Bàbá Sala: Fídíò tó sọ nípa ìgbà ayé Bàbá Sala

Àkọlé fídíò, Fídíò mánigbàgbé nípa ìgbà ayé Bàbá Sala

Ọmọ bibi ilu Ilesha ni alagba Moses Olaiya ti a si bi ni ọdun 1936.

Lati bi ọdun melo kan sẹyin ni a ti n gbọ awuyewuye lori iku Baba Sala sugbọn Baba ni anfaani ẹmi gigun titi di ana.

Baba Sala wa lara awọn to kọkọ mu ẹrẹ sinima wa si orileede Naijiria pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ bi Hubert Ogunde, Kola Ogunmola Oyin Adejobi ati Duro Ladipo.

Orin Highlife ni Baba Sala kọkọ n kọ ti o si da ẹgbẹ akọrin kan silẹ ti wọn pe orukọ rẹ ni ''Federal Rythym Dandies'' ki o to wa ya si ere tiata.