ẹkọ rẹ lati kawe de ibi to lapẹrẹ, Iya Osogbo nigba ti oun wa niwe kẹrin ni oun fi owo ile ẹkọ ra asọ ọdun Ileya.
O ni idi ree ti wọn ko fi jẹ ki oun kawe siwaju mọ.





