Tafa Oloyede: ₦200 ní owó oṣù àkọ́kọ́ mi nìdí iṣẹ́ tíátà, mo sì ní àṣọ mẹ́ta péré

Oríṣun àwòrán, Osun Digital Radio
Bi a ba n darukọ awọn agba ọjẹ ere tiata ni Naijiria loni, yoo ṣoro ki eeyan to le sọ wi pe bawo ni ti Tafa Oloyede ṣe jẹ.
To ba jẹ pe ti ba wọn wo ere bi Olaniyọnu, Folajiyọ,Orogun Adedigba, Iyekan Soja, Teni n teni, Jagun Aso, Ti Oluwa nilẹ apa kini ati apa keji, ẹ o ti ribi ti Tifa ti n da bi ẹdun, to si ti n rọ bi owe.
Gbajugbaja osere tiata Yoruba John Adewuni Adewole ti ọpọ mọ si Tafa, ti n sọrọ nipa iriri rẹ lagbo oṣere.
- Yekeen Ajileye, ọ̀gá mi nínú iṣẹ́ tíátà ṣẹ̀ mí, ó ṣẹ ẹlẹ́dàá mi - Abija
- Gbajugbaja òṣèré ''Toromagbe'' nínú fíìmù ''Arelu'' ti jáde láyé
- Kí ló ń pa ẹbí Orisabunmi lọkọ́ọ̀kàn, àkúfà ni àbí àmúwá Ọlọ́run?
- Afeez Ọwọ: Èmi kọ́ ni mo kọ́kọ́ làwòrán Orisabunmi, ẹ ti ṣe wá rangun mọ́ mi?
- Yatọ̀ sí pé ó ṣe sọ́jà, tó tún jẹ́ ọkọ Oriṣabunmi, wo àwọn nkan tí o kò mọ̀ nípa Jimoh Aliu
- Duro Ladipọ, ìlúmọ̀ọ́ká òṣèré tíátà àti ọmọ àlúfà tí kò gbàgbé àṣà ìbílẹ̀
- Iya Rainbow jẹ́ gbajúmọ̀, àmọ́ kí lo mọ̀ nípa rẹ̀?
- Ọlọ́pàá àti ológun kò ní lójú àánú mọ́ fáwọn abàlújẹ́, ìyàtọ̀ yóò wà - Buhari
Ninu fọnran fidio kan ti a ri lori ayelujara, Tafa tu kẹkẹ ọrọ nipa irinajo rẹ silẹ nibẹ, to si sọ pe oun ko ni ju aṣọ mẹta lọ nigba toun bẹrẹ si ni kopa ninu ere ori itage.
Adewuni to jẹ ọmọ bibi ilu Ede sọ pe, igba Naira, ₦200, ni wọn n fun oun gẹgẹ bi owo oṣu nigba toun bẹrẹ ere.
Nigba ti Tafa fi bẹrẹ si ni ba wọn ṣere, o ni ẹbun amutọrunwa ni ilu lilu ati ijo jijo jẹ fun oun.
Lasiko tawọn oṣere fi n ba awọn alarinjo ṣere kaakiri, ijo jijo orin kikọ tabi ilu lilu jẹ eroja pataki ti oṣere gbọdọ ni.
Igba ta n wi yii nigba tawọn ẹgbẹ ere ori itage bi ti Oyin Adejobi fi jẹ ilumọọka, ṣaaju ki sinima agbelewo to wa gbode.
Tafa sọ pe nigba naa lọhun, oun a maa saba kopa ninu ere ni ileewe girama ati nile ijọsin.
O tẹsiwaju pe nibi toun ti n dara, ni obinrin kan ti gba oun ni imọran lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣere wọn ni Osogbo.
"Taibat Oyetunji lorukọ arabinrin yii, to si jẹ iyawo ọga wa Ọlọfaina. Ẹgbẹ oṣere Oyin Adejobi ni wọn ni ki n wa darapọ mọ.
Mo gba lati darapọ mọ wọn. Nibẹ si ni irinajo mi lagbo ere tiata ti bẹrẹ. Apo kan Naira ni owo oṣu mi nigba naa, mi o si ni ju aṣọ mẹta lọ
Bi a ba fẹ ṣere nigba Kootu Aṣipa, emi ni maa kopa to pọ''
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ilúbìnrin tí wọn ti ń ní ìbálòpọ̀, bímọ̀ láì ní ọkọ
- Orí mi wú pé àkòkò ìjọba mi ní àṣeyọrí reluwé ń wáyé - Buhari
- Ọlọ́pàá àti ológun kò ní lójú àánú mọ́ fáwọn abàlújẹ́, ìyàtọ̀ yóò wà - Buhari
- Ẹ̀yin òṣèré tíátà, kò sí iṣẹ́ ọ̀fẹ́ mọ́, ẹ sanwó iṣẹ́ tẹ bá gbé fún mi - Funmi Awelewa
- Ẹ̀yin tẹ̀ ń pè fún ìyapa Nàíjíríà, òmùgọ̀ pátápátá ni yín - Obasanjo
- Kàyééfì! Ìyàwó bímọ mẹ́wàá lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ọkọ kò níṣẹ́ lọ́wọ́
- Sunday Igboho ní òun ṣetán láti dira fáwọn ọ̀dọ́ Ibarapa fún ìpèsè ààbò aráàlú
Lara awọn ti Oloyede a maa gboṣuba fun ninu awọn oṣere ni Baba Wande.
Idi si ni pe nigba naa lọhun to bẹrẹ iṣẹ ere tiata pẹlu ẹgbẹ Oyin Adejobi, Baba Wande lo jẹ gẹgẹ bi alamojuto ẹgbẹ ti a mọ si ''Manager''
''Ko si igba ti aya mi kii sọ ki, ti mo ba ti ri Baba Wande. Idi si ni pe wọn a maa foju dẹru ba wa, ti a ba wa lori itage.
''Mo kọkọ maa n ro wi pe boya wọn n dẹru ba mi ni ṣugbọn nigba to ya, mo ri wi pe iṣẹ wọn ni wọn n ṣe.''
Ninu awọn ipenija to ni nidi ere tiata, Tafa Oloyede sọ pe ko pọ pupọ.
''Eyi ti mo le pe ni ipenija ni pe, awa ko mọ pe awọn eeyan maa n lowo nidi iṣẹ tiata.''
O ni ifẹ tawọn ni si ere tiata nigba naa lọhun, lo mu ki awọn ṣi wa nidi ere di oni.
O wa gba awọn oṣere miran niyanju lati koju mọ iṣẹ tiata, ki wọn ba le jẹ́ ọrọ idi iṣẹ naa.





















